Niger boat: Àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ṣì n wá àwọn èèyàn tó rì sínú omi nínú ìjàmbá ọkọ ojú omi

Ọkọ oju omi to danu

Ko din ni eeyan mejidinlọgbọn ti wọn ti sin oku wọn, lẹyin ijamba ọkọ oju omi to waye ni abule kan ni ijọba ibilẹ Munya, nipinlẹ Niger.

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ ipajawiri ni ipinlẹ Niger, sọ pe ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye, ti wọn ko si ti i ri eeyan mẹjọ.

Alaga ajọ naa, Alhaji Ibrahim Inga Ahmed, sọ fun BBC pe eeyan bi ọgọrun ni ọkọ oju omi naa gbe lati Zumba, ṣugbọn ọkọ naa ni ijamba nigba to ku diẹ ki wọn o de ibi ti wọn n lọ.

Iroyin sọ pe ọkọ oju omi naa kọlu nkan lori omi ni, ko to o doju de.

"Wọn ri eeyan mejilelọgọta doola lara awọn eero ọkọ, awọn mejidinlọgbọn ti ku, bẹẹni eeyan mẹjọ ko ti i di riri."

Awọn oṣiṣẹ adoola lori omi

Alhaji Ahmed sọ pe awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n wa awọn to ṣe e ṣe ko rì sinu omi.

Ijamba ọkọ oju omi ko ṣẹṣẹ ma a waye ni ipinlẹ Niger.

Alhaji Ibrahim Inga Ahmed sọ pe eyi ko ṣẹyin bi awọn odò to wa ni ipinlẹ naa ṣe n kun akunfaya, nitori awọn odo adagun 'dam' to pọ ni ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan