Vaginal fluid transplants: Àlàyé bí o ẹ lè ra omira abẹ́ obìnrin rà tàbi fi tirẹ silẹ̀ fún títà?

Obinrin to la idi silẹ

Oríṣun àwòrán, María Conejo/BBC

Àwọn aṣewadii ti wu u jade, ohun ti kokoro inu ẹnu ni ṣe pẹlu awọn kokoro to n dagba ninu oju ara obinrin.

Awọn dokita orilẹede Amẹrika ti n gbero rẹ lati ọdun 2019 pe ki wọn bẹrẹ si ni ṣe agbekalẹ eto lati maa ṣayẹwo omi abẹ obinrin fun lilo.

Wọn gbagbọ pe awọn obinrin kan le jẹ anfani latara omira to wa ni ilera pipe latara obinrin eyi to lee wulo ninu didoju ija kọ arunkarun ti wọn n pe ni bacterial vaginosis(BV).

Ikọ kan lati fasiti Hopkins sọ pe nkan to fun awọn ni iwuri ni aṣeyọri ti wọ́n ṣe nibi ti gbigba igbẹ ẹlomiran lo.

Bo tilẹ jẹ pe ogun to n wo arun BV san wa, o tun maa n pada wa nigba miran.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Ki lo n jẹ aisan BV gan?

BV

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arun BV yii kii fi bẹẹ ṣe eyi to le to bẹẹ ṣugbọn o dara ki eeyan ṣe itọju ara rẹ to ba ko o toripe o maa n dakun bi obinrin ṣe le tete ko awọn arun ibalopọ STD ati UTIs.

Bi obinrin naa ba wa loyun pẹrẹ, o ṣeeṣe ko ṣokunfaa bibi ọmọ ti ko tọjọ.

Kini yii wọpọ, bẹẹ si ni awọn obinrin to ni aisan naa maa n rii pe oje to n jade lati oju ara wọn a maa run tuu bi ẹja.

O tun ṣeeṣe ki o rii pe awọ nkan to n jade ati kiki r ti yipada si bii awọ eeru ti ko funfun mọ bẹẹ si ni o maa ṣan.

Oju ara obinrin

Oríṣun àwòrán, Emma Russell

Kí ni anfani to wa ninu yiyọnda omi abẹ eeyan fun ẹlomiran lati lo?

Awọn aṣewadii ti n wa ohun to mu u wulo yatọ fun liloo lati wo aisan awọn obinrin to ti ko arun bacterial vaginosis, wọn si ti ri iwe aṣẹ alamojuto gba lọdọ ajọ to n ri si ilokulo ogun ati ounjẹ.

Wọ́n ti ṣayẹwo awọn kan to fi tiwọn silẹ fun ayẹwo esi wọn si jade ninu iwe iroyin igba de igba Journal Frontier labẹ imọ ẹkọ Infection Microbiology.

Pẹlu iye obinrin ogun ti wọn yẹwo, awọn aṣewadii ni awọn ti ri nkan to lee tọka si ẹni to koju osuwọn lati fi omi abẹ silẹ.

"Sampu omi abẹ obinrin ti kokoro Bacterium Lactobacillus crispatus ṣeeṣe ko ni eroja aabo to lagbara to n jẹ lactic acid eyi to lee wulo gidi gan.

Fun abo wọn, wọn yoo ni ki awọn oluyọnda yago fun ibalopọ fun o kere tan ọgbọn ọjọ ki wọn to lee fi apẹrẹ omi abẹ wọn silẹ ti wọn yoo si ẹ ayẹwo rẹ to fi mọ boya arun HIV wa ninu rẹ ki wọn ma baa ko o ran ẹni ti yoo lo omi abẹ naa.

Àkọlé fídíò, Mo máa ń déédé ṣubú lulẹ̀, tẹ́ẹ bá fi ọwọ kàn mí lásán, kódà lójú ọ̀nà márosẹ̀ - Fatimah

Ọkan lara awọn aṣewadi naa ni "funra oluyọnda ni yoo gba omi abẹ ara rẹ eyi taa m pe wọn yoo fẹran ju".

Obinrin naa yoo ki ike rọba fẹlẹfẹlẹ kan bọ oju ara rẹ lati gba sampu naa.

"O ya kiakia o si rọrun, bi wọn ba si gba sampu kan lasan, o lee to fun iwọn iye ti wọn lee gbe si oju ara ẹlomiran".

Dokita Ensign ni bi awọn ba ri iranw owo, iṣẹ naa yoo maa ya kiakia. "Lara awọn oluyọnda taa ri ni awọn ti ṣetan lati kopa ninu rẹ.

"A ti pinu lati ṣe eto gbigbe omi abẹ tuntun naa si oju awọn obinrin ogoji ka fi bẹrẹ na. bo tilẹ jẹ pe gbogbo wọn naa ni yoo ṣi gba oogun ti a maa n lo tẹlẹ.