Oyo LG Crisis: ALGON ní Seyi Makinde ń ṣe bíi Baṣọ̀run Gáà, tí kò bọ̀wọ̀ fún òfin

Seyi Makinde ati awọn alaga ijọba ibilẹ to yọ nipo

Awọn alaga ijọba ibilẹ ana ni ipinlẹ Oyo, ALGON, ti gomina Seyi Makinde da duro, ti sọ pe gomina ọhun kii ṣe ẹni to n bọwọ fun ofin.

Ayodeji Abass Alesinoye, to jẹ alaga ẹgbẹ ALGON lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba, iyẹn lẹyin ti Makinde kọ jalẹ lati san owo awọn alaga naa, eyi ti ile ẹjọ paṣẹ pe ko san fun wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, asiko ijọba gomina ana, Abiola Ajimobi ni wọn dibo yan awọn alaga naa, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn lẹyin wakati diẹ ti Makinde de ori oye, lo yọ awọn eeyan ọhun bii jiga lẹyin to ni idibo to gbe wọn wọle ko ba ofin mu.

Ṣugbọn awọn alaga ọhun gbe Makinde lọ sile ẹjọ, ile ẹjọ si ṣe idajọ pe ko san owo oṣu awọn alaga naa fun wọn.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Awijare Seyi Makinde ree to fi kọ lati sanwo osu awọn alaga kansu to yọ nipo

Bo tilẹ jẹ pe Makinde ṣetan lati san owo naa ṣaaju ki wọn to lọ sile ẹjọ, ti awọn eeyan ọhun si kọ jalẹ, ni bayii Makinde ti wa fake kọri pe oun ko ni owo kankan san mọ.

O ni ki awọn alaga naa pada silẹ ẹjọ, ki ile ẹjọ ọhun si salaye irufẹ awọn alaga ti oun yoo san owo fun ninu wọn.

Awijare rẹ ni pe alaga ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn ni ofin ilẹ wa mọ pe o wa nipinlẹ Oyo amọ gomina ana, Abiola Ajimobi lo da awọn ijọba ibilẹ onidagbasoke to to marunlelọgbọn silẹ.

Makinde ni ko seese ki oun sanwo fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti apapọ wọn jẹ mejidinlaadọrin, nigba ti ofin mọ mẹtalelọgbọn pere ninu wọn.

Àkọlé fídíò, Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́

ALGON ni Makinde n se bii Basọrun Gaa, ti ko si bọwọ fun ile ẹjọ

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga ALGON, Ayodeji Abass Alesinoye ṣalaye pe o ṣeni laanu pe kii ṣe irufẹ gomina Makinde lo yẹ ko maa tapa si ofin.

O ni "Gomina yii kan naa ni ile ẹjọ sọ pe oun gan lo jawe olubori ninu eto idibo, ko si sọ pe ile ẹjọ ṣisọ nigba naa lọhun."

"Ṣugbọn bayii Makinde ti n ṣe bii Baṣọrun Gaa ti ko bọwọ fun ofin, o si jẹ ohun iyalẹnu pe Makinde ko bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ."

O ni ni bayii ti ile ẹjọ naa ti fun Makinde di ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, awọn n duro de nnkan ti Makinde yoo ṣe boya yoo kọ lati ma san owo tabi bẹẹ kọ, ti akoko ba to.

Alesinloye pari ọrọ rẹ pe "Makinde ko ni ibọwọ fun ofin kankan, ti gbedeke ọjọ ti wọn fun un ba ti pe, oju rẹ yoo ri ohun ti oju awọn ti ko bọwọ fun ofin maa n ri."

BBC tun kan si akọwe ẹgbẹ APC nipinlẹ Oyo, iyẹn Mojeed Olaoya lati da si ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

APC ni oun ko ni ohunkohun lati sọ titi di gbedeke ọjọ ti ile ẹjọ fun Makinde lati san owo naa

Olaoya sọ pe oun ko ni nnkankan lati sọ lori ọrọ naa ju pe awọn n duro ki gbedeke ọjọ ti ile ẹjọ fun gomina Makinde pe, ki awọn to mọ igbesẹ to kan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ "Olofin ni awa, a kii kọ dindinrin lọgbọn, a n wo boya yoo ṣe ohun ti ile ẹjọ pa laṣẹ fun tabi bẹẹ kọ, ki a to mọ ohun ti a ṣe lori ọrọ naa."

Ẹwẹ, nigba ti alaga ẹgbẹ APC ti ọrọ naa kan gbọngbọn, Akin Oke n da si ọrọ ọhun, o ni awọn ko tii ri iwe idajọ naa ṣugbọn oye ni agba n wo.

Akin Oke sọ pe, awọn agba ẹgbẹ ṣi n fi oju ṣunukun wo ọrọ naa titi di igba ti awọn yoo foju gan ni iwe idajọ ati akoko ti ile ẹjọ fun gomina Makinde yoo pe.