Adebayo Adelabu: Florence Ajimobi lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdùnú àti ayọ̀ lẹ́yìn iku ọkọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Agbaakin Parakoyi ti ilẹ Ibadan, Adebayo Adelabu ti sọrọ lori awuyewuye to n waye lori fidio kan to gba ori ayelujara kan.
Ninu fidio naa, ni oun ati aya gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Florence Ajimobi ti dijọ n jijo si orin 'Gbẹ́sẹ̀, Gbe Body Soke' eyi to n ja rainrain lori ayelujara.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin, Adelabu sọ pe ko si nnkan babara ninu fidio naa, ṣugbọn awọn kọlọransi ẹda kan kàn mọọmọ fẹ fi fidio naa da wahala silẹ ni.
- Mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi si lẹ́yìn ikú rẹ̀ ju ojú ayé rẹ̀ lọ - Florence Ajimobi
- Iṣẹ́ àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́gán nílé ìtajà aya Ajimobi tó jóná
- 'Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi wà lọ́run rere'
- Ìgbé ayé Abiola Ajimobi nínú àwòràn pẹ̀lú àwọn ǹkan tó ṣẹlẹ̀
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
- Ajimobi kò fún wa ní kọ́bọ̀ fún ìsìnkú Kolapo Ishola - Ẹbi pariwo
- Ikọ̀ ìjọba Ọ̀yọ́ dé lásìkò tí kò yẹ ni wọn kò ṣe wọlé - Ẹ̀bí Ajimobi fèsì
Adelabu sọ pe inu oun bajẹ lori ọrọ ti awọn eeyan kan n sọ nipa fidio naa, o ni se lo yẹ ki wọn maa ba aya gomina tẹlẹri ọhun yọ, pe o gbẹyin ọkọ rẹ to jẹ Ọlọrun nipe.
O ni "Obinrin yii jẹ ẹnikan to duro ti ọkọ rẹ nigba ojo ati igba ẹrun, o si ṣe ọfọ oloogbe ọhun fun nnkan bii ọdun kan gbako.

Oríṣun àwòrán, SScreen Shot
Igbagbọ wa ni pe ẹtọ rẹ ni ki inu rẹ dun lẹẹkan si lẹyin iku ọkọ rẹ.
Ibi ti a ti n jo ijo naa jẹ ipejọpọ ajọyọ kan, ti wọn ṣe fun awọn alakoso ijọba ibilẹ, ALGON, lẹyin ti wọn jawe olubori nile ẹjọ to ga julọ.
Apejẹ naa si ni awọn alakoso ti wọn dibo yan atawọn eekan ni ijọba ibilẹ naa peju si."
Adelabu fi kun pe, lẹyin ti wọn fi ẹmi imoore han si Florence Ajimobi fun atilẹyin rẹ fun ALGON, ni wọn ni ko wa ba awọn fi ẹsẹ rajo, ti oun naa si ṣe bẹẹ.
O ni o ṣenu laanu pe ibi to ti n ba oun nikan jo, ni awọn kọlọrọsi ẹda naa gbe sita, ti wọn si n pin lori ayelujara lati tabuku aya gomina tẹlẹri ọhun ati oun alara.
Agbaakin Parakoyi ti ilẹ Ibadan naa ṣalaye pe, oun ko ri nnkan babara ninu ijo ti aya oloogbe naa jo nitori ko si ẹni ti ko ni ku.
O fikun pe, o ti to nnkan bi ọdun kan ti Abiola Ajimobi jade laye, iyawo rẹ si ti ṣọfọ rẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
O ni "Sẹnetọ Ajimobi gbe igbe aye to dara, o ni ọjọ lori ko to jade laye, o si foju ganni awọn ọmọ-ọmọ rẹ, nitori naa, ko si ohun to buru ninu ki eeyan dunnu lati ṣe iranti iṣẹ rere to gbele aye ṣe."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ń fa aáwọ̀ láàrin Gani Adams àti Sunday Igboho
- A fọwọ́ sí ìṣọ̀kan Nàíjíríà gẹ́gẹ́ bi ọmọ ẹgbẹ́ APC - Akeredolu, Fayemi
- Genesis Global: Sáká lara Woli Israel Ogundipe dá, kìí ṣe àìlera ló mú kí wọn fi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n
- TAMPAN pàṣẹ pé 'director' kankan kò gbọdọ̀ pe Nkechi Blessing àti Adams Kehinde sí iṣẹ́ mọ́
- Wọn ò bí Baba Ijesha dáa kó sọ pé kò mọ mí rí - Agbẹjọ́rò Adesina Ogunlana
- Àfinra! Amotekun lé àwọn Fulani 137 tó gba inú igbó ìjọba lọ́nà àìtọ́ kúrò l'Ondo
- 'Ọkọ̀ ńlá méjì ló kó àwọn Fulani wọ Ajowa Akoko ní Ondo, àmọ́ a ti jọ ń sọ̀rọ̀ pé ...'
- Tinubu, Gbajabiamila, Sanwo-Olu gbárùkù tí fífòfin de dída ẹran káàkiri ìgboro
Adelabu pari ọrọ rẹ pe, ki awọn ti ọrọ naa kan maṣe naani ọrọ ti awọn eeyan kan n sọ nipa fidio ọhun lori ayelujara.
Lẹyin naa lo ni pẹlu idunnu ati ayọ ni awọn yoo fi ṣeto iranti ọdun kan ti gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹri ọhun, Abiola Ajimobi fi aye silẹ.
Ṣaaju ni awọn kan ti kọkọ n bu ẹnu ẹtẹ lu Florence Ajimobi, lẹyin ti fidio ibi ti oun ati Adelabu ti n jo jade lori ayelujara.
Ninu fidio ọhun ni awọn mejeji ti n jo si orin "Gbẹsẹ" ti ẹni to wa ṣe ere nibi ayẹyẹ naa n kọ.


















