FUNAAB kidnap: Akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbé lọ ló ń rán ara rẹ̀ nílé ìwé

Fasiti FUNAAB

Oríṣun àwòrán, Eke Isaac

Akẹkọọ fasiti ti wọn ti n kẹkọọ eto ọgbin ni Abeokuta, FUNAAB to wa lahamọ awọ́n ajinigbe ti gba itusilẹ pada.

Akẹkọọ naa, Toyinbo Olayinka wa ni ipele kẹ́rin tii ṣe aṣekagba, wọn ji i gbe lọjọ Abamẹta to kọja ni agbegbe Abule Itoko to to iwọn kilomita mẹwa si ọgba ileewe naa.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Eke Isaac

Alukoro fasiti FUNAAB to kan si BBC, Kola Adepoju lo sọ aridaju pe wọn ti da a silẹ lalafia lalẹ Ọjọ Aje. Eyi jẹ lẹyin ti awọn akẹgbẹ rẹ ṣe iwọde ninu ileewe.

Ọgbẹni Kola ko sọ boya awọn ajinigbe kan da a silẹ tabi ẹnikẹni san owo idoola rẹ.

Àkọlé fídíò, A ti ń fẹ́ Hausa, Ibo, ó sàn ka jọ ṣe é ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ju ìjà ogun lọ - Ọba Alara

"Lai si ipalara, ninu ilera pipe ni wọn tu u silẹ. Ẹkunrẹrẹ lori itusilẹ rẹ ko pọ ati pe gbogbo ẹ wa lọwọ awọn Ọlọpaa ipinlẹ Ogun".

O ni lorukọ awọn alaṣẹ ileewe fasiti naa, awọn dupẹ fun awọn oṣiṣẹ alaabo, atawọn to jẹ ti ijọba ateyi ti kii ṣe tijọba paapaa ileeṣẹ Ọlọpaa Ogun.

Atawọn oniroyin to fi mọ awọn lọbalọba ati gbogbo awọn ti ọrọ̀ kan ni wọ́n ranṣẹ idupẹ si lori itusilẹ akẹkọ naa.

Akẹ́kọ̀ọ́ FUNAAB tí wọ́n gbé lọ ló ń rán ara rẹ̀ nílé ìwé

Agbẹnusọ fun Fasiti ti wọn ti n kẹkọọ eto ọgbin, FUNAAB, Adepoju Kola, ti sọ pe akẹkọọ ti ile ẹkọ naa, Olayinka Toyinbo ti awọn ajinigbe gbe lọ kii ṣe agbegbe ile ẹkọ naa ni wọn ti gbe e lọ.

Ọgbẹni Kola ṣalaye pe ni abule kan ti wọn n pe ni Itoko ni ijọba ibilẹ Odeda ni wọn ti gbe Toyinbo lọ nibi to ti n ba ẹnikan ṣiṣẹ ninu oko rẹ.

''O ṣeni laanu pe akẹkọọ yii lo n ran ara rẹ lọ si ile ẹkọ plu iṣẹ ti o n ṣe".

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Ati pe lori oko to ti n ṣiṣẹ naa ni o ti n sun ki iṣẹlẹ ọhun to ṣẹlẹ,'' Ọgbẹni Kola ṣalaye.

Lori boya awọn ajinigbe n beere fun owo itusilẹ fun akẹkọọ naa, Kola ni oun ko le sọ ohun kan nipa ọrọ naa.

''A ti fa ọrọ naa le ọlọpaa lọwọ, awọn ọlọpaa yii ṣi ti n ṣiṣẹ takun takun lati ri pe wọn doola akẹkọọ naa lakata awọn ajinigbe.

A ko tiẹ fẹ maa pariwo gan an lori ọrọ yii ki o maa ba ṣakoba akẹkọọ wa to wa lakata awọn ajinigbe.

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Eke Isaac

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Eke Isaac

Awọn akẹkọọ akẹgbẹ rẹ tu yaya jade lati ṣe ifẹhonuhan lori bi wọn ti ji Toyinbo gbe lọ.

Amọ iwọde alaafia ni wọn ṣe, ọdọ awọn ọlọpaa ni wọn ṣe iwọde lọ lati fi ẹhonu wọn han, wọn ko si ba ohun kohun jẹ,'' agbẹnusọ fasiti FUNAAB lo sọ bẹẹ.

Ọjọ Abamẹta ọsẹ to lọ ni wọn gbe Toyinbo lọ ti wọn si n wa di akoko yii.