Russia school shooting: Ẹni ọdún mọ́kàndínlógún gbẹ̀mí èèyàn mẹ́jọ nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀

Ileẹkọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Ọmọdé méje àti olùkọ́ kan jẹ́ Ọlọrun nípè lẹ́yìn tí agbébọn ẹni ọdún 19 ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ wọn

Ileeṣẹ eto abo ni Russia ti kede oku awọn ọmọ wẹwẹ meje ati ati olukọ kan lẹyin ti ọmọ ọdun mọkandinlogun kan dede ṣina ibọn bolẹ nile ẹkọ wọn ni ilu Kazan.

Iroyin ni ko din ni ogun eeyan miran, ti pupọ ninu wọn jẹ ọmọde to farapa lẹyin ikọlu ọhun.

Iṣẹlẹ naa waye ni iha ila oorun Rusia lagbegbe kan ti wọn n pe ni Tatarstan ti awọn Musulumi pọ si julọ.

Adari ijọba, Mikhail Mishustina juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii to gbomi loju eeyan nigba ti adari iha Tatarstan, Rustam Minnikhanov juwe iṣẹlẹ naa bii ọfọ nla.

ile ẹkọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Aare Rusia, Vladimir Putin sọ pe ijọba oun yoo ṣe agbẹyẹwo ofin to gba awọn eeyan ilu laaye lati ni ibọn ilewọ.

Bo tilẹ jẹ pe irufẹ iṣẹlẹ bayii ṣọwọn ni Rusia, eyii to ṣẹlẹ kẹyin to mi orilẹ-ede naa titi waye lagbegbe Crimea lọdun 2018.

Oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri kan sọ fun awọn akọroyin pe ni nnkan bii aago mẹsan an kọja ogun iṣẹju aarọ kutu ni iṣẹlẹ naa waye.

Awọn alaṣẹ kede orukọ agbebọn naa gẹgẹ bii Ilnaz Galyaviev, ti wọn si sọ pe o ti fi igba kan jẹ akẹkọọ nile ẹkọ naa ri.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Fidio kan to lu sori ayelujara lẹyin iṣẹlẹ naa ṣafihan bi awọn akẹkọọ kan ṣe n fo lati oju ferese lati sa asala fun ẹmi wọn.

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe meji ninu awọn akẹkọọ naa lo jẹ Ọlọrun nipe nitori bi wọn ṣe farapa lẹyin ti wọn fo lati oju ferese.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan