Ajimobi coronavirus: Àwọn èèyaǹ jàǹkàn mérin tó ti jẹ́ Ọlọrun nípè nítorí àrùn Coronavirus ní Naijiria

Covid-19

Oríṣun àwòrán, others

Lati igba ti arun Coronavirus ti ṣẹyọ ni ilu Wuhan lorilẹ-ede China lọdun 2019, ọpọ ẹmi lo ti sọnu kaakiri agbaye.

Arun naa ko yọ orilẹ-ede Naijiria silẹ ni bo ṣe n gbẹmi awọn eeyan lojojumọ.

O ti le ni ẹẹdẹgbẹta eeyan to ti dero ọrun ni Naijiria nitori arun naa, lara awọnn eeyan ọhun ni:

Abba Kyari

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin ọdun 2020 ni iroyin gbode pe Abba Kyari to jẹ olori oṣiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari, ti doloogbe.

Kyari ku si ile iwosan kan ni ilu Eko lẹni ọdun mẹtadinlaadọrin lẹyin to lugbadi arun Coronavirus.

Abba Kyari

Oríṣun àwòrán, @VickyShegzy

Yatọ si pe o jẹ olori oṣiṣẹ aarẹ Buhari, Abba Kyari tun jẹ ọrẹ timọ-timọ aarẹ Buhari nigba aye rẹ.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ri Kyari bi alagbara eeyan ninu iṣẹjọba Buhari, ti ko si ṣeyin bi aarẹ ṣe ma n tẹkọ leti lọ si ilu Ọba nitori ilera ara rẹ.

Nigba ti iyawo aarẹ, Aisha Buhari sọ loju opo Twitter rẹ pe awọn eeyan kan lo n tukọ iṣejọba ọkọ rẹ to jẹ aarẹ, pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria lo n sọ pe Kyari lo n sọ nipa rẹ.

Ṣugbọn lẹyin ti Kyari jade laye, Aisha sọ loju opo Twitter rẹ pe oun gbadura "Ki Ọlọrun dari ẹṣẹ rẹ jii."

Adebayo Osinowo

Oríṣun àwòrán, @AdekunleOtun

Adebayo Osinowo

Ko to jade laye, oniṣowo ati oloṣelu ni Adebayo Osinowo jẹ.

Oun si ni sẹnatọ to n ṣoju ẹkun idibo ila-oorun ipinlẹ Eko nile igbimọ aṣọfin agba to wa ni ilu Abuja.

Okiki Osinowo kan lẹyin to fidi Gbenga Ashafa janlẹ ninu idibo abẹnu sipo ṣenetọ to wa ye ninu ẹgbẹ oṣẹlu APC ni ẹkun idibo ila-oorun ipinlẹ Eko lọdun 2019.

Osinowo ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko fun saa mẹrin ọtọtọ, nibi to ti ṣoju ẹkun idibo Kosofe.

Wọn bii ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla ọdun 1955, ṣugbọn o jẹ ipe Eledumare lọdun 2020 lẹyin to ni arin Covid-19.

Maikanti Baru

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun un ọdun 2020 ni Maikanti Baru dagbere faye lẹyin ailera rẹ nitori arun Coronavirus.

Baru ni ọga agba fun ileeṣẹ to n risi ọrọ epo rọbi ilẹ Naijiria, NNPC ki ọlọjọ to de.

Maikanti Baru

Oríṣun àwòrán, @ComrMuhammad12

Wọn bi Baru ni ọjọ keje, oṣu keje ọdun 1959.

O kọ ẹkọ, o si ṣiṣẹ nipa eto imọ ẹrọ fun ọpọ ọdun ni ileeṣẹ NNPC ki aarẹ Muhammadu Buhari to yan an sipo ọga agba ileesẹ naa lọdun 2016.

Ko to darapọ mọ ileeṣẹ NNPC, Baru ṣiṣẹ nile iṣẹ Jos steel Rolling Company laarin ọdun 1988 si 1991.

Abiola Ajimobi

Wọn bi gomina ana ni ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi lọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 1949 si idile Ajimobi ni Oja-Iba ni ilu Ibadan.

Ajimobi

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Ki ọlọjọ to de, Ajimobi ti jẹ sẹnatọ nile igbimọ aṣofin lọdun 2003 ko to de ipo gomina lọdun 2011 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Congress of Nigeria, ACN, lọdun naa lọhun.

Ṣaaju ni iroyin kan ti gbode pe Ajimobi ti di oloogbe ṣugbọn ti awọn ẹbi atawọn eeyan miran to sun mọ sọ pe ọrọ ko ri bẹ.

Lẹyin-o-rẹyin, Ajimọbio dagbere faye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2020 lẹni ọdun mọkanlelaadọrin nile iwosan kan ni ilu Eko.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kan naa ni ijọba ipinlẹ Eko fi ọrọ lede pe arun Covid-19 lo da ẹmi gomina tẹlẹri naa legbodo.

Ọpọ awọn eeyan jankan ati awọn gomina ilẹ Yoruba lo ti n ṣelede lẹyin rẹ.

Àkọlé fídíò, Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà