Pastor Paul Adefarasin: Bí Naijiria kò bá rọrùn láti gbé ẹ gba orílẹ̀-èdè míì lọ

Adefarasin

Oríṣun àwòrán, @Adefarasin

Bó ṣe nípasẹ̀ ọkada ni tàbí ọkọ̀ ojú omi tàbí láti inú ihò ilẹ̀, ẹ wá ọ̀nà láti fi Naijiria sílẹ̀- Pasitọ Paul Adefarasin

Oluṣọagutan agba ati oludasilẹ ijọ House on The Rock, pasitọ Paul Adefarasin ti gba awọn ọmọ ijọ rẹ nimọran pe ki wọn fi Naijiria silẹ lọ ilẹ miran ti aye rẹ ba ṣi silẹ.

Ninu iwaasu rẹ to ṣe lọjọ Aiku lo ti sọ ọrọ naa nibi to ti sọ pe awọn to ti n ṣejọba Naijiri bọ latẹyinwa ati lọwọ yii ko kọbi ara si bi nnkan ṣe lọ.

Pasitọ naa ni bo tilẹ jẹ pe oun ni igbagbọ pe Naijira ṣi maa dara, oun ti wa wọrọkọ fi ṣ'ada lati fi Naijiria silẹ ti nnkan ba pada yiwọ.

O ni "Mo mu ikinni wa fun yin lati ọdọ pasitọ Ifeanyi to n ṣeto ọna abayọ wa… mo mọ pe ẹ ni igbagbọ o, emi naa ni igbagbọ, ṣugbọn mo ti wa abayọ lati fi orilẹ-ede yii silẹ."

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Adefarasi ṣalaye pe oun le ṣe iwaasu fun awọn ọmọ ijọ naa lati ibikibi lorile¬̣-ede agbaye pẹlu imọ ẹrọ, nitori naa lo ṣe ṣe pataki ki awọn eeyan naa tete wa ọna abayọ lati sa kuro ni Naijiria nitori gudugbẹ to ṣeeṣe ko ja lọjọ iwaju.

O ni "Bo ṣe nipasẹ ọkada ni tabi ọkọ oju omi tabi lati inu iwo ilẹ, ẹ wa ọna abayọ lati fi Naijiria silẹ nitori awọn adari Naijiria ko ni afojusun rere fun araaalu."

Pasitọ naa tun ke si awọn adari ijọba ni Naijiria lati tun Naijiria ṣe ki ogun abẹle keji ma baa bẹ silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ "Iṣoro Naijiria ti pọ ju ti tẹlẹ lọ, o si yẹ ki a ṣe iwadii awọn iṣoro naa lati ipinlẹṣẹ igba ti a gba ti ominira, bi bẹẹ kọ, ko si ohun ti a le ṣe lati yanju iṣoro ti a n koju."

Pasitọ naa pari ọrọ rẹ pe ko si orilẹ-ede kankan to le farada ogun abẹle meji.

Lẹyin naa lo rọ awoon adari lati pe ipade apero ki wọn si jiroro bi Naijiria yoo ṣe ni ilọsiwaju lawujọ awọn akẹgbẹ rẹ.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọrọ ti pasitọ naa sọ.

Bi awọn kan ṣe n kiin lẹyin pe ootọ ọrọ lo sọ lawọn mii n sọ pe kii ṣe irufẹ iwaasu to yẹ ko maa ṣe fun awọn ọmọlẹyin rẹ niyẹn.