NYSC: Ìjọba àpapọ̀ ní kò sí gìrì lórí ètò àgùnbánirọ̀ NYSC ní Nàìjíríà

Aworan agunbaniro

Oríṣun àwòrán, Twitter/@nysc_ng

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya, Sunday Dare ti ṣalaye pe ijọba apapọ ko ni tẹti lati rii daju pe eto agunbanirọ lorilẹede Naijiria n tẹsiwaju sii.

Minisita Sunday Dare sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ ninu eyi to ti jẹ ko di mimọ pe eto agunbanirọ lorilẹede Naijiria kun ara awọn eroja pataki ti ijọba fi n peeli ikokoọbẹ idagbasoke to loorin fun awọn ọdọ.

Ọrọ yii n jẹyọ lẹyin ti iroyin jade pe awọn aṣofin apapọ lorilẹede Naijiria n gbero abadofin kan ti yoo wọgile eto agunbanirọ lorilẹede yii. Abadofin naa ti kọja ipele kika akọkọ ni ileegbimọ aṣoju-aṣofin

Minisita f'ọrọ ọdọ ati ere idaraya ni awọn atunto to loorin ti n lọ lọwọ lori eto naa ati pe orilẹede Naijiria ko ni fi awọn ọdọ rẹ silẹ.

Àkọlé fídíò, Mo máa ń déédé ṣubú lulẹ̀, tẹ́ẹ bá fi ọwọ kàn mí lásán, kódà lójú ọ̀nà márosẹ̀ - Fatimah

Ìdí tí àwọn aṣòfin ṣe fẹ fagilé NYSC, ohun táa mọ rèé

Abadofin ti awọn aṣofin gbe ka iwaju lori pe ki wọn da eto agunbanirọ duro ni Naijiria ti kọja kika fun igba akọkọ bayii.

Iroyin to n gbode kan ni pe aṣofin Họnọrebu Awaji-Inombek Abiante to n ṣoju kun Opobo/Nkoto lo mu aba naa wa gẹgẹ bo ṣe tska si ọrọ iṣoro abo to wa lorilẹede Naijiria ni lọọlọ yii.

Ninu abadofin naa, o sọ pe "ipaniyan to n peleke sii to si kan awọn agunbanirọ naa lawọn ipinlẹ kan nitory awọn ikọlu adigunjale, ija ẹsin ati ẹlẹyamẹya.

Àkọlé fídíò, A ti ń fẹ́ Hausa, Ibo, ó sàn ka jọ ṣe é ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ju ìjà ogun lọ - Ọba Alara

"Ati ileeṣẹ ijọba ati ti aladani, ko si eyi to n gba awọn ọdọ Naijiria to koju osuwọn mọ paapaa bi wọn ṣe n deede da awan agunbanirọ silẹ lawọn ileeṣẹ ni kete ti wọn ba ti pari isinru ilu lai fun wọn ni ireti pe wọn yoo ri iṣẹ".

O ni nibayii, ipenija aabo ti mu ki wọn maa pin awan agunbanirọ si agbegbe wọn gangan eyi to si ba ọkan lara eredi pataki ti wọn fi da eto agunbanirọ silẹ jẹ eyi to jẹ mimu idagbasoke ba irẹpọ laarin awọn ọdọ Naijiria fun isọkan ati ibaṣepọ laarin oriṣiriṣi ẹya.

Nibayii, abadofin naa ti ṣaṣeyọri la kika fun igba akọkọ kọja.

Ki ni wọn n ṣe ninu eto NYSC gan?

Eto isinruulu jẹ eto ọlọdun kan to pọn dandan fun awọn akẹkọja ileewe giga ni Naijiria ti ko ba tii pe ọgbọn ọdun.

Ọna ti wọn maa n gba pin wọn ni pe ẹni to ba jẹ ọmọ ẹkun ariwa loke ọya, yoo gba iwe lati lọ si bii iha Guusu Naijria.

Ọsẹ mẹta gbako ni wọn yoo fi gba ẹkọ lọdọ awọn oṣiṣẹ afara jologun ki wọn to lọ bẹrẹ iṣẹ ni ileewe, họsibitu, banki, atawọn ileeṣk aladani mii ti ajọ naa ba pin wọn si.

Amọ ni asiko yii, wahala aisi aabo lorilẹede ti ṣakoba fun eto yii gẹgẹ bi iroyin wọn n pa agunbanirọ kaakiri ati jiji wan gbe ṣe n peleke sii.

Ki ni yoo ti ibi abadofin fifagile NYSC wa?

Idahun si ibeere yii ko tii jade toripe o ṣẹṣẹ kọja kika fun igba akọkọ ni.

Ki abadofin kankan to le di ofin ni Naijiria, o gbudọ jajabọ gba ipele kika mẹta kọja nile igbimọ aṣofin yoo si tun gba waju awọn igbimọ naa kọja.

Lkyin eyi, wan yoo fi ṣọwọ si ile igbims aṣofin agba ti wọn yoo si ni lati gba a wọle ki aarẹ orilẹede to buwọlu u lati di ofin.

Eleyi ks ni igba akọka ti wan n gbe ọrọ boya eto naa ṣi wulo siwaju ile fun ijiroro.

Amọṣa ọrọ yii ti rin wọ ori ayelujara ti awọn ọmọ Naijiria kan si n to sẹyin pe ki wọn fagile eto agunbanirọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Ni ijọba ologun ni saa ijọba Ọgagun Yakubu Gowon ni wọn ṣe agbekalẹ eto agunbanirọ lọjọ kejilelogun oṣu karun, ọdun 1973 gẹgẹ bi ọna lati fopin si aala ti ogun ti pa si aarin awọn araalu nigba ogun abẹle to waye laarin ọdun 1967 si ọdun 1970.

Awọn ọmọ Naijiria mii ni awọn ko fẹ ki ijọba fagile e tori awọn anfani ti wọn gbagbọ pe o n ti ara rẹ wa fun orilẹede.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4