Abiola Ajimobi: Ẹbí Kolapo Isola ṣẹ́ pé òun kò gba ₦30m lọ́wọ́ Ajimobi fún ìsìnkú bàbá wọn

Kolapo Isola ati Abiola Ajimobi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹbi ati ara Gomina Ipinlẹ Oyo tẹlẹri, Kolapo Ishola ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti olori oṣiṣẹ fun Abiola Ajimobi nigba to wa nipo gomina, Gbade Ojo sọ nipa eto isinku rẹ.

Gbade Ojo ni o le ni ọgbọn miliọnu Naira, ti ijọba Abiola Ajimobi fun awọn ẹbi fun isinku gomina tẹlẹri, Kolapo Ishola.

Gbade Ojo sọ ọrọ yii lori ẹrọ redio ni ilu Ibadan, nigba to n ba awọn eniyan fọrọ jomitoro ọrọ lori iku Abiola Ajimobi ati ipa ti ijọba Seyi Makinde ko.

Awọn ẹbi Kolapo Ishola, nigba ti wọn n fesi ninu atẹjade ti wọn fi sita ni, irọ patapata ni olori oṣiṣẹ Ajimobi pa.

AJIMOBI

Oríṣun àwòrán, TWITTER/AJIMOBI

Wọn fikun wi pe, Ajimobi ko fun wọn ni Kọbọ kan to kereju nitori awọn kọ lati jẹ ki o ti eto oṣelu bọ oku baba awọn, bi o ṣe wu u.

‘Ajimobi ko yọju si ibi isinku naa ti wọn ṣe laarin ọsẹ kan, ti ko si ran ẹnikẹni wa si ibi isinku naa.’

‘Baba wa, Oloye Kolapo jẹ ẹni to ni iwa tutu, to si fẹran awọn ara ipinlẹ Oyo nigba ti o wa laye.’

‘Ko wu wa lati dasi ija to wa laarin Gomina Seyi Makinde ati ẹbi Abiola Ajimobi, amọ ohun to buru ni lati ma pa irọ mọ ẹbi oloogbe Kolapo pe wọn gba owo.’

‘A fi ọrọ yii sita ki awọn araalu le mọ otitọ nipa iṣẹlẹ naa, ki wọn si dẹkun ati ma a wu iwa aitọ.’

Bakan naa ni awọn ẹbi naa wa kesi Gbade Ojo lati sọra nipa ọrọ ẹnu rẹ, nitori pe ko si ẹni ti ko ni ku.

Kolapo Ishola lo wa ni ipo gomina ni ipinle Oyo laarin odun 1992 si odun 1993 labẹ Ijọba Alagbada.

Ọdun 2011 ni gomina tẹlẹri naa jade laye ni ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò yin Ajimobi lojú ayé, tó ń yìn-ín lẹ́yìn ikú, yóò jẹ ìyà - Oníwáàsí

Eto akanse adura Fidau ọjọ kẹjọ fun gomina ana nipinlẹ Ọyọ, Isiaka Abiola Ajimobi ti waye lọjọ Aiku.

Akanse adura Fidau ọjọ mẹjọ naa lo waye nile oloogbe Ajimọbi nilu Ibadan nilana ẹsin Islam.

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Ajimobi lives on

Adura Fidau naa, ni awọn ọmọ, aya ati ẹbi oloogbe nikan peju si, ti ikede saaju pe ko si fun gbogbo eniyan nitori ofin itakete sira ẹni to wa lode lori arun Coronavirus.

Ninu waasi rẹ to se ni ede oyinbo nibi adura naa, Imaamu agba fun mọsalasi Oluyole, Sheik Nafiu Atanda Bada mẹnuba pe ọpọ ẹsin to wa laye lo gbagbọ ninu ka gba dura fun oku, eyi ti awọn n se lonii.

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Bada ni Abiola Ajimobi ri aye gbe, to si fi aye rẹ sin iran ọmọniyan, to si gbadura pe ki Ọlọrun gba abọ rẹ, ko si dari awọn ẹsẹ rẹ jin.

Bakan naa, Sheik Muideen Ajani Bello, tii se oniwaasi agbaye to se waasi nibi akanse eto adura naa ni ijoko adura naa ti to fun waasi nikan.

