Iniubong Umoren: Àwọn ọlọ́pàá fojú afurasí to ṣekúpa Iniubong Umoren tó ń wá iṣẹ́ hàn

Frank Akpan ati Iniubong Umoren

Ọjọ ti a ba ku laa dere, eniyan o sunwọn laaye.

Lẹyin ti wọn sin oku Iniubong Umoren ti wọn ṣekupa nibi to ti wa iṣẹ lọ nipinlẹ Akwa Ibom tan, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa tiu ṣafihan afurasi to sẹkupa a, Akpan 'Frank' Uduak.

Ọga agba ọlọpaa nipinlẹ Akwa Ibom, Andrew Amiengheme ṣalaye pe awọn ọlọpaa fi oju Akpan han nitori ahesọ ọrọ to n lọ kaakiri lori ayelujara pe o ti ku si ahamọ awọn ọlọpaa.

''Awọn tiẹ sọ pe o ti gbẹmi ara rẹ ni ahamọ ọlọpaa, awọn ni ṣokoto to wọ lo fi pa ara rẹ.

Mi o mọ ibi ti afurasi to wa ni ahamọ yoo ti fi ṣokoto to wọ gbẹmi ara rẹ.

Ọpọlọpọ eeyan lo ti pe mi lori ago lati beere bo ya awọn ọlọpaa fẹ tọ oju ẹjọ naa mọlẹ ni.

Idi niyii ti a fi pe apero awọn akọroyin ki onikaluku le fi oju ara wọn ri i pe o si wa ni atimọle ọlọpaa,'' ọga ọlọpaa ṣalaye.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ni o ṣeni laanu pe ayelujara to yẹ kawọn eeyan maa lo lati ran awọn ọlọpaa lọwọ ni wọn fi tabuku ọlọpaa.

O ni ẹjọ ti wọn kọkọ mu wa ni ẹjọ ijinigbe eleyii tawọn ọlọpaa ṣi bẹrẹ iṣẹ lori rẹ ni kiakia.

Ọga ọlọpaa Amiengheme tun ṣalaye pe DPO agọ ọlọpaa Uruan tawọn kan sọ pe o lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ko mọ ohun kan nipa rẹ.

O ni DPO naa kan darapọ mọ ẹbi Frank lati ri pe o pada wale lati ilu Oron to sa lọ ni.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa niwọn igba ti ọrọ naa ko tii de ileẹjọ.