Cure for coronavirus: Ìjọba ti sún wa kan ògiri ló jẹ́ kí a daṣẹ́ sílẹ̀ - ẹgbẹ́ àwọn dókítà

Oríṣun àwòrán, @FcMglobal
Awọn dọkita to n ṣiṣẹ nile ẹkọṣẹ iṣegun ni Naijiria ti sọ pe iya n jẹ wọn lo jẹ ki wọn gunle iyanṣẹlodi.
Aarẹ awọn dokita naa ni ẹka ile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa ni Abeokuta, Adekunle Akeem Jimoh sọ fun BBC pe ijọba apapọ ko ṣe awọn ohun to yẹ ni ṣiṣe lo jẹ ki wọn daṣẹ silẹ.
O ni "Bi a ṣe n lọ si ibiṣẹ, ko si awọn ohun ti a nilo lati fi dabo bo ara wa; bi ibomu atawọn nnkan mii to yẹ ki ijọba pese, ijọba kọ lati pese rẹ."
Jimoh ni lati ọdun 2014 ni ẹgbẹ awọn dokita naa ti n bere awọn ẹtọ wọn lọwọ ijọba apapọ ṣugbọn ijọba ko kọbi ara si awọn ibere naa.
Bo tilẹ jẹ pe wọn wa ni idaṣẹṣilẹ, Jimoh sọ pe awọn dokita ọhun ṣi n ṣetọju awọn to ni arun Covid-19.
Ẹwẹ, Samuel Aluko to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ọhun ni ẹka ile iwosan ijọba apapọ, FMC to wa ni Owo, ni ipinlẹ Ondo ni tirẹ ṣalaye fun BBC pe ijọba ti sun awọn dokita kan ogiri lo jẹ ki iyanṣẹlodi naa waye.

Oríṣun àwòrán, @DamienAjayi
O ni "Ki n ṣe pe o wu awa dokita lati gunle iyanṣẹlodi, ṣugbọn ijọba ko kọbi ara si gbogbo awọn ohun ti a n bere lọwọ wọn."
Dokita ọhun tẹsiwaju pe ko si awọn irinṣẹ to yẹ ki wọn fi dabo bo ara wọn ti wọn ba ti n ṣetọju awọn to ni arun Covid-19.
Aluko ṣalaye pe "Iya n jẹ awọn to n ṣiṣẹ nile iwosan, papa julọ, awọn ile iwosan ijọba ipinlẹ."
"Ọpọlọpọ ni ko gba owo oṣu fun nnkan bi oṣu mẹwaa, awọn miran ko gba owo oṣu fun ọsu mẹrinla, wọn dẹ ni ẹbi sile, iya n jẹ wọn, sibẹ ijọba ko sẹtọju wọn."
Aluko pari ọrọ rẹ pe ko wu awọn awọn dokita lati daṣẹ silẹ ṣugbọn ọrọ naa ti sun wọn.
Lẹyin naa lo ni yoo wu awọn dokita lati pada sẹnu iṣẹ wọn pada lati maa ṣe itọju awọn alaisan, kuku ki ijọba ṣe ohun to tọ nikan lo ku.
Oru ọjọ Aje, ọjọ karundinlogun oṣu kẹfa ọdun 2020 ni awọn dọkita to n ṣiṣẹ nile ẹkọṣẹ iṣegun ni Naijiria bẹrẹ iyanṣẹlodi.














