Lizzy Anjorin: Èmi ń ṣiṣẹ́, obìnrin yìí ń gba owó láti fi ṣe àríyá

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin/Instagram
Iroyin nipa osere tiata ati onisowo nni, Lizzy Anjorin ati ọkọ rẹ lo tun n rugbo ni ori ayelujara lọwọ lọwọ bayii.
Eyi ko si sẹyin bi obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Fola Tinubu se n pariwo Lizzy ati ọkọ rẹ, Alhaji Lawal lori ayelujara.
Fola lo kede fawọn akọroyin lori ayelujara pe iya n jẹ oun, ti oun ko si nile lori nitori bi Lizzy Anjorin se gba ọkọ oun, to si bimọ fun.
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
- Ọlọ́run Ọba ti pa ẹ̀gàn mi rẹ́, a bímọ l'Amẹrika - Lizzy Anjorin
- Mo gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́ oyún ọmọ mi tuntun, ọkọ mi nàá sì faramọ́ nítorí pé...
- Ọkọ mi kò fẹ́ràn oúnjẹ òyìnbó àfi ti ìbílẹ̀ - Lizzy Anjorin
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Lizzy Anjorin ń kiri àgọ́ ọlọ́pàá láti gba ọ̀dọ́ afẹ̀hónúhàn, tó wà láhàámọ́ sílẹ̀
Bakan naa lo fun wọn ni ohun to gba silẹ nipa itakurọsọ lori foonu laarin ohun ati Alhaji Lawal yii, nibi to ti n beere pe ki onitọun fi owo ransẹ si oun.
Eyi lo mu ki Lizzy wa se fidio kan soju opo Instagram rẹ, to fi n fun obinrin naa lesi pe oun ko ni orogun rara, nitori oun nikan ni iyawo ti ọkọ oun fẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/ Lizzy Anjorin
Nigba to n sọrọ lori bi obinrin ọlọmọ mẹta naa se ni iya n jẹ oun, Lizzy wa se afihan bi obinrin naa se gba owo to le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira laarin osu Januari nikan.
"Fola, o kan bimọ fun ọkọ mi ni, o kii se iyawo rẹ rara nitori ko ba ọ se igbeyawo tabi so yigi fun ọ.
Laarin osu kinni ọdun si akoko yii, owo to ti gba lọwọ ọkọ mi to miliọnu kan naira, to si tun lọ ba baba onile rẹ pe ko parọ pe o ko tii sanwo ile.
Ti mo ba jẹ eeyan buruku ni, n ko ni jẹ ki ọkọ mi fun ọ ni owo tabi Jeep Exterra ti mo ni ki ọkọ mi gbe fun ọ, bẹẹ ni emi ni mo jẹ ki ọkọ mi gba oyun nigba to loyun."
Bakan naa tun ni Lizzy se afihan agbasilẹ fọnran ohun itakurọsọ laarin ọkọ rẹ, Lawal ati Baba Onile naa, ti onitsun si n salaye pe obinrin naa lo ni ki oun parọ pe ko tii sanwo ile.
Bakan naa ni Lizzy tako obinrin naa peirọ nla ni aworan to n gbe kiri pe oun se igbeyawo pẹlu ọkọ oun, nitori aworan naa ni wọn ya nigba ti wọn n fi obinrin naa joye.
Lizzy wa n sọ fun obinrin naa pe to ba jẹ pe bi oun se ranti rẹ, naa lo jẹ ki Lawal ranti awọn eeyan to saaju tiẹ naa ni, ko ba ri wọn pe loni.
O fikun pe kii kuku se pe Fola yii nilo owo amọ o mọọmọ se fọnran ohun naa sita lati wọ oun nilẹ ni, ti Ọlọrun yoo si gbe oun leke gbogbo wọn.
Wa lọjọbọ lati wa se ayẹwo boya ọkọ mi lo ni ọmọ mẹtẹẹta to bi
Wayi o, Lizzy Anjorin ti sọ fun obinrin ti wọn dijọ n fa surutu naa pe fọọmu fun ayẹwo DNA ti wa nilẹ fun, to si se afihan awọn fọọmu naa.
"Ọmọ mẹta lo sọ fun araye pe o bi fun wa, agbẹjọro yoo pe ọ ni ọjọbọ ọla, to ba lọ se DNA naa, ko to kuro nibẹ, maa fi owo ransẹ si ọ, ko lọ se tara rẹ naa, ko ma baa da bii magomago.
To ba jẹ Lawal lo ni ọmọ mẹtẹẹta, a yanju rẹ amọ to ba jẹ ẹyọ kan tabi meji ni ti Lawal nibẹ, a maa ja."
"Ọkọ mi kii se Jigolo tabi joko ti owo mi
Nigba to n fesi lori bi awọn eeyan se n yọ suti ete si ọkọ rẹ pe owo osere tiata naa lo n na lai ni isẹ kan pato lọwọ, lizzy salaye pe okoowo jọ pa oun ati ọkọ oun pọ ni.
"Lawal kii se Jigolo, ibudo to ti n ta mọto mẹta lo ni laarin Lekki si Ajah, to si tun ni ileesẹ ti wọn ti n fọ ọkọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Níbo ni Baba Ijesha wà lẹ́yìn wákàtí 48 tí wọ́n gba béèlì rẹ̀?
- Ọmọ Yahoo gba ọkọ̀ 25 padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣọ́ EFCC lásìkò tí wọn dènà dè wọ́n l‘Osogbo
- Ẹ fún wa láàyè díẹ̀ si, kẹ tó fòfin de ẹ̀ran dídà nígboro - Fulani darandaran rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ sí Gómìnà Ogun ségi lórí ẹsùn jìbìtì $350,000
- Àwọn ọmọ Yahoo dènà de ẹ̀ṣọ́ EFCC tó fòru wọ̀lú l'Osogbo, nǹkan yan
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí James Ibori gbé- Malami
- Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram
Lawal n sisẹ takuntakun ni Owode onirin, to si maa n ba wọn ja irin, o maa n sisẹ kara, kii se eeyan buruku, ko si kundun obinrin.
Obinrin mẹrin lo wa nile bii ọmọ ọdọ mi, ko le dẹnu kọ ikankan wọn amọ oju aanu lo fẹ pa Lawal, yoo si dara ki Fola sọ iru eeyan ti lawal jẹ."
Lizzy wa n gba Fola nimọran pe ko ye na owo lori ayẹyẹ to maa n lọ, nitori ibẹ gan lo n na owo le lori.
Lizzy wa n kesi gbogbo awọn eeyan to n sepe fun lori ayelujara pe ayafi ti wọn ba le se ohun ti oun se fun obinrin naa ni erongba wọ̀n ko ni pada da le wọn lori.
Ọmọ Fola wa ninu iwe akọsilẹ ogun ti mo se
Lizzy Anjorin wa sisọ loju rẹ pe oun ti fi silẹ ninu akọsilẹ ogun oun pe gbogbo ọmọ ti ọkọ oun ba bi ati ti tiẹ naa, ni wọn maa pin ninu ogun oun.
O ni orukọ awọn ọmọ Fola wa ninu iwe akọsilẹ ogun naa, ati pe ni aduru gbogbo ọmọ ti oun kọ orukọ wọn silẹ lati pin ogun oun, ẹyọ kan soso pere ni ti oun.
O ni eyi fihan pe anfaani ti oun ba ni lati lọ silẹ okeere, ni awọn ọmọ obinrin naa ni pẹlu.
"Emi n sisẹ, amọ Fola n gba owo lati maa lọ si pati.






















