Yoruba Nation: Gani Adams ní 'Entertainer ní Igboho àti àgbá òfìfo

Oríṣun àwòrán, Gani Adams and Sunday Igboho
Ọrọ idasilẹ orilẹede Yoruba ti di ija agba meji ati isu ata yan-an yan-an lori ayelujara.
Idi ni pe awọn agbaagba meji nilẹ Yoruba, Aarẹ Ọna Kakanfo Iba Gani Adams ati awọn ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho, ti n sọ oko ọrọ si ara wọn.
Koda, ọrọ yii tun ti ran bi ina inu ojo de ọdọ awọn alatilẹyin asaaju Yoruba mejeeji, ti wọn si n sọko ọrọ buruku si ara wọn.
- Ẹ wo àwọ́n lọ́balọ́ba tó ti ṣàtìlẹ́yìn jíjá fún Oduduwa Nation ní ilẹ̀ yorùbá
- Ìròyìn àyọ̀! Wọ́n tí tú akẹ́kọ̀ọ́ FUNAAB tí wọ́n jígbé sílẹ̀, bí orí ṣe kó o yọ rèé
- 'Ìyà ń jẹ́ wá o! Owó osù mẹ́jọ́ há sọ́wọ́ Akeredolu, ẹ́ bá wa wá bẹ̀ ẹ́'
- Ọdún 32 ni mo fi ṣiṣẹ́ oko mọ́ ìṣẹ́ tíṣà kí àwọn ọmọ mi le jẹ́ èèyàn, àmọ́ ikú mú Taiwo lọ - Baba Taiwo Asaniyi
Gẹgẹ bi awọn fidio to n lọ lori ayelujara, awọn agbaagbaa mejeeji naa ni lo n pe ara wọn ni oniruuru orukọ, ori ọrọ idasilẹ orilẹede Yoruba si ni aawọ wọn naa da le lori.
Ohun to sokunfa aawọ Gani Adams ati Sunday Igboho ree:
Fidio kan to n ja rain lori ayelujara lo se afihan Iba Gani Adams to se apejuwe awọn ajijagbara to n pe fun idasilẹ Orilẹede Yoruba bii Adanilaraya lasan, eyi to pe ni "Entertainer".
Gbogbo eeyan lo si mọ pe Sunday Igboho lo n siwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba.
Adams ni oun ni oun kọkọ sawari ikọlu awọn darandaran to n waye lagbegbe Ibarapa naa, ti oun si pariwo fun araye nipa rẹ.
Amọ o ni se ni 'ajijagbara yii' ko ẹrọ ayaworan Kamẹra lọ sibẹ, to si n se bii ẹni to n da awọn eeyan lara ya.
Iba ni Igboho kii se ajijagbara rara, bi ko se Adanilaraya lasan nitori to ba jẹ pe ajijagbara ni, ko ni maa gbe Kamẹra kiri lati polongo ara rẹ.
Bakan naa lo ni agba ofifo lo maa n pariwo kiri, nitori agba to ni omi ninu kii pariwo rara.
Sunday Igboho fesi pada fun Gani Adams:
Ninu fidio mii ti agbẹnusọ fun Sunday Igboho, Olayomi Koiki fi soju opo Facebook rẹ, lo se afihan esi ti Sunday Igboho fọ pada lori orukọ Adanilaraya ti Igboho sọ.
Igboho ni isẹ ijijagbara ti oun n se ko wa lati gba ohunkohun lọwọ ẹnikẹni, bi ko se lati gba ominira fun iran Yoruba.
O ni awọn to ni awọn ti n se isẹ ijijagbara yii lati ọjọ pipẹ, ni wọn n gba owo nidi rẹ, ti wọn ko si le sẹ epe pe awọn ko gba owo.
O ni ọpọ owo ni wọn ti gba, tori owo si ni wọn fi n se isẹ ijijagbara wọn, ọpọ igba si ni oun maa n sẹ epe pe oun ko gba owo lọwọ ẹnikẹni, eyi ti awọn to ni awọn n jija gbara ko le se.
"O yẹ kẹ jẹ ki ori yin pe, kẹ si maa mọ oun ti ẹ maa sọ jade lori ayelujara. Entertainer ni mi lootọ, emi ni Ọlọrun fun.
Iwa ijijagbara mi yii si ni maa fi gba orilẹede Yoruba kuro ni ara Naijiria, agba ofifo tẹ pe mi yii naa ni maa fi gba ominira fun ilẹ Yoruba .
Ti wọn ba to bẹẹ, ki wọn jade lati wa pariwo fun ominira Yoruba, mo mọ pe ko le se bẹẹ nitori to ba se bẹẹ, owo ti awọn araabi gbe fun wọn, wọn yoo beere rẹ pada lọwọ wọn."

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
O ni ẹni to pe oun ni Entertainer ti jẹ dodo, ti ko si le sọ ododo. O ni se bi Restructuring ni wọn kọkọ ni awọn n fẹ, ki wọn to wa pada maa beere fun orilẹede Oduduwa.
Akeem Omiata, olori ẹgbẹ OPC sọko ọrọ pada si Sunday Igboho:
Ohun ti Sunday Igboho sọ ninu fidio naa ti bọ si apo ibinu Alaga ẹgbẹ oselu OPC nijọba ibilẹ Ikosi Isheri nilu Eko, Alhaji Akeem Omiata.
Ninu fidio kan ti Omiata gbe soju opo Facebook rẹ, lo ti ni Sunday Igboho ko sọ idi gun, to si ti gun igi aladi.

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
O ni ọpọ ọrọ ti Sunday Igboho sọ naa ni ko mu laakaye lọwọ, ti awọn to n ti i, si ti tii subu.
"Ẹni to sọrọ si yii kii se ẹgbẹ rẹ, Aarẹ Ọna kakanfo kii se ẹni to maa fi tayin, abi ta lo fi awọn aarẹ to saaju tayin.
Iwọ n fi aarẹ tayin amọ ko le dun mi fun ọ nitori gbogbo awọn ọba lalaye lo ti sọrọ si tan patapata.
Bakan naa lo tun n sọrọ si Baba Adeboye, to n yọ wọn pe ọmọ wọn ku, to ba kawe, se o ko ka ọgbọn inu ni."
Bakan naa tun ni Omiata ni Igboho yoo gba nipa iwa to hu, ti Igboho yoo si mọ pe oun ko jẹ nkankan.
Awọn ọrọ yii si lo n ti n da ori ayelujara laamu bayii.





















