Eid-el-Fitri security: Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní Nàìjíríà pàṣẹ ki wọn kó ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá síta fún ìtúnu àwẹ̀

Alkali Usman Baba

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Police

Ọga agba ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Alkali Usman Baba ti paṣẹ ti paṣẹ pe ki wọn da ọlọpaa sita kaakiri Naijiria lọpọ yanturu lọna ati mu ki okun abo o tubọ gbopọn lasiko itunu awẹ to wa lode.

Ninu ọrọ ti alukoro apapọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba fi sita, ọga agba ọlọpaa ni Naijiria ti kan si gbogbo awọn amugbalẹgbẹ rẹ, awọn kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ pẹlu awọn lọgalọga lẹka ileeṣẹ ọlọpaa lati gbe igbesẹ gbogbo to ba yẹ fun idaabobo bo araalu lasiko ọdun yii.

Ọga ọlọpaa Usman Baba nilootọ ọrọ abo ti dagun lorilẹede Naijiria sibẹ kii ṣe ohun to kọja bibori.

Bakan naa lo tun fọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ pe ileesẹ ọlọpaa labẹ idari oun ko ni ja wọn ni tan mọnnn nipa ririi daju pe ojuutu wa si ọrọ abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

O wa ro awọn ọmọ Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹl'awọn ọlọpaa lọna ati tu aṣiri gbogbo awọn oniṣẹ ibi lawujọ pẹlu ibuba wọn.

Lori ipele kẹrin ilana igbogun ti ajakalẹ arun COVID-19 ni Naijiria, iyẹn Level-4 protocol ti ijọba apapọ ṣẹsẹ kede.

Ọga agba ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria naa rọ awọn ọga ọlọpaa ni ipinlẹ lati ṣiṣẹ tọ ilana tuntun naa lẹyin nipa ririi dajupe awọn eeyan ni ipinlẹ koOwa wọn tẹlẹ ilana ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati dena ajakalẹ

COVID-19 lẹẹkan sii ni Nigeria.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde