Timbuktu global Yoruba: Ilé ìtajà aṣọ̀ kan ti ra orúkọ Yorùbá tí ẹnikẹ́ni kò fi ní le lò ó mọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin kan ti n lọ kaakiri ori ayelujara pe, ileeṣẹ kan ni United Kingdom, ti ra orukọ ẹya Yoruba pa.
Ile ẹkọ kan to n kọ awọn ọmọde ni ede Yoruba lori ayelujara, Culture Tree, lo fi iroyin naa sita.
Ile ẹkọ naa sọ pe lasiko ti awọn lọ si ileeṣẹ ijọba to n ri si rira orukọ ileeṣẹ, ti wọn n pe ni Trademark ni ede Gẹẹsi, lati ra orukọ kan fun awọn akẹẹkọ ile ẹkọ naa, ni wọn sọ fun wọn pe wọn ko ni le ra orukọ ti wọn mu wa, Yoruba Stars, nitori pe o ni yoruba ninu.
Eyi lo mu ki ile ẹkọ naa o beere pe bii ti bawo?
Nibẹ si ni awọn alakoso ileeṣẹ to n ri si iforukọsilẹ ọhun ti ṣalaye pe ileeṣẹ kan to n ta aṣọ nilu Lancashire, Timbuktu, ti sanwo fun orukọ Yoruba lati ọdun 2015.
Ninu atẹjade to fi sita, olusasilẹ ileewe naa, Gbemisola Isimi sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe wọn gba ileeṣẹ kan laaye lati ra orukọ to jẹ orukọ ẹya ati ede ogunlọgọ miliọnu eniyan.
O ni ileeṣẹ iforukọsilẹ gba orukọ ti oun fẹ ẹ lo na, ṣugbọn lẹyin oṣu diẹ ni wọn kọ lẹta si oun pe ileeṣẹ Timbuktu ko faramọ ọ.
"Wọn sọ fun mi pe ileeṣẹ Timbuktu tako orukọ ti mo fẹ ẹ ra, wọn si ti n gbe igbesẹ lati fofin de ẹnikẹni lati ma lo orukọ to ba ni Yoruba ninu fun orukọ ileeṣẹ wọn.
Gbemisola Isimi sọ pe oun gbe igbesẹ ni ilana ofin lẹyin ti Timbuktu sọ pe awọn yoo ta orukọ Yoruba wọn fun oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Mo kọ igbesẹ wọn, mo si sọ fun wọn pe mi o ni owo kankan lati san fun wọn. Kilode ti wọn fẹ ẹ ta orukọ naa, to ba jẹ pe o jẹ wọn logun?"
O ni lẹyin naa ni ileeṣẹ Timbuktu ti gbe ọrọ lọ si ile ẹjọ, ti igbẹjọ yoo si bẹrẹ ninu oṣu Keje.
Nkan to yẹ ki o mọ nipa ileeṣẹ Timbuktu?
Ileeṣẹ Timbuktu jẹ ileeṣẹ kan to n ta aṣọ ọkunrin ati obinrin nilẹ Gẹẹsi.
Ọdun 2015 si lo bẹrẹ.
Ọmọ ilẹ Gẹẹsi meji to wa lati North England ni oludasilẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orukọ ti wọn sọ ileeṣẹ naa, Timbuktu jẹ orukọ ilu kan lorilẹ-ede Mali, nilẹ Africa.
Ṣugbọn ileeṣẹ naa kọ si ori ayelujara rẹ pe Timbuktu jẹ "ilu kan ninu ààlọ́, to jina, to si jẹ́ ilẹ ajeji nibi ti onikaluku ti le wa isinmi ati igbadun fun ara rẹ.
Kini Trademark tumọ si?
Kaakiri agbaye ni wọn ti ma n ṣe eto rira orukọ fun ileeṣẹ tabi eto, eyi ti wọn n pe ni Trademark.
Nkan to tumọ si ni pe ẹnikẹni to ba da ileeṣẹ silẹ, tabi ni orukọ kan to ṣe pataki si iru gbajumọ bẹẹ le lọ si ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ Trademark lati fi orukọ naa silẹ.
Ẹni naa yoo san owo fun ijọba lati ra orukọ naa patapata, eyi ti ko ni fun ẹlomiran ni anfaani lati lo lara orukọ naa tabi lo gbogbo rẹ.
Nigbakuugba ti ẹni naa tabi ileeṣẹ ba n kọ orukọ wọn, wọn yoo fi ami ™ si ẹgbẹ orukọ tabi ami idanimọ ti wọn ra.
Eniyan le ra orukọ ileeṣẹ, inagijẹ, ọrọ, nọmba, gbolohun tabi ami idanimọ, ṣugbọn eeyan meji tabi ileeṣẹ meji ko le ra orukọ kan naa.
O si le pe ẹnikẹni to ba ya lo ninu orukọ naa l'ẹjọ.
Kini awọn amuyẹ lati ṣe Trademark ni Naijiria?
Ni orilẹ-ede Naijiria, ileeṣẹ to wa fun eto okoowo lo n mojuto fifi orukọ silẹ fun Trademark.
O si ma n to oṣu mejila si oṣu mejidinlogun ki iforukọsilẹ naa to yọri.
Ẹnikẹni ti ko ba faramọ iforukọsilẹ le kọwe si ajọ naa pẹlu awijare rẹ. Bi awijare naa ba ṣe l'agbara to ni yoo sọ boya ẹni to fẹ ẹ ra orukọ yoo ṣe aṣeyọri tabi bẹẹkọ.
Ọdun meje ni eeyan fi le lo ami Trademark rẹ, lẹyin naa ni yoo ma fi owo ra a pada ni ẹẹkan laarin ọdun mẹrinla.
Ṣugbọn, ijọba le gba aṣẹ naa pada ti ẹni to ni i ko ba lo ami Trademark to ra laarin ọdun marun-un, tabi ti ko ni idi pataki to fi ra a, tabi to ba kuna lati sanwo irapada lẹyin ọdun meje akọkọ.
Kini awọn ọmọ Nigeria n sọ lori ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ Timbuktu?
Lati igba ti ile ẹkọ Culture Tree ti fi iroyin naa sita ni awọn ọmọ Nigeria, paapaa awọn ọmọ Yoruba ti n fi apa janu lori ayelujara.
Ọpọlọpọ wọn si lo ri igbesẹ ileeṣẹ Timbuktu gẹgẹ bi iwa afojudi ati ikọjaaye.














