Fatimah Aderounmu's muscular dystrophy: Bí Ọlọ́run ṣe gbé àdánwó yìí lé mi lọ́wọ́ rèé

Àkọlé fídíò, Mo máa ń déédé ṣubú lulẹ̀, tẹ́ẹ bá fi ọwọ kàn mí lásán, kódà lójú ọ̀nà márosẹ̀ - Fatimah

"Ìgbà tí Dókítà sọ fún mi pé ipò tí mo máa wà títí láé rèé, mò rò pé ayé ti fẹ́ parẹ́".

Arabinrin Fatimah Aderounmu to jẹ ẹni ọdun mejilelogun ni ipenija aramanda yii n ba finra to maa n mu iṣan eeyan dede rẹwẹsi ti yoo rọ jọ. Awọn oloyinbo n pe aisan naa ni "muscular dystrophy".

"O maa sabaa ṣakoba fun ọmọde diẹ diẹ lati ẹsẹ tabi nigba mii ko ki wọn ni gbogbo ara kija".

Fatimah Aderounmu

Fatimah ni o maa n mu ara eeyan kaarẹ fun ọpọlọpọ ọjọ, to ba ya yoo pada yi si arun rọpa rọsẹ titi ayeraye.

Titi di oni, awọn onimọ iṣegun oyinbo ko tii ri oogun kankan gbe jade lati koju aisan naa.

Fatimah sọ fun BBC Yoruba pe lati igba ti oun ti wa lọmọ ọdun mọkanla ni Dokita ti kede fun oun pe o ni aisan yii latigba naa lo si ti wa lori aga oni kẹkẹ arọ ti ko si lee gbe ara rẹ.

Nibayii, fatimah ti na 'gbara o ti na 'gboro ninu irir rẹ to si ti da ẹgbẹ kan silẹ lati maa da awọn eeyan lẹkọọ nipa ohun to n jẹ muscular dystrophy to si fi n kowo jọ fun iranwọ awọn to wa ninu iru ipo tirẹ.