Yoruba Nation: YAF ní gbàjarè Banji Akitoye lé ṣàkóbá fún Yorùbá tó bá jẹ́ irọ́

Oríṣun àwòrán, Yoruba Appraisal Forum
Awọn ọmọ ẹgbẹ Yoruba Appraisal Forum, YAP, ti ke si awọn agbofinro, lati ṣe ọfintoto ọrọ ti aṣaaju ẹgbẹ Ilana ọmọ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ.
Alagba Akitoye ni wọn lo sọ pe awọn agbesumọmi ti n mura lati kọlu Guusu iwọ-oorun Naijiria.
Adari ẹgbẹ YAF naa, Adeshina Animashaun lo sọ ọrọ naa lẹyin ipade kan ti wọn ṣe niluu Eko.
- Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Ẹ má lọgun ‘Oduduwa Nation’ mọ́, Yorùbá ló kàn láti jẹ ààrẹ - Oluwo
- Ta ni Ọjọgbọn Adebanji Akintoye tó borí Tinubu láti di olórí àwọn Yoruba?
- Ẹ lo Amotekun, OPC, Fijilanté àti ọ̀dẹ ìbílẹ̀ fétò ààbò - Ọba Tejuosho
- Obìnrin bíi 1000 láti orílẹ̀èdè 37 bẹ Ọọ̀ni wò fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa
- Ẹgbẹ́ tó ń fẹ́ Oduduwa Republic kọ̀wé ẹ̀hónú sí UN, EU, AU àti ìjọba Gẹ̀ẹ́sì
Animasahun ni iwe ti Akintoye kọ nipa ikọlu awọn ẹgbẹ agbesumọmi nilẹ Yoruba le da wahala silẹ, ti ko ba si ootọ kanka ninu ọrọ ọhun.
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe baba Akintoye kọ lẹta si awọn gomina ilẹ Yoruba lori ikọlu naa to ṣeeṣe ko waye.
Ninu lẹta ọhun ni Akintoye ti sọ pe awọn ẹgbẹ agbesumọmi ti n mura lati kọlu gbogbo ilẹ Yoruba, lọna ati ṣakoba fun eto ọrọ aje agbegbe naa.
Animashaun sọ fun awọn kọroyin pe "O yẹ ka wo lẹta Akintoye daadaa nitori atilẹyin rẹ fun iyapa Yoruba kuro lara Naijiria."
"O ṣeeṣe ki Akintoye mọ ọpọ ohun ti awa araalu to ku ko mọ."
O tẹsiwaju pe "O yẹ ki awọn agbofinro fi ọrọ wa Akintoye lẹnu wo nitori irufẹ ọrọ to sọ pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ to n pe fun iyapa Naijiria."
Animashaun ni ki awọn ọdọ sọra fun awọn eeyan to n pe fun iyapa Naijiria, ki wọn ma baa maa ja ija ti ko tọ eyii to le mu ki wọn ṣẹ si ofin.
O ni "Awọn ọdọ ni lati ṣọra gidi fun awọn ti yoo maa pe wọn lati darapọ mọ ẹgbẹ agbesumọmi labẹ asia pe wọn n jija ominira."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iyabo Ojo fèsì lórí béèlì tí wọ́n fún Baba Ijesha
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Sunday Igboho, jọ̀ọ́ má gbé ìwọ́de Yoruba Nation wọ Iseyin - Aseyin ṣèkìlọ̀
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- "Sunday Igboho kò fí lààkáyé kún ìjìjàgbara rẹ̀ nípa àtakò sí ìbò 2023"
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
Adari YAF naa wa rọ ijọba apapọ atawọn gomina ni iha Guusu iwọ-oorun Naijiria lati pese eto abo to peye ni gbogbo ipinlẹ mẹfa to wa lagbegbe ọhun.
O ni eyi lọna ati kapa awọn janduku to n gbero lati da omi alaafia agbegbe naa ru.
Lẹyin naa lo rọ awọn ọdọ ilẹ Yoruba lati gbogun ti iwa iṣẹrubalu ati gbogbo ipe fun ijijagbara ti awọn kan n lọgun rẹ.
O ni alaafia Naijiria ni ẹgbẹ YAF n fẹ nitori ninu alaafia nikan ni orilẹ-ede ti le ni ilọsiwaju.

Shehu Sani fi olùwọ́de Yoruba Nation ṣe ẹlẹ́yà torí òjò tó tú wọn ká

Asofin agba to n soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Kaduna nile asofin agba kẹjọ to kọja, Sẹnatọ Shehu Sani ti bẹrẹ si fi ọrọ idasilẹ orilẹede Yoruba Nation dapara.
Bẹẹ ba gbagbe, awọn ajijagbara to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba lati ara orilẹede Naijiria ni wọn se iwọde nilu Osogbo lọjọ Satide.
Nibi iwọde naa to waye ni gbagede Nelson Mandela Freedom Square ni ogunlọgọ awọn ajijagbara naa peju si, to fi mọ asaaju wọn, Sunday Igboho.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn olùwọ̀de Yoruba Nation mú afurasí òṣìṣẹ́ DSS níbi ìwọ́de l‘Osogbo
- A ti ṣe iṣẹ́ ribiribi lórí ètò ààbò láti ìgbà tí a ti gorií àléfà- Ààrẹ Buhari
- Àwọn Aláṣẹ ilẹ̀ Palestine ní eèyàn 139 ló ti kú ní Palestine nínú ìja Isreal àti Palestine
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọmọ oṣù kan he lẹ́ba ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko
- Èèyàn márùn ún kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ẹ̀ni ọdún 42 kan l'Ẹ́dẹ
- Kò sẹ́ni tó lè ní kí n má yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi
- Ẹ̀yìn tí ẹ̀ ń pè fún Yoruba Nation, òpè ní yín, ẹ kò ní ìmọ̀- Ladoja
Lasiko iwọde ọhun si ni ojo nla kan bẹ silẹ, to si bẹrẹ si ni rọ le awọn oluwọde ọhun lori, eyi ti ko see da duro, ojo yii si lo tu iwọde naa ka.
Idi si ree ti asofin agba naa, Shehu Sani se bọ soju opo Twitter rẹ, to si n fi awọn ajijagbara ọhun se ẹlẹya pe ojo to rọ naa, kii se lasan.
Sani ni ojo naa lo n paroko fun awọn ajijagbara ọhun pe ki wọn tun ero wọn pa lori igbesẹ ti wọn n gbe lati pin Naijiria si yẹlẹyẹlẹ.
"Ojo alagbara to rọ lọjọ Satide, eyi to tu awọn oluwọde to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ka, jẹ isẹ lati ọdọ Ọlọrun fun wọn.
Isẹ yii lo n paroko pe ki wọn tun ero wọn pa lori igbesẹ ti wọn n gbe, ki wọn si maa sisẹ fun isọkan orilẹede yii.
Erongba lati se agbekalẹ orilẹede fun ẹya tabi ẹsin kan lo jade latinu ọkan ẹlẹyamẹya ti ko ni ifarada fun ibagbepọ alaafia."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post






















