Oluwo Farmers-Herders Summit: Àwọn darandaran ní aráàlú le è jí màálù àwọn torí òfin ìjọba

Aṣoju awọn Fulani darandaran ẹka ti ipinlẹ Ọṣun, ti ra ọwọ ẹbẹ si ijọba apapọ ati awọn alẹnulọrọ lati fun wọn ni anfani diẹ si i, ki ofin to de ẹran dida kaakiri.
Seriki Fulani ni ilu Iwo n'ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Mohamadu Oloruntele lo fi ipe naa sita l'ọjọ Iṣẹgun, nibi akanṣe eto apero to waye lori ija awọn darandaran ati awọn agbẹ.
Aafin Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni ni ipade apero naa si ti waye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baba Ijesha yóò jẹ́jọ́ ìwà tó hù, ohun tó bá gbà, ni màá fun - Iyabo Ojo
- Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ sí Gómìnà Ogun ségi lórí ẹsùn jìbìtì $350,000
- Àwọn ọmọ Yahoo dènà de ẹ̀ṣọ́ EFCC tó fòru wọ̀lú l'Osogbo, nǹkan yan
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí James Ibori gbé- Malami
- Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram
Ninu ọrọ to sọ nibi ipejọpọ naa, Oloruntele ṣalaye pe oye ofin tuntun ti ijọba gbe kalẹ lori kikọ ọgba fun awọn maalu dipo kiko ẹran jẹ kaakiri, ko ti i fi bẹẹ ye awọn darandaran.
Nitori idi eyii lo fi kesi ijọba lati fun wọn ni asiko diẹ si i, ki wọn le gbaradi fun ilana tuntun naa.

Seriki Fulani fikun pe, yoo di irọrun fun awọn darandaran lati tẹle aṣẹ ijọba, lẹyin ti wọn ba ni oye ati idanilẹkọ to peye lori i bi wọn ṣe le tọju awọn nnkan ọsin wọn, lai ko wọn jẹ kaakiri.
O ni ṣugbọn saaju eleyii, awọn darandaran rọ ijọba lati fun wọn ni anfani diẹ si i ki wọn to gbẹsẹ le dida ẹran kaakiri.
Oloruntele tẹsiwaju wi pe, ewu to pọ lo rọ mọ ofin tuntun ti ijọba gbe kalẹ lori i dida ẹran kaakiri.
O ni awọn ara ilu ti ijọba ko bẹ lọwẹ yoo bẹrẹ si ji maalu ti wọn ba ri nigboro gbe, nipasẹ aṣẹ ti ijọba pa lori i dida ẹran kaakiri.
O ni awọn darandaran yoo dẹkun ati maa da ẹran kaakiri lai pẹ, ṣugbọn ki ijọba ṣe suuru fun wọn diẹ ki wọn fi ọna mi i ti awọn nnkan ọsin wọn yoo maa gba jẹun.
Ijọba Osun ni maalu ti wọn bọ ninu ọgba maa n ni alaafia
Ẹni ti o jẹ alaga nibi ipade apero naa, to tun jẹ Kọmisana fun eto ọgbin nipinlẹ Ọṣun, Arakunrin Adewole Adedayo ṣalaye pe ko si nnkan to buru ninu ofin tuntun ti ijọba gbekalẹ.
Adedayo ni ofin naa yoo ṣe anfani to pọ fun ọlọsin ẹran, ti awọn maalu to ri itọju to peye ninu ọgba ti wọn kọ fun wọn ni ibamu pẹlu aṣẹ ijọba,yoo si ni alafia.
O tun salaye pe irufẹ awọn maalu inu ọgba bayii maa n sanra ju awọn maalu ti wọn n rin kaakiri inu igbo ati igboro lati wa ounjẹ lọ.
Nipa bẹẹ, o ni awọn ọlọsin maalu ti ni anfani lati bọ awọn nnkan ọsin wọn yo, bẹẹ si ni wọn yoo maa taa ni owo gọboi.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe, ijọba yoo ṣe iranlọwọ nipa idanilẹkọ fun awọn darandaran lori agbekalẹ ofin tuntun naa.
Oluwo setan lati seranwọ fun darandaran lori ọgba maalu
Ninu ọrọ tiẹ, olugbalejo agba nibi ipejọpọ naa, Oluwo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ṣalaye pe awọn agbẹ ati darandaran gbọdọ wa ni iṣọkan ki alafia le jọba.
O ni ọna ti alafia le fi jọba si ni ki awọn darandaran gbọran si aṣẹ ijọba lori i ofin to de dida ẹran kaakiri igboro.
Ọba alade naa wa ṣe ileri lati ṣe iranlọwọ fun awọn darandaran to o ba nilo iranlọwọ lori agbekalẹ awọn ọgba ti maalu yoo ti maa jẹ koriko, dipo kiko wọn jẹ kaakiri ilu.
Awọn Lọbalọba, Baalẹ, ẹgbẹ awọn darandaran, awọn agbẹ, agbofinro ati awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Ọṣun wa lara awọn to ba wọn pejupesẹ sibi apero naa.

Oluwo pe ìpàdé àpérò láti parí aáwọ̀ àgbẹ̀ àti darandaran

Saaju la ti sọ fun yin pe ipade apero laarin awọn agbẹ ati Fulani ti bẹrẹ nilu Iwo.
Pẹlu bii olukuluku igun lorilẹede Naijiria ṣe n wa ọna abayọ si gulegule wahala awọn agbẹ olohun ọgbin atawọn Fulani darandaran lo bi ipade apero naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iyabo Ojo fèsì lórí béèlì tí wọ́n fún Baba Ijesha
- Àwọn ọmọ Yahoo dènà de ẹ̀ṣọ́ EFCC tó fòru wọ̀lú l'Osogbo, nǹkan yan
- Princess pàrokò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lẹ́yìn tí Baba Ijesha gba béélì
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Ẹ̀yin ọdọ́, ẹ sọ́ra fún ìtànjẹ láti darapọ̀ mọ́ ìyapa Naijiria - YAF
- Sunday Igboho, jọ̀ọ́ má gbé ìwọ́de Yoruba Nation wọ Iseyin - Aseyin ṣèkìlọ̀
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- "Sunday Igboho kò fí lààkáyé kún ìjìjàgbara rẹ̀ nípa àtakò sí ìbò 2023"
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
Oluwo tilu Iwo Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi si lo gbe igbesẹ gẹgẹ bi ọba alaye, lati mu alaafia wa laarin awọn agbẹ ati darandaran.

Ọba Akanbi ni igbesẹ naa yoo faye silẹ lati gbọ ẹhonu awọn igun gbogbo tọrọ aawọ laarin agbẹ olohun ọgbin ati darandaran kan, paapaajulọ nipinlẹ Ọṣun.

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, awọn eekan gbogbo tọrọ abo ati idagbasoke kan nipinlẹ Osun ni wọn ti peju sibi ipade naa.

Ikọ iroyin BBC Yoruba si ti gunlẹ silu Iwo lati maa mu bi nnkan se n lọ nibẹ wa fun yin nibi ipade apero naa, ẹ maa fi oju sọna lati gbọ ẹkunrẹrẹ iroyin.



















