Ondo workers salary: Ìyà ń jẹ́ wá! Owó osù mẹ́jọ́ há sọ́wọ́ Akeredolu

Egbẹ́ àwon òṣìṣẹ́ ilé-ìwe gbogbonìse ìlú Òwò dá rúgúdù sílẹ̀ lòní bí wón se gbégi dí ẹnu ònà àbáwọlé ọ̀gbà ilé-ìwé náà látàrí àjẹsílẹ̀ owó oṣù mẹ́jọ tí ìjoba jẹ wọ́n.
Àwon òsìsẹ́ náà sọ pé kò sí ẹni tí ó gba ìgbéga lẹ́nu isẹ́ láti bíi ọdún mẹta sẹyìn èyí tí ó jẹ kí wón dàbíi adágún odó.
Àwon olùfẹ̀hónúhàn ọ̀hún tí olórí ẹgbẹ́, Adébáyó Obayoríadé ṣaájú, tún fẹ̀sùn kan àwọn aláṣẹ ilé-ìwe náà pé owó tí ó tó irinwó miliọ̀nu naira ni wọ́n yọ nínu owó osù àti àpò ẹgbẹ́ alajẹṣẹku wọn.
Obayoríadé ẹni tí ó jẹ́ Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òsìsé tí kì n se olùkọ̀ni NASU sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn kan pàdánù ẹ̀mí wọn látàrí aìsí owó láti tójú aìlera ara wọn tí wọn sì n wa ọ̀nà mìíràn láti jẹun.
"Níbí oṣù díẹ̀ sẹ́yìn a pàdánù ọ̀gbẹ́ni Jamiu làti ẹ̀ka Maintenance, ó ní ìjàmbá ọkọ̀ lásìkò tó n wá ọ̀nà àtijẹ míràn láti lè tọ́jú ẹbí rẹ̀ nítorípé kò gba owó osù fún ọ̀pọ̀ oṣù".
"Àwọn onílé kò fẹ́ fún wa nílé mọ́, lórí ìbẹ̀rù pé a kò ní r'ówó ilé san. A kò lè bọ́ àwọn ọmọ wa mọ́ tàbí san owó ilé ìwé. Ñkàn ò fararọ mọ́".
"Gbogbo ọ̀sẹ̀ ni mò ń lọ sí ilé ìwòsàn láti lọ wo ọmọ ẹgbé látàrí àwọn ìṣòro tó ń jẹyo bíi owó kò ṣe wọlé déédé."

Akitiyan, olùdarí ilé èkò náà, Gani Ogundahunsi láti pẹ̀tù sì wọn lọ́kàn ló jà sí òfo.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí tí àwọn òsìsẹ́ náà ti kọrin, wọ́n bá kẹnu bọ adúrà pé ti àwon olórí wọn ò bá sọ̀rọ̀, àwọ́n ò ní sinmi ìyanṣẹ́lódì.
Ọpẹ́lọpẹ́ Ọba Ọlọwọ ti ilu Ọwọ, Ọba Ajibade Ogunoye to ba wọn sọ̀rọ nigba ti aṣoju rẹ to ran to jẹ akọwe rẹ pẹtu si wọn ninu, wọ́n fẹnukò pé won yio fòpin sí ifẹhonuhan náà laarin osù méjì.
Orí Adé náà, ẹni tó gba ẹnu Akòwé rè, Amos Aladeseye sọ̀rọ̀ sèlérí láti bá gómínà sọ̀rọ̀ lójúnà àti wá ojutu sí ọ̀rọ̀ náà.













