Apocalypse: Ìgbà mọ́kànlá tí ayé ò bá ti parẹ́

USA

Oríṣun àwòrán, EMMANUEL DUNAND

Àkọlé àwòrán, Awọn to n ṣewọde mlẹyin ti Harold Camping ni aye yoo parẹ lọdun 2011

Ọjọ ti pada kọja bayii ti onkọwe kan, David Meade sọ asọtẹlẹ pe aye yoo parẹ ni ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan ọdun 2017. Iyẹn o ṣẹlẹ.

Nigba to ya, Ọgbẹni David tun yi ẹnu pada o sọ tẹlẹ pe ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2017 tun ni aye yoo parẹ.

Gẹgẹ bi David Meade to jẹ onkọwe ẹsin Kristẹni ṣe sọ tẹlẹ, o ni ọjọ naa ni ọjọ ti aye mii to wa loke aye yii to pe ni "Planet X" yoo wo lulẹ sori aye gẹgẹ bo ṣe ni bibeli sọ ọ.

O ni ọjọ yii kan naa ni ogun ati idarudapọ yoo bẹrẹ laye.

Amọ, bi Ọgbẹni Meade ṣe n sọ eyi naa ni igbimọ awon to n wo inu afẹfẹ to jẹ ẹgbẹ awọn onimọ sayẹnsi, NASA to mọ nipa oju ọrun sọ pe ko si aye kankan to tun n jẹ Planet X,

Koda, won ni irọ ni gbogbo ẹ, Wọn ni ko si nkankan ti yoo wo lulẹ sori aye yii.

Ni bayii, awọn eeyan n bere ibeere koda wọn n ṣewadii lori ayelujara lati mọ ọjọ ti aye yoo parẹ.

Lati dahun ibeere yii, o ti di igba mọkanla ọtọọtọ bayii to yẹ ki aye parẹ ṣugbọn ti ko ṣẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Port harcourt Bole: Mi kò mọ́ pé bọ̀ọ̀lì títà lè gbé mi dé ipò yìí láyé mi!

Awọn igba wọnyi ni aye o ba ti parẹ:

1. A.D. 66

Ni igba yii, awọn ẹlẹsin Juu kan ti wọn n pe ni Essenes sọ tẹlẹ pe laarin AD 66 - 70, Jesu Kristi yoo pada wa lẹẹkeji aye yoo si pa aye rẹ.

2. Ọjọ kinni, oṣu ẹẹrẹ (January), ọdun 1,000

Poopu ijọ Katoliki kan, Pope Sylvester II atawọn adari ẹsin Kristẹni kan lo sọ tẹlẹ pe ọdun 999 lọjọ aisun ọdun laye yoo wa sopin

Sugbọn lẹyin ti ọpọlọpọ eeyan rọ lọ si ile ijọsin fun aisun ọdun tuntun ni ijọ Katoliki St. Peter's Basilica, ọjọ kini, oṣu kini ,ọdun 1000 de, o kọja lọ ṣugbọn aye o ma parẹ lọjọ naa.

3. A.D. 1284

Poopu mii, Innocent III sọ asọtẹlẹ pe ọdun 1284 eyi to jẹ ọdun 666 lẹyin ti ẹsin Islam bẹrẹ ni aye yoo parẹ.

Sugbon si iyalenu awon eniyan, oun funrarẹ ku ni aadọta ọdun ṣaaju ọdun to sọ nitori naa ko si laye lati ri i pe aye ṣi n tẹsiwaju.

Florence, Italy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Florence, Italy, nibi ti awọn Poopu kan ti sọ pe aye yoo parẹ si

4. Ọjọ kinni oṣu erele (February), ọdun 1524

Lọdun 1523, ẹgbẹ awọn kan ti wọn ro pe awọn lee ri ọjọ iwaju ni ilu London sọtẹlẹ pe ọjọ kinni, oṣu keji, ọdun to tẹle e ni ẹkun omi yoo pa aye rẹ.

