Major General Faruk Yahaya: Òun lo n dari ikọ ọmọogun to n gbogun ti iwa igbesunmọmi lọ́wọ́

Olori ilee ologun tuntun, Ọgagun Farouk Yahaya

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ni ọsan ọjọbọ ni ileesẹ aarẹ kede olori ọmọ ogun tuntun fun ileesẹ Ologun Naijiria, Oluwarẹ si ni Ọgagun Faruk Yahaya.

Saaju iyansipo Yahaya yii ni ẹnu ti n kun oun ati awọn ọga ologun marun miran pe o seese ki wọn yan ọkan lara wọn bi olori ileesẹ ologun ilẹ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibayi ti aarẹ Buhari ti wa fontẹ lu ọga ologun naa, awọn ohun marun to yẹ kẹ mọ nipa akikanju ọga ologun naa ree.

Ohun marun pataki nipa Ọgagun Faruk Yahaya:

  • Ipinlẹ Zamfara ni Faruk Yahaya tisẹ wa, to si di ipo gboogi mu ni ikọ ọmọogun Naijiria
  • Olori ileesẹ ologun tuntun yii lo ti jẹ ọga ologun pata tẹlẹ, to n dari ọwọ kinni ileesẹ ologun ilẹ wa
  • Saaju lo ti fi igba kan di ipo adari olu ileesẹ ọwọ kẹrin ọmọogun ilẹ Naijiria mu, (4th Brigade Headquaters)
  • Ọgagun Faruk Yahaya tun ti jẹ oludari ibudo ti wọn ti n se idanilẹkọ atigbadegba, ti wọn pe ni Regular course 37 nile ẹkọ ologun ilẹ wa to wa nilu Kaduna
  • Ọgagun Faruk Yahaya lo n dari ikọ ọmọogun to n gbogun ti iwa igbesunmọmi Boko Haram lọwọlọwọ ni ariwa orilẹede Naijiria.
Amin iyasọtọ kan

Àwọn Ọ̀gágun tó ṣeéṣe kó gba ipò olórí àwọn ọmọogun lẹ́yìn ikú Attahiru nìyìí

Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Lẹyin iku olori awọn ikọ ọmọogun ori-ilẹ ni Naijiria, Ọgagun Ibrahim Attahiru, ibeere ti awọn eniyan n beere ni ẹni ti yoo rọpọ ọgagun naa.

Opin ọsẹ to kọja ni Ọgagun Attahiru ati awọn ọmọ ikọ ologun mẹwaa miran ki aye pe odigba-oṣe lẹyin ijamba ọkọ baalu to gbẹmi wọn ni ilu Kaduna.

Attahiru lo gba ipo lọwọ ọgagun Tukur Buratai lati gbogun ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram to n fa eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri ariwa orilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari ati awọn eekan lorilẹede Naijiria ti kan saara si Attahiru gẹgẹ bi akọni to ṣiṣẹ takuntakun lati gbogun ti iwa ọdaran lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Tani yoo rọpo Attahiru gẹgẹ bi Adari ikọ ọmọogun ilẹ ni Naijiria?

Awọn onimọ ni ẹka eto aabo lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ si ni darukọ awọn to ṣeeṣe ki wọn gba ipo olori ikọ ọmọogun ilẹ ni Naijiria, lẹyin iku Ọgagun Attahiru Ibrahim.

Iroyin lati ileeṣẹ aarẹ tilẹ sọ wi pe ko nipẹ rara ti aarẹ Buhari yoo fi yan adari miran lọna ati gbogun ti eto aabo to mẹhẹ.

Lara awọn ti o ṣeeṣe ki wọn di ipo yii mu ni Major General Danjuma Ali-Keffi, Major General Ben Ahanotu, Major General AM Aliyu, Major General Ibrahim Manu Yusuf ati Major General Faruk Yahaya,

Ọgagun Danjuma Ali-Keffi

Ọgagun Danjuma Ali-Keffi lo di ipo adari awọn ikọ ọmọogun to wa ni ipinlẹ Kaduna, oun ni commander of the national army ni Kaduna.

Ọpọlọpọ eniyan gbagbọ wi pe o ṣeeṣe ko jẹ oun ni aarẹ Buhari yoo yan sipo, amọ wọn ni lati ni ki awọn to wa ni iwaju rẹ to le ni ọgbọn lọ tete fẹyinti.

Eleyii tumọ si wi pe awọn ọgagun to wa niwaju yoo padanu iṣẹ wọn lasiko ti wọn nilo wọn julọ.

Amọ ni awọn orilẹede miran ẹni to ba kunjuwọn julọ ni wọn ma n yan sipo lai fi ti ọjọ ori tabi ọgagun to wa nipo to gajulọ yan ẹnikẹni sipo.

Ọgagun Ben Ahanotu

Ọgagun Ben Ahanotu jẹ ọkan gboogi ninu awọn onimọ nipa eto aabo ni Naijiria, ti o si mọ nipa gbigbogun ti igbesunmọmi gẹgẹ bi iṣẹ to yan laayo.

Ipinlẹ Anambra ni Ahanora ti wa ti o si gbo ede ṃẹrin ti wọn sọ lorilẹede Naijiria to fi mọ Hausa.

Ahanotu ni asaaju ikọ ọmọogun to mu olori awọn agbesunmọmi Boko Haram, Muhammed Yusuf ni ilu Maiduguri ni ọdun 2009.

Àkọlé fídíò, Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

Ọgagun AM Aliyu

Ọgagun AM Aliyu naa pegede ninu awọn ti yoo le di ipo olori ikọ ọmọogun Naijiria, nitori imọ rẹ nipa eto aabo ati otẹlẹmuyẹ.

Ipinlẹ Gmbe ni o ti wa, ti o si ti di ipo adari eto ati ise ni ileeṣẹ ikọ ọmọogun Naijiria.

Ọgagun Faruk Yahaya

Ọgagun Faruk Yahaya lo n dari ikọ ọmọogun to n gbogun ti Boko Haram lọwọlọwọ ni iwọ ariwa orilẹede Naijiria.

Ipinlẹ Zamfara ni Faruk Yahaya tisẹ wa, to si di ipo gboogi mu ni ikọ ọmọogun Naijiria.

Saaju o ti fi igba kan di ipo adari ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria ri, iyẹn Commander of the Armed Forces.

Ọsẹ yii ni awọn eniyan n woye wi pe aarẹ Buhari yoo kede ẹni ti yoo di ipo olori ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria mu, ti yoo si ṣiṣẹ takuntakun lati ripe opin deba eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.