Nigerian Senators deaths: Àwọn sẹ́nẹ́tọ̀ mẹ́rin tó jáde láyé ní Nàìjíríà láàrin oṣù mẹ́fà sẹ́yìn rèé

Bayo Oshinowo, Rose Oko ati Benjamin Uwajumogu

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Iku o da ọjọ, aarun ko da oṣu, awaye kan ko si, ọrun nikan ni are mabọ.

Laarin oṣu mẹfa ninu ọdun 2020 yii, sẹnẹtọ mẹta ọtọtọ nile aṣofin agba l'Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria lo ti jade laye.

Wọnyi ni awọn sẹnẹtọ mẹrin ọhun to papoda laarun oṣu mẹfa tun to fori sọ asiko ajakaklẹ aarun coronavirus lorilẹede Naijiria.

Bayo Osinowo, sẹnẹtọ ẹkun ila oorun Eko

Ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹfa ọdun 2020 ni Sẹnẹtọ Bayo Osinonowo ti ọpọ mọ si Pepperito jade laye.

Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni Sẹnẹto Osinowo ki ọlọjọ to de.

Ohun ti a gbọ ni pe aisan ranpẹ lo ṣe Pepperito ki o too jẹ Ọlọrun nipe.

Osinowo

Oríṣun àwòrán, @LuqmanTI_2

Igba mẹrin ọtọtọ ni wọn dibo yan oloogbe Osinnowo sile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko nigba aye rẹ.

Ninu idibo gbogbogbo to lọ ni Naijiria ni wọn ti dibo yan Pepperito gẹgẹ bi sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun ila oorun ipinlẹ Eko nile aṣofin agba nilu Abuja.

Oun ni alaga igbimọ to n ri si ọrọ owo, ileeṣẹ ati idokowo nile aṣofin agba l'Abuja ki o to fi aye silẹ.

Rose Oko, sẹnẹtọ ẹkun ariwa Cross River

Lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta ọdun 2020 yii ni iroyin jade pe sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Cross River, Rose Oko ti papoda.

Ọkan lara awọn oluranlọwọ rẹ sọ fawọn akọroyin pe ẹni ọdun mẹtalelọgọta ti sẹnẹtọ Oko jẹ ki o to dagbere faye.

Ni ile iwosan kan nilẹ Gẹẹṣi ni arabinrin Oko dakẹ si.

Rose Oko

Oríṣun àwòrán, Facebook/Rose Oko

Saa keji ni Sẹnẹtọ Oko n ṣe lọwọ nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja ki iku to mu un lọ.

O tun ti fi igba kan ri ṣoju ipinlẹ Cross River nile aṣoju-ṣofin l'Abuja.

Ninu idibo gbogbogbo ọdun 2015 ni wọn kọkọ dibo yan Oko gẹgẹ bi sẹnẹtọ lati ṣoju ẹkun rẹ ki wọn to dibo yan pada fun saa keji lọdun 2019.

Ignatius Longjan, sẹnẹtọ ẹkun guusu Plateau

Sẹnẹtọ to n ṣoju ẹkun guusu ipinlẹ Plateau, Ignatius Longjan jade laye lalẹ ọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu keji, ọdun 2020.

Ẹni ọdun marunlelaadọrin ni Sẹnẹtọ Longjan ki iku to mu lọ.

Ignatius Longjan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ignatius Longjan

Sẹnẹtọ Longjan to tun ti fi igba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Plateau papoda lẹyin to ti ṣ'aisan fun ọjọ pipẹ.

O tun fi igba kan jẹ olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Plateau, bakan naa ni o jẹ alaga igbimọ to n ri si ọrọ aṣa ati igbafẹ nile aṣofin.

Benjamin Uwajumogu, sẹnẹtọ ẹkun ariwa Imo

Sẹnẹtọ Benjamin Uwajumogu to n ṣoju ẹkun ariwa ipinlẹ Imo papoda lọjọ kejidinlogun oṣu kejila ọdun 2019.

Akẹgbẹ rẹ, Sẹnẹtọ Rochas Okorocha to n ṣoju ẹkun guusu ipinlẹ naa lo kede iku rẹ fawọn akọroyin.

