Eid al-Fitr: Wo àwọn ohun tó yẹ ki o ṣe sáájú ọdún ìtúnu ààwẹ̀ Ramadan, ìrun Yidi

Sallar Idi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awẹ Ramadan jẹ eleyi tawọn musulumi gbagbọ pe Allah fun ara rẹ nikan lo le san wọn lẹsan rẹ.

Ni bayi ti awẹ ti wa pari , ohun to kan ni kawọn musulumi se ayẹyẹ ọdun Eid Fitri taa mọ si ọdun itutnu awẹ nipa kuki irun laaye Yidi.

Irun Yidi yi jẹ ọna ati fi ọpẹ fun Olorun pe ẹmi wọn ba awẹ naa ja.

Yatọ si ọdun itunu awẹ, igba mii ti awọn musulumi tun maa n ki irun Yidi ni asiko ọdun Eid Adha taa mọ si ọdun Ileya.

Ki wa lawọn nkan to yẹ ki musulumi se lasiko yi saaju tabi lasiko igba to baa n lọ si irun Yidi?

Ekunrẹrẹ alaye ree lati ẹnu Sheikh Nura Khalid, Imam mọsalasi Apo to wa ni olu ilu Naijiria, Abuja.

1) Yiyọ zakat ul Fitr taa mọ si Jaka

Zakatul Fitr,tabi ọọrẹ sise di dandan lori gbogbo alaawẹ gẹgẹ bi Anobi Muhammad SAW ti se mu asẹ yi wa lati ọdọ Allah.

Ninu apejuwe awọn onimọ ẹsin taa ba sọrọ, Jaka yi jẹ bi afọmọ fawọn kudiẹkudiẹ to ba wa ninu awẹ ti eeyan gba.

Nkan tẹnu n jẹ ni ẹsin ni ki awọn Musulumi fi yọ bo ti lẹ jẹ pe lawọn aaye kọọkan awọn miran maa n fi owo yọ Zakatul Fitr yi.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Ki alaawẹ to lọ si irun Yidi lo ti gbọdọ yọ Zakatul Fitr yi, yala lọdun ku ọla tabi laarọ ọjọ ọdun.

To ba fi le kọja igba irun Yidi, o ti di saara ọjọ lasan ni yẹ.

Awọn alaini ni wọn maa n fun tabi ki wọn si gbe fun awọn ẹgbẹ ẹsin ti yoo pin fawọn to nilo rẹ.

Gari, Irẹsi, ọka baba, agbado tabi nkan miran ti eeyan le jẹ ni wọn fi n yọ Jaka.

Sallar Idi

Oríṣun àwòrán, Reuters

2) Wiwẹ iwẹ mimọ lọ si irun Yidi

Imọran ki a to lọ si irun Yidi se pataki. Iwẹ taa n sọ yi ko yatọ si iru eleyi taa maa n wẹ ki a to lọ si irun ọjọ Jimọ.

3) Jijẹun ki a to lọ si Yidi.

Ustaz Nura tẹsiwaju pe Sunnah yi naa pataki nitori bẹẹ la ti se ri kọ lati ọdọ Anọbi Muhammad.

Awẹ ti tan nitori naa ko yẹ ki musulumi wa febi panu lọ si irun Yidi.

Lara awọn ọjọ ti ko si igbalaye ki eeyan gba awẹ ni ọjọ ọdun jẹ.

Idakeji isesi yi ni aaye wa fun lasiko irun Yidi ileya.

Eeyan ko gbọdọ jẹun lọ si Yidi Ileya ni afijọ bi Anọbi Ibrahim ti se wa ninu ipo aijẹun nigba to fẹ lọ fi ọmọ rẹ Ibrahim jọsin ki Allah to wa fi agbo paarọ fun un.

4) Wọ asọ to daa, to si rẹwa lọ si Yidi

Islam faaye gba ki a mura daada lọ si Yidi lọjọ ọdun.

