Àwọn òmùwẹ̀ ń wá èèyàn kan tó pòórá lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi to dójúdé l'Eko

awọn eeyan ninu ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, twitter/LASWA

Lai tii pe ọsẹ kan lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko kede iroyin ayọ pe ko si ijamba ọkọ ojuomi lawọn ojuna agbami ni ipinlẹ naa laarin oṣu mẹfa, eeyan kan ti di wiwa bayii lẹyin ti ọkọ oju omi kan to n rinna lọ loju agbami agbegbe Lekki dojude.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe mẹta ninu awọn to wa ninu ọkọ oju omi to dojude naa ni wọn doola ẹmi wọn.

Awọn mẹrin lo wa ninu ọkọ oju omi naa lasiko ti ijamba naa fi waye ṣugbọn wọn ṣi n wa ẹni kẹrin wọn bayii.

Iji nla to ja lori omi naa lasiko irinajo wọn ni wọn ni o ṣokunfa idojude ọkọ naa.

Awọn alaṣẹ ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ oju omi nipinlẹ Eko, LASWA atawọn ajọ miran la gbs pe wọn pawọ pọ ṣe bẹbẹ ni kete ti ijamba naa ṣẹlẹ lati doola awọn to wa ninu ọkọ naa.

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, awọn omuwẹ ṣi n wa eeyan kan to ku ninu ọkọ oju omi naa.