Ban on open grazing: Akeredolu, yé rí Ààrẹ Buhari fín mọ́; nǹkan tí ààrẹ fẹ́ ni Garba Shehu sọ -BMO

Oríṣun àwòrán, Presidency
Ẹgbẹ kan to n risi ifọnrere Buhari, Buhari Media Organization (BMO) ti ranṣẹ ọrọ si gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lori esi to fọ pada si amugbalẹgbẹ aarẹ Buhari, Garba Shehu.
Wọn ni esi to ranṣẹ fun igbesẹ ti aarẹ Buhari ṣẹṣẹ gbe kalẹ fun didẹkun wahala laarin awọn darandaran ati agbẹ fihan pe ko fi ọwọ fun ọfiisi aarẹ.
Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa, Niyi Akinsiji pẹlu Cassidy Madueke to jẹ akọwe fọwọsi, wọn ni ọrọ ti gomina Akeredolu sọ ku diẹ kaato lori ipinnu ti aarẹ gbe kalẹ lati da awọn igbo ọba pada gẹgẹ bi ara ọna to ṣee mulo dipo kiko maalu jẹko kiri igboro eleyi ti awọn gomina lẹkun gusu orilẹede Naijiria n tako laifi ọna abayọ to tọ silẹ.
Wọn bu ẹnu atẹ lu Gomina Akeredolu fun fifi ọwọ si atẹjade kan eleyi ti wọn ni o fi ọgbọn kọlu aarẹ ati amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu to kede laipẹ yii nipa igbesẹ ti aarẹ Buhari n gbe lori ọna ati ṣe atunṣe awọn igbo ọba gbogbo.
Ẹgbẹ naa woye pe irufẹ awọn ọrọ to n ti ọdọ gomina ipinlẹ Ondo jade fihan pe ootọ ọrọ ni pe eekan ọmọ Yoruba nni to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Igboho sọ nigba to wipe gomina Akeredolu wa lara awọn to n ti ipe fun iyapa Yoruba kuro labẹ Naijiria lẹyin sọ.
Ẹgbẹ BMO naa ni awọn lee sọ yanya pe aarẹ lo fọwọsi atẹjade ti Garba Shehu fi sita lori igbesẹ ijọba apapọ lati ṣe agbedide awọn igbo ọba fun sinsin awọn maluu ati pe bi inu gomina Akeredolu ko ba dun si eyi ko bọ si gbangba wa sọ.
Ẹgbẹ to n fonrere Buhari naa, (BMO) wa fi da awọn ọmọ Naijiria loju peigbesẹ aarẹ lati ṣe agbedide awọn igbo ọba naa ko si fun jija ilẹ gba lọwọ ẹnikẹni tabi fifa awọn ilẹ le awọn agbebọn to n fi iṣẹ darandaran boju gẹgẹbi atẹjade ti gomina Akeredolu fọwọsi ṣe sọ.
Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ lo sọ Garba Shehu, Ààrẹ Buhari kọ́ ló rán ẹ níṣẹ́ lórí àwọn Fulani darandaran- Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Garba Shehu
Gomina ipinle Ondo, Rotimi Akeredolu ti bu ẹnu atẹ lu oluranlọwọ Pataki fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Garba Shehu lori ọrọ to sọ nipa adehun awọn gomina mẹtadinlogun ni Guusu Naijiria pe ko gbọdọ si dida ẹran kaakiri igboro ni Naijiria.
Garba Shehu ninu atẹjade to fi lede wi pe lati ọdọ aarẹ Buhari sọ wi pe ko si ọrọ ninu adehun awọn gomina naa, to si ni pe wọn ko fi ọna abayọ jade si isoro naa.
Amọ gomina Akeredolu ninu atẹjade gba owo oluranlọwọ pataki fun lori awọn iṣẹ pataki, Doyin Odebowale fi lede pẹlu akọle '' 'Mr Garba Shehu: On the trail of an agent provocateur'
- Tinubu, Bisi Akande, ìtàn kò ní sọ rere nípa yín- Ẹgbẹ́ Ilana Oodua yarí
- Ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ń fa aáwọ̀ láàrin Gani Adams àti Sunday Igboho
- Wo bí àwọn olùwọ́de ṣe dí òpópónà Abuja sí kaduna gbágbá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé
- A fọwọ́ sí ìṣọ̀kan Nàíjíríà gẹ́gẹ́ bi ọmọ ẹgbẹ́ APC - Akeredolu, Fayemi
- Ìdí tí àwọn aṣòfin ṣe fẹ fagilé NYSC, ohun táa mọ rèé
- Àwọn Ọ̀gágun tó ṣeéṣe kó gba ipò olórí àwọn ọmọogun lẹ́yìn ikú Attahiru nìyìí
- Ọdún 32 ni mo fi ṣiṣẹ́ oko mọ́ ìṣẹ́ tíṣà kí àwọn ọmọ mi le jẹ́ èèyàn, àmọ́ ikú mú Taiwo lọ - Baba Taiwo Asaniyi
Akeredolu ni ẹnikẹni to ba ti n feti si ọrọ ti Garba Shehu n sọ yoo mọ wi pe oun da nkan ṣe ni adabọwọ ara rẹ ni lai gba aṣẹ ni ọwọ aarẹ Muhammadu Buhari, eleyii to fihan wi pe oun lọgun ituka lorilẹede Naijiria.
''O fihan pe o ni awọn miran to n ṣiṣẹ fun yatọ si ilọsiwaju ijọba, eleyii to si fẹ mu ki awọn kan lagbara lori ijọba orilẹede Naijiria''
''Garba gbọdọ sọ awọn to n ṣiṣẹ fun nitori kii ṣe aarẹ Buhari , bi bẹẹ kọ ko salaye idi ti ọrọ Minisita fun eto agbẹ, Alhaji Sabo Nanono, ti wọn yan si ipo, yoo ṣe lagbara ju adehun awọn gomina mẹtadinlogun, ti awọn araalu dibo yan.''
''Garba Shehu ninu ọrọ rẹ ni adehun awọn gomina mẹtadinlogun yii ko ṣe e duro le lori, amọ igbesẹ awọn Fulani darandaran to jẹ ibatan, to paṣẹ wi pe ki wọn kọ ile igbe fun awọn darandaran, ki wọn fun wọn ni omi ati ipese ileewe to fi mọ ileewosan fun wọn lo ṣe e tẹle''.
''Garba fihan pe awọn gomina ko lagbara mọ lori awọn araalu to yan wọn si ipo tabi lori ilẹ wọn, ni ijọba apapọ yoo ṣe ma a gbe igbesẹ tako wọn ni ibi ti wọn jọba le lori.''
Bakan naa ni Gomina Akeredolu wa kilọ gidigidi fun Garba Shehu ati awọn ẹmẹwa rẹ, wi pe ki wọn so ewe agbejẹ mọ ọwọ lori ọrọ awọn Fulani darandaran ni ilẹ Yoruba.
Akeredolu ni nitori pe ijinigbe ati ipaniyan ni ọrekoore gbọdọ dopin at I wi pe awọn ni aṣẹ gẹgẹ bi Gomina ni ipinlẹ awọn lati ripe eto aabo to munadoko wa fun awọn araalu lorilẹede Naijiria.
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu fikun pe ko si ilẹ kan ninu ilẹ awọn eniyan ni ilẹ Yoruba ti wọn yoo fun awọn Fulani darandaran labẹ akoso bo tilẹ wu ko ri.














