David Oyedepo: Ẹnikẹ́ni kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fipá mú mi gbabẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 - Oyedepo

Oríṣun àwòrán, @Oyedepo
Ẹ ò lè rí Covid-19 nínú ìjọ mi, ẹ má fi abẹ́rẹ́ rẹ̀ lọ̀ mí - Oyedepo
Oludasilẹ ijọ Living Faith kaakiri agbaye, Biṣọọbu David Oyedepo ti sọ pe iwalaaye Ọlọrun nilẹ Afrika ni ko jẹ ki arun Coronavirus gbẹmi ọpọ eeyan gẹgẹ bii awọn onimọ kan ṣe sọ ṣaaju.
Alufa naa lo sọ ọrọ ọhun lasiko to n waasu nibi isin idupẹ ajọdun ogoji ọdun ti wọn da ijọ naa silẹ.
Oyedepo ni "Awọn onimọ sayẹnsi kan sọ pe arun Corona yoo pa awọn eeyan nilẹ Afrika to bẹ ti ko ni si aye lati sin oku awọn eeyan naa si."
"Ṣugbọn Ọlọrun doju ti wọn nitori Afrika ni iye eeyan to kere julọ ti Corona pa wa."
Baba Oyedepo ni ko si ẹni to le fi ipa mu ẹnikẹni gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Oyedepo sọ pe "Ko si ẹnikẹni tabi alaṣẹ kankan to le fi ipa mu yin lati gba abẹrẹ ajẹsara kankan."
"Ẹ wo bi ero ṣe pọ nibi yii, ṣe ẹ gburo arun Corona kankan nibi…?"
Alufa ọhun ṣalaye pe iwalaaye Ọlọrun ni ko jẹ ki awọn lugbadi Covid-19 gẹgẹ bii asọtẹlẹ awọn onimọ sayẹnsi ṣaaju.
O ni ko si ẹnikẹni to le fi ipa mu oun lati gba abẹrẹ nitori oun ko mọ erongba awọn alaṣẹ ti wọn fi n lọgun abẹrẹ naa, o si fi kun pe oun mọ pe wọn ko ni erongba rere fun awọn araalu.
- Amotekun Ondo ju afurasí ajínigbé mẹ́rin s'átìmọ́lé, dóòlà àwọn tí wọ́n jígbé
- Ọkọ mi kò kú rárá- Arabinrin Temiloluwa aya olóògbé Dare Adeboye
- Ẹ̀mí ọlọ́pàá mẹ́tàlá ló sọnù lópin ọ̀sẹ̀ lọ́wọ́ àwọn "unknown gunmen"
- Orílẹ̀-ède UK ti fi kún iye òfin tó de àwọn arìnrìàjò wọn tó fẹ́ wá sí Nàìjíríà nítorí…
- Ènìyàn 49 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdí ààrùn Coronavirus ní Naijiria
Alufa ọhun ni ko bojumu ki wọn ki wọn kan an nipa fun eeyan lati gba abẹrẹ naa, tabi ki wọn fi ọwọ osi juwe ile fun eeyan nitori pe o kọ lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Oyedepo pari ọrọ rẹ pe eeyan kii ṣe ẹranko, nitori naa ko yẹ ki wọn dan abẹrẹ kankan wo lara awọn eeyan labẹ asia arun Coronavirus.
Biṣọọbu Oyedepo jẹ ọkan gboogi lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni Naijiria to maa n sọ erongba wọn jade, ti wọn ko si gbagbọ pe arun Coronavirus le ṣe wọn ni ohunkohun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kọkọ na alufa kan ti oun naa jẹ ọmọ Naijiria ni paṣan, iyẹn pasitọ Chris Oyakhilome lẹyin to waasu tako Covid-19 ati abẹrẹ ajẹsara ti wọn po lati koju ajakalẹ arun naa.
- Ìjọba àpapọ̀ kéde Òjọ́rú àti Ọjọ́bọ gẹ́gẹ́ bi ísinmi lẹ́nu iṣẹ́
- Ṣé ẹ rántí àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ilé ìjọba rí? Àwọn rèé
- Bó ṣe nípasẹ̀ ọkada ni tàbí ọkọ̀ ojú omi tàbí láti inú ihò ilẹ̀, ẹ wá ọ̀nà láti fi Naijiria sílẹ̀- Pasitọ Paul Adefarasin
- Ìnú ìpayà, ìbẹ̀rú ní a wà nítorí a kò tíì gburò Pásítọ̀ Ìjọ Deeper Life tí wọ́n jígbẹ lọ ni ìlú Akure- Ẹbí














