Osun state: Èèyàn márùn ún kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ẹ̀ni ọdún 42 kan l'Ẹ́dẹ

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, other

Ọwọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn afurasi ọdaran marun un kanlori iku ẹni ọdun mejilelogoji kan ti orukọ rẹ n jẹ Wakili Ọlayiwọla ni agbegbe Arulogun ni ilu Ẹdẹ l'Ọjọbọ.

Gẹgẹ bi awn eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, awọn janduku kan ti wọn to ọgbọn ni iye kslu ile oloogbe naa ti wọn si rọ ojo ibọn lee.

Ileeṣẹ ọlọpaa, ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Yẹmisi Ọpalọla fi sita awọn eeyan meji kagbako iku ojiji lọwọ awọn janduku naa ti wọn si ti gbe oku wọn si ile igbokupamọsi.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

Bakan naa ni wọn ni wọn ka awọn ohun ija oloro bi ibọn oloju kan, ibọn ṣakabula kan, ọta ibọn mẹjọ, aake, ada, ogun abẹnugọngọ ati alupupu marun.

Awọn iroyin abẹle tun fi kun un pe awọn afurasi ọdaran naa tun da ina sun ọkọ ayọkẹlẹ Toyota corola to jẹ ti ọkunrin naa.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama