First symptom of Coronavirus: Àwọn èèyàn kò bìkítà sí àlàkalẹ̀ ìjọba lórí àrùn Covid-19 - ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Àkọlé àwòrán, Eeyan mẹrinlelogoji miran lo ṣẹṣẹ ni Coronavirus ni ipinlẹ Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn eeyan ipinlẹ naa ko gbagbọ pe Coronavirus wa lode lo jẹ ki arun naa maa pọ si ni ipinlẹ ọhun.

Kọmiṣọna ọrọ ọrọ to n lọ ni ipinlẹ naa, Donald Ojogo lo sọ bẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

O ni isọro kan gboogi ti ijọba ipinlẹ Ondo n dojukọ ni bi awọn awọn eeyan ipinlẹ Ondo ko ṣe kọbi ara si gbogbo alakalẹ ijọba lori arun arun Covid-19.

Ojogo sọ pe "Ọwo awọn eeyab lo ku si lati yanju iṣoro Covid-19 ni ipinlẹ Ondo nitori ọpọ ninu wọn ko gbagbọ pe aisan naa wa lode."

Ijọba n gbiyanju, a ti ṣe iwọn ti a leṣe lati lka awọn eeyan lọyẹ ṣugbọn wọn o gbagbọ."

Ṣaaju ni ajọ NCDC ti kede pe eeyan mẹrinlelogoji lo fara kasa arun Covid-19 ni ipinlẹ ọhun ni Ọjọbọ, eyi to jẹ iye eeyan to pọ ju ti yoo ni arun naa lọjọ kan ṣoṣo ni ipinlẹ ọhun.

Akeredolu

Oríṣun àwòrán, @RotimiAkeredolu

Àkọlé àwòrán, Awọn nọọsi ti daṣẹ silẹ lẹyin ti wọn ni ijọba n jẹ wọn lowo oṣu

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn dokita ipinlẹ Ondo ti gunle iyanṣelodi ọlọjọ gbọọrọ lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2020.

Awọn oṣiṣẹ eto ilera naa fẹsun kan ijọba ipinlẹ naa pe wọn ko kọbi ara si ẹdun ọkan wọn.

O jẹ wọn lowo oṣu bẹẹ ni ko pese ohun idabo bo araẹni fun wọn lasiko ajakalẹ arun Coronavirus.

Ṣugbọn kọmiṣọnna naa ti fesi pe ijọiba yoo yanju aawọn to wa laarin rẹ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ awọn adokita ọhun laipẹ.

O ni "Awọn oṣiṣẹ wa lati ileesẹ eto ilera yoo ṣepade pẹlu awọn nọọsi, aawọ naa yoo si di ohun igbagbe titi ọjọ Aje, ọjọ kọkandinjlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun yii."