Sarah Dosekun, Obìnrin ẹni ọdún 67 di àwátì lásìkò tó ń lọ sí ìṣọ́ òru ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Others
Obìnrin ẹni ọdún 67 di àwátì ní ìpínlẹ Ogun lẹ́yìn tó dágbére ìṣọ́ òru nílé.
Awọn ẹbi obinrin oniṣowo kan, Sarah Dosekun, ti ko sinu hilahilo bayii ni bi obinrin naa ṣe dede di awati lẹyin to dagbere nile pe oun n lọ si iṣọ oru.
Iroyin ni obinrin ọhun wọ ọkọ lati agbegbe Mowe, ni opopna marosẹ Eko si Ibadan to si dagbere pe oun n lọ si ijọ alaṣọ funfun kan to wa ni agbegbe Ogba, nipinlẹ Eko.
- Lẹ́yìn ìwọ́de Yomi Fabiyi, ọlọ́pàá sọ ìdí tí wọ́n kò fi gba béélì Baba Ijẹsha, àti ìgbà tó ṣe é ṣe kí wọ́n ó fi sílẹ̀
- Ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ẹbí ẹ̀gbọ́n mí, Dare Adeboye rè é ... -Leke Adeboye
- Iyabo Ojo pé Yomi Fabiyi lẹ́jọ́, ìdí abájọ rèé
- Ifayemi Ẹlẹbuibọn ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láarin Àsàsí, Èdì àti Àfọwọ́fà
- Davido sí Yomi Fabiyi: Mùmú ni ẹ́
- Wo bí ìwọ́de Yomi Fabiyi nítorí ọ̀rọ̀ Baba Ijẹsha to wa ni àhámọ̀ ọlapàá ṣe n lọ nílùú Eko
Ọmọ obinrin naa, Janet ṣalaye fun awọn akọroyin pe igba ti oun gburo iya kẹyin ni asiko to de ibudokọ Asese, eyii to sun mọ ala ipinlẹ Ogun ati Eko.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "O kuro nile ni nnkan bii aago meje kọja iṣẹju mẹẹdogun aṣalẹ lọ si iṣọ oru, nigba to di aago mẹjọ ku iṣẹju diẹ ni wọn pe wa pe awọn ti de Asese, lẹyin naa ni ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn ko lọ mọ ti a ko si gburo wọn mọ titi di akoko yii."
Janet ni: "Auntie mi kan to ti wa nile ijọsin naa ṣaaju wọn tilẹ pe aago wọn titi, bẹẹ si ni ko lọ."
O ni awọn ti lọ fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ẹka ti Mowe leti.
- Ọmọdé méje àti olùkọ́ kan jẹ́ Ọlọrun nípè lẹ́yìn tí agbébọn ẹni ọdún 19 ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ wọn
- Òṣèré tíátà Yorùbá míràn tún kó sí gbaga ọlọ́pàá
- Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ gbé ohùn àdúrà sókè nítorí ètò ààbò Naijiria - Buhari
- Eid al-Fitr: Wo àwọn ohun tó yẹ ki o ṣe sáájú ìrun Yidi fún ọdún ìtúnu ààwẹ̀
- Ogójì èèyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ìjà tó ń wáyé láàrín Israel àti Palestine ní Lod
- Wo bí ìwọ́de Yomi Fabiyi nítorí ọ̀rọ̀ Baba Ijẹsha to wa ni àhámọ̀ ọlapàá ṣe n lọ nílùú Eko
Janet ni "A lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Mowe, wọn ni ka pada wa lẹyin wakati mẹrinlelogun.
Lẹyin naa ni a tun lọ si agọ ọlọpaa ti Warewa boya wọn wa lara awọn ti wọn faragba ninu ijamba ọkọ to waye lori afara Long Bridge ṣugbọn pabo ni gbogbo akitiyan wa jasi."
Ọmọ obinrin naa fikun pe igbagbọn awọn ẹbi ni pe ko ba ijamba ọkọ lọ, ko si si ẹni kankan to tii kan si awọn pe boya awọn ti ji obinrin ọhun gbe.
Nigba ti awọn akọroyin kan si agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, o sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun awọn si ti bẹrẹ iwadii.
Oyeyemi ni gbogbo ẹka ileeṣẹ awọn ni awọn ti ta lolobo to fi mọ olu ileeṣẹ naa ni Abeokuta, o fi kun pe o ṣeeṣe ki obinrin ọhun ti kuro ni ala ipinlẹ Ogun ko to di pe o poora.
- Ẹ ò lè rí Covid-19 nínú ìjọ mi, ẹ má fi abẹ́rẹ́ rẹ̀ lọ̀ mí - Oyedepo
- Kàyèéfì! Wo ìdí tí àlùfáà ìjọ Aguda fi ń kó ère ìṣẹ̀nbáyé pamọ́?
- Ọkùnrin kan bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni mi, àmọ́ o le darapọ̀ mọ́ ìwọ́de fún Baba Ijẹsha tí o ba tako ìfìyàjẹni
- Àwọn ọmọ Naijiria yóò rí akitiyan ìjọba láti yanjú ètò àbò tó mẹ́hẹ láìpẹ́ - Lai Mohammed
- Ẹni tó bá ní láàkàyè, a mọ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, àwà ti kọ lẹ́tà, èsì t'Ọ́lọ́pàá sì fún wa rèé - Yomi Fabiyi