5. Ọdun 1666

Lẹyin adanwo ati ina nla to ja ni ilu London eyi to pa ọpọ eeyan lọdun naa ẹgbẹ ẹlẹsin kan to jẹ iran to n dari sọ pe ọdun yẹn ni aye yoo parẹ ṣugbọn ko ri bẹẹ.

6. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Ebibi, ọdun 1780

Lọdun 1780 l'Amẹrika, eefin ru jade latinu ina to n jo laginju eyi to mu ki gbogbo ikuuku oju ọrun dudu fun ọjọ kan gbako.

Eyi mu ki gbogbo awọn ara Orilẹ-ede Amẹrika nigba naa ro wi pe aye ti fẹ parẹ.

8. 1936, 1943, 1972, ati 1975

Herbert Armstrong to jẹ ọkan lara awọn ajihinrere to kọkọ bẹrẹ si ni waasu lori tẹlifisan sọ wi pe igbasoke awọn ayanfẹ yoo waye lọdun 1936,

Sugbọn o ya a lẹnu pe ko ṣẹlẹ bẹẹ lasiko to da.

Nigba tiyẹn ko ṣẹlẹ, Armstrong tun sọtẹlẹ pe yoo ṣẹlẹ laarin ọkan ninu awọn ọdun ọtọọtọ yii - 1943, 1972 ati 1975 pe igbasoke yoo waye ṣugbọn gbogbo rẹ ko ṣẹlẹ.

9. Oṣu ẹẹrẹ (January), ọdun 2000

Igba yii ni ohun ti wọn n pe ni Y2K bug gbode kan ti awọn eeyan si gbagbọ pe gbogbo ẹrọ ayarabiaṣa (computer) lagbaye yoo pafuka lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 1999.

Ati pe ti aye yoo si parẹ ni ọdun 2000 yii.

Bẹẹ ni ọjọ naa wa to si tun lọ, ko ma sohun to ṣẹlẹ; koda, awọn ẹrọ ayarabiaṣa gan an ko pafuka.

Aworann ọjọ idajọ ni Piazza del Popolo, ni Rome

Oríṣun àwòrán, TIZIANA FABI

Àkọlé àwòrán, Aworann ọjọ idajọ ni Piazza del Popolo, ni Rome

10. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Igbe (April), ọdun 2007

Ninu iwe rẹ ti akọle rẹ n jẹ "The New Millenium" eyi to kọ lọdun 1990,

Pat Robbertson sọtẹlẹ pe ọjọ ikẹyin laye yii yoo jẹ ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2007 ṣugbọn iyẹn gan an tun kuna.

11. Ọjọ kọkanlelogun, Oṣu Ebibi (May), ọdun 2011:

Asọtẹlẹ eyi ti gbaye kan ju nipa igba ti aye yoo parẹ ni eyi ti Harold Camping sọtẹlẹ pe ọjọ kọkanlelogun, oṣu karun un, ọdun 2011 ni opin aye yoo de.

O ni igbasoke awọn ayanfẹ yoo ṣẹlẹ lọjọ naa idajọ yoo si waye lẹyin oṣu mẹfa iyẹn ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa.

Nigba tohunkohun ko waye ninu oṣu karun un, ni Camping sọ pe idajọ inu ẹmi lo ti ṣẹlẹ lọjọ naa ati pe igbasoke ati idajọ gangan yoo waye papọ ninu oṣu kẹwaa.

Ṣugbọn oṣu kẹwaa ọhun wa ko si si igbasoke ayanfe kankan.

Nibayii, gbogbo eniyan lo kawọ gbera ti wọn n reti boya lootọ lootọ aye yoo ṣi parẹ ni 21/10/2017 ti Camping sọ.

Ṣugbọn beeyan ba gbojule gbogbo asọtẹlẹ to ti kuna yii, koko idahun si ibeere ni wi pe ko sẹni to mọ igba ati bi aye yoo ṣe wa sopin?

Àkọlé fídíò, Ìtàn Olaniyi Balogun, ọ̀jọ̀gbọ́n tó fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ gba iṣẹ̀ àgbẹ̀ l'Ámẹ́ríkà