Osusan Oluwatobi tricycle accident: 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'

"Ki n ma fi kun un ki n si ma yọ kuro, ko tii to iṣẹju kan ti mo wọ inuu kẹkẹ, afi gbaa! tí a gbọ́".

Oṣusan Oluwatobi ko jẹ ara aye ko jẹ ara ọrun nigba ti iye rẹ sọ pada nibi ijamba buruku to mu ọkọ kan ati kẹkẹ alupupu to wọ forigbari.

"Igba ti mo maa fi laju, mo rii pe ero ti pọ gan ti wọn n kigbe pe Haa, obinrin yii ti lọ, oloyun dẹ ni o!"

Iṣẹ ranṣọranṣọ ni iṣẹ Oluwatobi to si ni o wu oun lati kọkọ simẹdọ foju si iṣẹ ọhun daadaa na ki o to da kun bukata rẹ.

Oyun to ni ṣẹṣẹ pe oṣu mẹrin nigba ti iṣẹlẹ naa waye ni. Koda o sọ ifẹ inu rẹ lati ma tii fẹ ni oyun ọmọ ọhun lasiko yii ṣugbọn bi Ọlọrun ṣe fẹ ni.

Ariwo "arabinrin yii ti lọ" ni oun funrarẹ gbọ ninu eti rẹ lọhun to fi laju. Ẹsẹ ti ha o si ti kan sinu Kẹkẹ Maruwa to run jegejege.

Ọjọ keje oṣu kẹta ọdun 2020 ni ọjọ buruku eṣu gbomi mu naa ti Oluwatobi de ọrun bọ̀.

Awọn dokita ni ẹsẹ naa ti bajẹ kọja ala, iṣẹ abẹ si lo gbudọ ṣe ṣugbọn oyun to wa ninu ko lee jẹ́ afi ko gbe oyun naa titi di oṣu mẹsan ninu irora ati titi di oṣu mẹfa akọkọ ọmọ naa.

Iriri Oluwatobi wọ omi loju gbogbo eeyan.

"Ninu ko fọwọ mu ki wọn yọ oyun ki wọn lee ṣe iṣẹ abẹ tori ko lee tilẹ lo oogun ara riro lasan lati din irora ku tori yoo pa ọmọ lara tabi ko fi oyun silẹ ko gbe ninu irora titi.

Ọrọ ba di pe ọkọ yan, iyawo naa yan, awọn mejeeji, ọna ọtọtọ ni wọn gba.