Toyin Abraham Vs Lizzy Anjorin: ESABOD dá sí ìjà àwọn méjèéjì, wàhálà míì tún bẹ̀rẹ̀, Iyabo Ojo di Ońlàjà

Ọpọ eeyan lo n ro pe aawọ to wa laarin gbajumọ osere tiata meji, Lizzy Anjorin ati Toyin Abraham ti jẹ rodo, lọ ree mumi ni.
Amọ eyi ko ri bẹẹ rara nitori bi aawọ naa se n pẹ nilẹ si, lo tun n gbọn si, ti awọn oju opo ibanidọrẹ lori ayelujara si n gbona janian janni to ri ija awọn osere meji naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ija Toyin ati Lizzy lo fẹ ni bii ọdun meji sẹyin, nigba ti Toyin bimọ, ti Lizzy si ni isọ alagbo lo bimọ si.
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Ọkọ Toyin Abraham pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ lórí aáwọ̀ láàrin ìyàwó rẹ̀ àti Lizzy Anjorin
- Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Ṣé o mọ̀ pé o leè rí omira abẹ́ obìnrin rà tàbi fi tìrẹ silẹ̀ fún títà?
Ọrọ yii dogun dọdẹ nigba naa, bi awọn eeyan awujọ atawọn gbajumọ kan si se pọn sẹyin Toyin to sẹsẹ bimọ, ni awọn miran pọn sẹyin Lizzy.
Koda, akoko kan tiẹ wa ti agbẹjọro Lizzy kọwe si Toyin Abraham pe ti ko ba sọra, ohun yoo gbe lọ sile ẹjọ.
Ija miran bẹ silẹ bi Lizzy anjorin se bimọ tan
Ni osu kẹrin ọdun 2021, eyiun bii osu kan sẹyin ni ariwo ayọ jade pe Lizzy Anjorin bimọ tuntun tawọneeyan si n ki ku oriire.
Ko pe ọsẹ meji lẹyin eyi ni obinrin kan, Fola Tinubu kede sita pe iya n jẹ oun atawọn ọmọ oun nitori pe Lizzy gba ọkọ oun, ti ko si jẹ ko tọju oun.
Aanu obinrin naa, to gbe fọnran ohun sita nipa itakurọ oun ati ọkọ rẹ, ti wọn si n koro oju si Lizzy pe ko se daadaa.
Koda, awọn kan ni di ẹbi ru Toyin pe oun lo wa nidi igbesẹ ti obinrin naa gbe yiui, lati ba Lizzy lorukọ jẹ.
Ọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo n sẹ epe fun Lizzy, ti wọn si n darukọ Toyin Abraham pe eeyan gidi ni, amọ aburu wa lọwọ Lizzy.
Eebu yii pọ fun Lizzy toun naa fi se fidio sita lati se alaye ohun to waye laarin oun ati obinrin naa pẹlu ọkọ rẹ.
Sugbọn kaka ki wọn dẹyin lẹyin Lizzy, eebu tun n pọ fun ni.

ESABOD da si ija Lizzy ati Toyin, ọrọ di isu ata yanyan
Bi ọpọ eeyan se n fi ẹnu tabuku Lizzy to sẹsẹ bimọ yii, ti wọn si n to sẹyin Toyin, bọ si apo ibinu gbajumọ sọrọsọrọ kan lori ayelujara, Esther Tokunbo Aboderin, ti ọpọ mọ si ESABOD.
Ni irọlẹ oni ọjọ Isẹgun ni ESABOD se fidio kan, to si n sọ kobakungbe ọrọ si Toyin Abraham, ọkọ ati awọn ololufẹ rẹ lori bi wọn se yan Lizzy sọju.
ESABOD sọ ọpọ ọrọ lati gbe sẹyin Lizzy, to si n sọ kobakungbe ọrọ si Toyin, idile rẹ atawọn eeyan to n ti lẹyin.
Koda, o sọrọ debi pe ole, asẹwo ati ẹni ti ko ri owo kọle ni Toyin, ati pe, ko ri ohun kankan sọ lasiko ti ohun beere ohun to fa ija rẹ ati Lizzy ni bii ọdun meji sẹyin.
Koda, ESABOD ni ẹni to n mu oogun oloro ni Toyin, ti ko si gbe nnkan rere se.
Toyin Abraham fesi pada fun ESABOD, ija sọ
Ninu fidio naa, ta n wo loju opo Instagram ESABOD, bo ti n se lọwọ, ni Toyin Abraham pe si, to si bu sẹkun.
Toyin wa fun ESABOD ni gbedeke ọjọ mẹta pe awọn ogun ọrun to n gbe inu oun yoo kan si tori epe to sẹ fun ọmọ ati ọkọ oun.
Toyin ni oun ko mọ idi ọrọ atawọn ẹsun ti ESABOD ati Lizzy fi kan oun nitori oun ko bẹ ẹnikẹni nisẹ lati maa bu Lizzy.
Gbedeke ọjọ mẹta ati ileri ti Toyin se yii bọ sapo ibinu ESABOD, to si ni lẹyin ọjọ mẹta, ti nnkan kan ko ba sẹlẹ, gẹgẹ bi Toyin ti leri, oju rẹ yoo si mabo.

Iyabo Ojo ba Toyin bẹ ESABOD
Asiko yii naa ni osere tiata miran, iyabo Ojo foju han ninu fidio naa, to si n bẹ ESABOD pe ọr naa ko ri bẹẹ.
Iyabo wa jẹri Toyin Abraham pe kii se ọmọ buruku rara,m ti oun si ti tẹ ninu ni kọrọ nipa ija oun Lizzy, ti Toyin si ni oun ko mọ ohunkohun nipa rẹ.
Lẹyin ti fidio ESABOD pari tan ni Toyin Abraham naa bẹrẹ fidio tiẹ pẹlu Iyabo Ojo, to si n da omije loju.
Toyin ni gẹgẹ bii abiyamọ, oun ko le laju silẹ, maa wo ESABOD niran, ko maa fi ọmọ ati ọkọ oun sepe ni oun se leri pe gbogbo epe to sẹ yoo sẹlẹ si obinrin naa laarin ọjọ mẹta.
Ki lo fa aawọ Toyin ati Lizzy?
Nigba ti aawọ naa kọkọ̀ bẹrẹ, ko si ẹni to le sọ pato ohun to faa, amọ a sa ri pe se ni ri ayelujara n gbona laarin awọn ololufẹ awọn osere tiata mejeeji naa.
Awọn ololufẹ Lizzy ni Toyin atawọn ololufẹ́ rẹ ti wọn pe ni Toyin Titans n lo ayederu orukọ lati maa ba Lizzy lorukọ jẹ.
Koda, wọn tun ni Toyin kọ iwe si ilẹ okeere kan ti Lizzy ti lọ ra ọja pe ki wọn yẹ ẹru rẹ wo daadaa, tori o le oogun oloro sinu rẹ.
Bakan naa ni awọn ololufẹ Toyin ni inu Lizzy ko dun si ọmọ ti Toyin bi, lo se n fooro ẹmi rẹ ni kete to bimọ tan.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn agbaagba awujọ kan ati ninu agbo tiata dide nigba naa lati jẹ́\ki ọrọ naa pari, ta si ro pe o ti ri bẹẹ.
Amọ awọn isẹlẹ akọtun yii lo tun mu ko maa foju han pe ija ọhun sẹsẹ bẹrẹ ni.




