Awọn obinrin to wa ba Florence Ajimobi daro

Oríṣun àwòrán, Ajimobi lives on

Bello ni "ọpọ awọn fọnran aworan ti Ajimobi ti sọrọ silẹ nigba aye rẹ fihan pe, oloogbe naa kii se eeyan lasan, wolii Ọlọrun ni. Gbogbo ohun ti kaluku wa ba n se ni ka yipada, abi, ta a ni sọ."

O wa gbadura pe ki Ọlọrun kẹ Ajimọbi, ko gẹ ẹ, ko si san gbogbo laada to yẹ ko duro jẹ fun ninu saare.

"Iya ni ọpọ eeyan ti ko yin Ajimobi loju aye rẹ, amọ ti wọn n yin lẹyin to ku tan yoo jẹ niwaju Ọlọrun, nitori igba to wa laye lo yẹ ki wsn sọ daada nipa rẹ."

Awọn Aafa to peju sibi adura ọjọ kẹjọ fun Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Ajimobi lives on

Bello, ẹni to sọ pe Ajimobi leri lati kọ mọsalasi nla ti yoo gba gbogbo eeyan, to si mu ileri naa sẹ tun fikun pe, mọsalasi ti Ajimobi kọ silẹ ni iwe ẹri Aljanna to gba laye.

Oniwaasi agbaye naa wa gba aya Ajimobi niyanju lati tẹle ohun ti iwe Alukurani sọ nipa opo sise, eyi to ni o jẹ osu mẹrin ati ọjọ mẹwa, eyiun aadoje ọjọ, ti yoo si jade opo ni ọjọ keji osu Kọkanla ọdun 2020.

Lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn, Seyi Makinde ránṣẹ́ ìbánikẹ́dùn sí ẹbí Ajimobi

Abiola Ajimobi ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Vanguard newspaper

Ikini naa waye lẹyin ti iyawo oloogbe naa, Florence Ajimobi, fi ẹsun kan ijọba ipinlẹ Oyo ti Makinde n dari rẹ pe, wọn ko ki oun ku ara fẹraku ọkọ oun.

Ẹsun to fi kan wọn fa awuyewuye laarin awọn ọmọ Naijria.

Ọjọ isinku ni Florence sọ ọrọ naa, lasiko ti igbakeji Makinde, lọ ọ ki ni ile fun iku ọkọ rẹ.

O ni Makinde n fi ọrọ iku ọkọ oun ṣe ọrọ ati ija oṣelu.

Fidio naa re e:

Skip Facebook post, 2

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 2

Ninu lẹta ibanikẹdun naa to wa lori ayelujara, Makinde ṣapejuwe oloogbe Ajimobi, gẹgẹ bi ẹni to fi igbe aye rẹ sin ọmọniyan.

Lẹta ibanikẹdun ti Makinde kọ si ẹbi Ajimọbi

Oríṣun àwòrán, Oyo state Government

Bakan naa lo sọ pe "Ajimobi ko ipa ninu idagbasoke ọrọ aje ati awujọ nipinlẹ Oyo, ati Naijiria lapapọ.

Ṣaaju ni Akọwe iroyin fun gomina, Taiwo Adisa, sọ pe ijọba ipinlẹ naa n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹbí Ajimobi, lati fun oloogbe ni eto adura Fidau to bu iyi kun.

Ètò àdúrà Fìdáù yóò wáyé fún olóògbé nílùú Ibadan

Ọjọ karun-un, oṣu Keje, ni adura ọjọ kẹjọ yoo waye fun gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ to di oloogbe, Sẹnetọ Isiaka Abiola Ajimobi.

Eto adura naa, Fidau, wa ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣe ẹsin Islam.

Idile oloogbe sọ ninu ikede to fi sita fun eto adura naa pe, ẹbí Ajimobi nikan ni yoo kopa nibi eto adura , nitori ofin to rọ mọ itankalẹ coronavirus.

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Twitter/@aaajimobi

Ṣugbọn ṣa, wọn ni awọn araalu yoo ni anfaani lati wo bi eto adura naa ba ṣe n lọ lori amohunmaworan ati lori ayelujara.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2020, ni Abiola Ajimobi kú, sileewosan First Cardiologist, to wa niluu Eko, lẹyin to ni aarun Covid-19.

Ẹni aadọrin ọdun si ni ko to o kú.