Genesis Global: Bí Ọlọrun ṣe lò mí fún Musiliu tò ti lo ọdún 11 lọgbà ẹwọn ti mo lọ

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Wolii Isreal Ogundipe Oladele Israel ti ọpọlọpọ mọ si Genesis ni oun rii daju pe akoko ti wọn wa fi ọ̀lọ́paa gbe ohun jẹ eyi ti awọn to ṣe e to daadaa ni. O sọ ẹkunrẹrẹ idi to fi ro bẹẹ fun BBC yoruba.

O ṣalaye pe ọgba ẹwọn ti oun lọ "jẹ ibi ti kii ẹ ibi too ti le jẹ́un to wu ẹ tabi ri iyawo abi ọmọ. O jẹ ibi ti ẹni ti ko ṣẹ ti lee ba ara rẹ boya tori Ọlọpaa ko ṣe ẹjọ daadaa".

Awọn ọmọ ijọ Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global

BBC Yoruba gbera lọ si ile ati ijọ gbajugbaja Wolii ti wọ́n dajọ́ ẹwọn ọdun kan gbako fun amọ ti gbogbo eeyan dede gbọ pe o ti kuro lọgba ẹwọn lai tii lo ọdun meji oloṣu mejila naa pe.

Wolii Genesis ni ṣugbọn ẹni to ba ni Kristi a kan mọọmọ gba fun Ọlọrun ni pẹlu ohun toju rẹ yoo ri lọgba ẹwọn.

Genesis

Oríṣun àwòrán, Genmesis Global

Ẹsun jibiti to to miliọnu mọkanla naira ni wọn fi kan Wolii Genesis eyi to pa ohun ati arabinrin kan, Laide Oni Williams to n gbe ni UK pọ.

Wolii Genesis sọ ohun toju ri ati ohun to ba bọ lati ọgba ẹwọn to lọ bọ tori wọn da a silẹ lẹyin oṣu mẹrin to bẹrẹ ijiya ẹsun naa dipo ọdun kan to yẹ ko lo nibẹ.

Ọrọ naa wa dabi owe kan to sọ pe igba gbogbo ni ọrọ kii ṣi lori alabahun tori bi ọpọlọpọ eeyan ṣe maa n wo awọn iranṣẹ Ọlọrun to ba ti ni iru idojukọ yii.