Covid-19 in Nigeria: Ìjọba dá òfin kónlé-ó-gbélé lórí àjàkálẹ̀ àrùn covid-19 padà

Oríṣun àwòrán, Twitter/NCDC
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti da ofin konle-o-gbele pada lori ati dena ajakalẹ arun coronavirus.
Ọkan lara awọn oludari igbimọ PTF to n ri si ati dena ajakalẹ arun naa ni Naijiria, Dokita Mukhtar Mohammed lo fọrọ yii lede lọjọ Aje.
O ṣalaye pe ijọba ti da ofin konle-o-gbele to wa tẹlẹ laarin ago mejila alẹ si ago mẹrin aarọ pada kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria.
- Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀
- Wo orúkọ mẹ́rìnlá tó làmìlaaka tí Lizzy Anjorin sọ ọmọ rẹ̀
- Wo orísun agbára tí Sunday Igboho gbójúlé tí ọwọ́ ẹnikẹ́ni kò fi le tẹ̀ ẹ́
- Àṣìṣe dókità ló pa Peju, ìbànújẹ́ dorí àgbà kodò- Funke Akindele
- Àyànmọ́ ló mú mi pàdé Princess, èrò wa jọra wọn- Iyabo Ojo
- Emmanuel Abina, ọmọ Olùdarí ìjọ GOFAMINT, Elijah Abina jáde láyé lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀
- Amotekun Ondo ju afurasí ajínigbé mẹ́rin s'átìmọ́lé, dóòlà àwọn tí wọ́n jígbé
Bakan naa lo ṣalaye pe lati alẹ ọjọ Iṣẹgun, gbogbo ile ijo, gbọngan idaraya yoo di titi pa.
O tun fikun ọrọ rẹ pe ipejọpọ awọn eeyan ko gbọdọ ju aadọta lọ mọ lati asiko yii lọ
''Ẹnikẹni ti ko ba wọ ibomu ko ni lanfaani lati wọ ileeṣẹ ijọba kankan.
Lori ayelujara ni ipade awọn ileeṣẹ ijọba yoo ti maa waye bayii.
Awọn ti o ṣe pataki fun lati rinrin ajo lọ si oke okun nikan lo yẹ ki wọn rinrin ajo lọ si ilẹ okeere bayii,'' Dokita Mohammed lo ṣalaye bẹẹ.
Amọ, o sọ pe awọn eeyan yoo ṣi maa lanfaani lati rinrin ajo lati ipinlẹ kan si omiran kaakiri Naijiria.
- Ènìyàn 49 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdí ààrùn Coronavirus ní Naijiria
- Òní ni àṣekágbá ètò ìsìnkú olóògbé Dare Adeboye ni Redemption Camp
- Orílẹ̀-ède UK ti gbégi lé àwọn arìnrìàjò láti Nàìjíríà nítorí…
- Ẹ̀mí ọlọ́pàá mẹ́tàlá ló sọnù lópin ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́ àwọn "unknown gunmen"
- Mi ó ṣọ̀fọ̀, mo sọkún nítorípé... - Ìyàwó olóògbé Dare Adeboye sọ̀rọ̀ níbi ìsìn idágbére ọkọ rẹ̀