Ohun ti a gbọ nipe Sẹnẹtọ Uwajumogu yọ ṣubu nibi ti o ti n wẹ, lati ibẹ ni wọn ti gbe digbadigba lọ si ile iwosan ni Apo nibi ti ẹlẹmi ti gba a.

Benjamin Uwajumogu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Benjamin Uwajumogu

Saa meji ni Sẹnẹtọ Uwajumogu lo nile aṣofin agba niluu Abuja.

Titi ti o fi ku, oun ni alaga igbimọ ile to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ati eto igbaniṣiṣẹ.

Oun ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Imo laarin ọdun 2011 si 2015.

Ẹwẹ, ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC ti kede pe ọjọ kọkanlelọgbọn ọdun 2020 yii ni idibo mii yoo waye lati dibo yan awọn ti yoo rọpo awọn sẹnẹtọ to ku yii atawọn meji to jẹ gomina ati igbakeji gomina Bayelsa bayii.

Ṣé lóòtọ́ ni Sẹ́netọ̀ Bayo Osinowo ní ìfura ikú ara rẹ̀?

Ṣe awọn agba bọ wọn ni ko si iku ti yoo pa agba ti ko ni ṣee loju firi.

Kii ṣe iroyin yajoyajo mọ pe gbajumọ oloṣelu ọmọ Ijẹbu ode to n ṣoju ẹkun ila oorun ilu Eko nile aṣofin agba, Sẹnetọ Bayọ Oṣinọwọ ti wọ kaa ilẹ

Sugbọn iroyin ibẹ ni pe ninu fidio kan to lu sori ayelujara, ọrọ ti Sẹnetọ Osinowo sọ ninu rẹ da bi ẹni pe o ti ri iran iku rẹ ni.

Nibi ijoko ile aṣofin agba nibi ti wọn ti gbe ijoko kan kalẹ lati fi daro eekan orilẹ-ede Naijiria kan to jade laye ni o ti ṣẹlẹ

Gbogbo awọn aṣofin agba ni wọn sọrọ ni ṣiṣẹ n tẹle lori oloogbe naa laiyọ Pepperito naa silẹ.

Osinowo ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, other

Nigba ti o kan Sẹnetọ Oṣinọwọ lati sọrọ, awọn ọrọ to jade lẹnu 'Pepperito' gẹgẹ bi ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e dabi ti ẹni to ti riran iku ara rẹ ni

Se lo dabii pe o wa n fi ọgbọn sọ fawọn eeyan irufẹ nkan to fẹ bi oun pẹlu ba rewalẹ asa.

Lẹyin to darukọ ara rẹ nigba to dide, ọrọ akọkọ to jade lẹnu Bayọ Oṣinọwọ ni pe,:

' Oni kii ṣe ọjọ ẹkun gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n sọ, bikoṣe ọjọ ọpẹ nitori Ọlọrun ko ba ẹnikẹni da majẹmu lori akoko ti yoo jade laye nigba to da koowa.

Ọlọrun da wa ni laigbọ aroye ẹnikẹni, yoo si mu koowa lọ nigba to ba wuu."

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ọpọ to ti wo fidio naa ni wọn ti ni bi igba ti a pẹ ara sọ oloogbe naa ni o fi sọ ọrọ naa lai mó pe oun pẹlu yoo di ara ilẹ laipẹ jọjọ.

Sẹnetọ Osinọwọ to ni akoko to fun olukuluku o maa gbaradi fun ọjọ afiyesi ni: 'ọpọ la bi ti ko duro ṣe ọdun kan lori oke erupẹ,

Melo la fẹ ka ninu oore Ọlọrun, ọpọ ni ko ri ọdun kẹwaa loke erupẹ. Iku o dọjọ, bẹẹni ko doṣu, gbogbo wa la dagbada iku'

Ni ọjọ Aje, ọjọ karundinlogun ni Sẹnetọ Adebayọ Oṣinọwọ jade laye lẹyin aisan ranpẹ.

senator adebayo osinowo

Oríṣun àwòrán, Twitter/ senator adebayo osinowo

Bayo Osinowo: Ọmọ Ìjẹ̀bú tó wọlé sílé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko nígbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Osinowo, ti wọn ko tii mọ iku to pa a, ni wọn yoo sin lọjọ Ìṣẹgun oni nile rẹ to wa nilu Ijẹbu Ode, nipinlẹ Ogun.

