ICPC ń wá ọkọ ọmọ Buhari àtàwọn méjì míì lórí ṣíṣe $65,000,000 kúmọ kùmọ

Oríṣun àwòrán, ICPC/Screenshot
Ajọ ICPC to n gbogun ti iwa ajẹbanu atawọn iwa ọdran mii ti kede pe awọn n wa ọkọ ọmọ Aarẹ Muhammadu Buhari, Gimba Yau Kumo,atawọn meji mii lori ẹsun iṣowo ilu kumọ kumọ.
Ẹsun ti ajọ naa fi kan wọn ni pe wọn na miliọnu marunlelọgọta owo dọla baṣu baṣu.
Ọdun 2016 ni Ọgbẹni Yau Kumo ti ICPC n wa yii ṣe igbeyawo pẹlu ọmọbinrin keji Aarẹ Buhari.
- Saudi Arabia, Iran àti Egypt wà lára orile-ede àgbáyé tó ga jùlọ láti fi ikú ṣe ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dún 2020
- Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní Nàìjíríà pàṣẹ ki wọn kó ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá síta fún ìtúnu àwẹ̀
- Òpó iná ẹ̀lẹ́ńtíríkì daṣẹ́rú, ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà wà lókùnkùn
- Wo bí wọ́n ṣe kírun ìtúnu àwẹ̀ Ramadan 2021 ní Makkah àti Medina ní Saudi lónìí
- Àjọ́ CAN pàṣẹ ètò àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́tà fún Naijiria ní May 28 sí 30, ẹ wo kókó àdúrá...
- ''Àwa àgbààgbà òṣèré kò dákẹ́ lórí wàhálà láàrin Iyabọ Ojo ati Yomi Fabiyi nitori Baba Ijẹsha''
ICPC ni ajọ to ri si iwa ajẹbanu tawọn oṣiṣẹ ọba ba hu lẹnu iṣẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ naa fi soju opo alatagba wọn, ICPC ni Tarry Rufus, Bola Ogunsola ati Yau Kumo lawọn n wa bayii.
Ẹsun ti wọn kan wọn niṣe pẹlu iwa ajẹbanu lori owo ileegbe awọn oṣiṣẹ.

Oríṣun àwòrán, ICPC
Eto ti ijọba apapọ gbe kalẹ ni eto ileegbe ti ko ni gara fawọn fawọn oṣiṣẹ.
Ilu Daura to jẹ ile Aarẹ Buhari ni Yau kumo ti ṣe igbeyawo pẹlu Fatima to jẹ ọmọbinrin Buhari.
Yau Kumo ni ọga agba banki ayanilowo kọle ti ijọba apapọ tẹlẹ, banki lo si n ṣamojuto owo tawọn oṣiṣẹ n da fun ileegbe.