Koda bi ko ba jẹ asọ tuntun, a gbọdọ ri wi pe asọ yi ko dọti ti o si fanimọra.

Asọ funfun ni wọn gba awọn ọkunrin niyanju lati wọ ki wọn si lo turare.

Ọjọ idupẹ ni ọjọ yi jẹ nitori oore ooru Lilatul Qadr ti Allah fi kẹ awọn musulumi ninu rẹ.

Masallacin Idi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

5) Lara Sunnah ni ki eeyan maa se afọmọ bo ba ti se n lọ si Yidi.

Afọmọ yi jẹ gbolohun gbigbe Allah tobi lati ẹnu awọn Musulumi to lọ ki irun Yidi.

Ninu ohun taa le sọ ni ka sọ pe"Allahu Akbar, Allahu Akbar, Allahu Akbar," tabi "Allahu Akbar, Allahu Akbar, Lailaha illahahu Wallahu Akbar, Allahu Akbar Walillahil Hamd.

A tun le sọ pe: "Allahu Akbar Kabira Walhamdu lillahi kasira, Walhamdulillahi bukratan wa asila."

Ni kete ti Imaamu ba gun ori minbari la gbọdọ dake sisọ afọmọ yii.

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

6) A kii yan Nafila ba ba de Yidi

Irun Yidi ko ni Nafila yiyan kankan.

Idi ni pe irun yi fun ara rẹ, irun Nafila loun gaan jẹ.

Amọ bi eeyan ba fẹ ki irun Yidi ninu Mọsalasi nitori ojo, a le yan Nafila rakaa meji la ti fi ki Mọsalasi eleyi ti a n pe ni Taiyyatu Masjid.

Bi o ba jẹ ita gbangba la ti fẹ ki irun yii, ohun to yẹ ni ki olujọsin joko ki o si maa se afọmọ titi ti Imaamu yoo fi gun ori minbari.

7) Titẹti gbọ Waasi lẹyin irun Yidi.

Ni kete ti Imaamu ba pari irun Yidi, wọn a maa se isisti diẹ fawọn olujọsin.

O se anfaani pupọ ki a duro lati gbọ waasi yi lẹyin irun.

Ki see pe ka sare dide lati maa lọ sile lẹyin ti Imaamu ba salamọ tan.

Eyi kii se Sunnah gẹgẹ bi Sheikh Nura Khalid ti se salaye.

Anọbi Muhammad ninu alaye Sheikh Nura gbawa loungbẹ lati rosẹ gbọ waasi yi nitori o wa ninu nkan taa wa se ni Yidi lọjọ ọdun.

Sallar Idi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

8) Ki a gba ọna mii ta baa n pada sile

Ninu Sunnah ti Sheikh Khalid salaye pe a le se lọjọ ọdun ba ba ti n dari b lati Yidi ni pe ki a gba ọna ibomiran yatọ si ibi ta gba wa.

O ni Sunnah Anọbi ni ati pe o fẹ ki a gba ọna miran ta baa n pada sile.

Anọbi a maa se bẹ lati le ki awọn eeyan miran yatọ si awọn to ki nigba to n lọ si Yidi.

9) Obinrin naa le lọ si Yidi nitori irun Yidi ko yọ ẹnikankan silẹ.

Ọmọde tagba, ọkunrin ati obinrin ni igbalaye wa fun lati lọ kirun Yidi.

Obinrin to baa n se nkan alejo naa le lọ sugbọn wọn ko ni bawọn kirun.

Wọ n o kan duro sẹgbẹ kan lasiko tawọn iyoku baa n kirun ni.

Ustaz Khalid ni o yẹ ki awọn obinrin bori ati ara wọn lọ́ si Yidi.

Lẹyin awọn ọkunrin lo yẹ ki wọn to si.

Eyi to se anfaani gẹgẹ bo se sọ ni ki awọn obinrin to saafu tiwọn sẹyin tawọn obinrin.