Ni bayii ti asofin agba naa wọ kaa ilẹ lọ lonii, BBC Yoruba ṣe akojọpọ ohun mẹwaa to yẹ kẹ mọ nipa asofin agba naa, to fi ta yọ

Ohun mẹwaa nipa Ṣẹnetọ Adebayo Osinowo:

  • Ọmọ bibi ilu Ijebu Ode, nipinlẹ Ogun ni asofin agba naa, amọ to fi ilu Eko ṣe ibujokoo
  • Oshinowo gba iwe ẹri Diploma ninu ẹkọ imọ ẹrọ nipa ile kikọ ni ilu Rome, to si tun kọ ẹkọ nipa ede orilẹ-ede Italy
  • Bakan naa lo tun gba iwe ẹri keji ninu ẹkọ nipa ibaraẹnisọrọ ni fasiti Urbaniana nilu Rome, nilẹ Italy
  • Oshinowo ti jẹ alaga fẹgbẹ ọdọ ninu ẹgbẹ oselu NPN ni ọdun 1979 lasiko saa isejọba alagbada keji
  • Asofin agba to di oloogbe yii, tun ti fi ọdun mọkanla jẹ alaga igbimọ ile asofin nipinlẹ Eko, eyi to wa fun ọrọ ilẹ ati ilegbe
Àkọlé fídíò, Lockdown in Africa: Nínú Ọlọ́pàá àti Coronavirus, èwo gan an laráàlú ń bẹ̀rù jùlọ?
  • Bakan naa, igba mẹrin ọtọọtọ ni Oshinowo ti soju ẹkun idibo Kosofe kinni nipinlẹ Eko nile asofin ipinlẹ laarin ọdun 2003 si 2019
  • Ibo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọtalerugba ni Oshinowo fi bori alatako rẹ, Gbenga Ashafa ninu ibo to gbe wọle asofin agba lọdun 2019, to si soju ẹkun idibo ila oorun ipinlẹ Eko, labẹ ẹgbẹ oselu APC
  • Pepper abi Pepperito ni inagijẹ ti ọpọ eeyan mọ Oshinowo si, nigba miran, wọn tun maa n pe e ni Unifier abi Stabiliser
  • Ile ẹkọ girama lo wa, ti wọn fi fun ni Inagijẹ Pepper eyes nitori ẹyin oju rẹ to maa n pọn bii ẹrẹ ina, ikekuru rẹ si ni Pepper
  • Adebayo Oshinowo ni iyawo, to si bimọ mẹta, meji ninu wọn lo jẹ onimọ Isegun oyinbo.
Osiniwo

Oríṣun àwòrán, @APCUKingdom

Bayo Osinowo: Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò ìlà-oòrùn ìpínlẹ̀ Eko, Adebayo Osinowo ti d'olóògbé

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo ila-oorun ipinlẹ Eko, Adebayo Osinowo ti jade laye.

Gẹgẹ bi ọrọ ti ẹgbẹ oṣẹlu APC ti ẹka Ilẹ Gẹẹsi fi lede loju opo Twitter rẹ, Osinowo dagbere faye nile iwosan kan ni ilu Eko.

Okiki Osinowo kan lẹyin to fidi Gbenga Ashafa janlẹ ninu idibo abẹnu sipo ṣenetọ to wa ye ninu ẹgbẹ oṣẹlu APC ni ẹkun idibo ila-oorun ipinlẹ Eko lọdun 2019.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Osinowo ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko fun saa mẹrin ọtọtọ, nibi to ti ṣoju ẹkun idibo Kosofe.

Wọn bii ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla ọdun 1955.

Titi di asiko yii, ako tii mọ ohun gan to ṣokunfa iku Sẹnetọ naa, amọ iroyin to gbe e jade pe lẹyin aisan ranpẹ ni.