Baba Ijesha: Ẹ wo àbábọ̀ ìpàdé Yomi Fabiyi pẹ̀lú àwọn àgbà agbẹjọ́rò

Yomi Fabiyi atawọn agbẹjọro

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Gbajugbaja oṣere Yomi Fabiyi ti gbe igbesẹ lẹyin ti akẹgbẹ rẹ Iyabo Ojo fi iwe ipẹjọ beere fun Ọgọrun un miliọnu naira lọwọ rẹ fun pe o parọ nkan ti oun ko sọ mọ oun.

Yomi Fabiyi lọ ṣe ipade pẹlu awọn agbẹjọro lori ọrọ to n duro le lori lati ọjọ yii eyiun, pataki ẹtọ ọmọniyan lori eyi to fi tun ṣe iwọde ifẹhonuhan pe ki wọn tu Baba Ijesha silẹ pẹlu beeli.

Awọn agbẹjọro ti Yomi ba ṣe ipade ni agbẹjọro Adesina Ogunlana Esq. (alaga ẹgbẹ awọn amofin tẹlẹ ni Ikeja), agbẹjọro Ayo Ademiluyi, Comrade Aghedo Kehinde (ajafẹtọ ọmọniyan).

Gbogbo igbesẹ rẹ yii da lori ẹtọ akẹgbẹ rẹ, Lanre Omiyinka ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijesha.

Oun ni wọn fi ẹsun ifipaba ọmọde lopọ kan to si ti wa lahamọ ọlọpaa lati igba naa tori awọn ile ẹjọ ko tii fopin si iyanṣẹlodi wọn.

Ipo ti Baba Ijesha wa bayii

Awọn agbẹjọro naa ni nigba ti awọn de agọ Ọlọpaa agbegbe Panti pẹlu akẹgbẹ rẹ Yomi Fabiyi ti awọn jọ lọ lati yẹ Baba Ijesha wo, "ṣe lo ri ráhun-ràhun, bi ẹni ti iya ti jẹ to ni idamu ọkan to si n tiro lori ẹsẹ kan, ẹsẹ ọtun rẹ".

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha

"Ẹtọ ọmọ eniyan ṣe koko. Idajọ kankan ko lee dara bi wọn ko ba faaye gba ki awọn tọrọ kan ri sọ tabi ki wọn gbọ tẹnu wọn ki wọn si da abo bo ẹtọ wọn".

Yomi Fabiyi tẹnu mọ ọ pe lai fi ti ohun to n ṣẹlẹ si eeyan ṣe, o yẹ ki ibọwọ wa fun gbogbo eeyan.

"E lee tẹra mọ jija fun ẹtọ eeyan, ẹ lee ni imọlara ati itara si ohun to ṣe eeyan kan amọ ẹ ma ṣatilẹyin fun ohun to ba mu ẹtọ ẹlomiran kuro ati ilokulo ofin".

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Yomi ni iru nkan bayii maa n dunkoko mọ idagbasoke ati alafia ni.

Ẹwẹ, loju opo ayelujara ọkan lara awọn agbẹjọro ti Yomi Fabiyi ba ṣe ipade ti fi ara re han ni agbẹjọrọ Babab Ijesha.

O o fi lẹta ti o kọ lorukọ ileeṣẹ rẹ si kọmisọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko ninu eyi to ti sọ wi pe ohun gẹgẹ bi amofin ati agbẹjọro to n duro fun afurasi ọdaran to wa lahamọ wọn, Baba Ijesha.

Ati wi pe o han gbangba pe lati bii ọsẹ melo kan ti ọrọ yii ti bẹrẹ, aridaju ti hande to si tumọ si pe imọran to yẹ ki wọn gba labẹ ofin bayii ni ki wọn gba beeli rẹ.

Lẹta

Oríṣun àwòrán, Adeshina Ogunlana

Ninu iwe ti agbẹjọrọ naa kọ si kọmisọnna ọlọpaa Eko, o ni "a fẹ ko di mimọ pe fifi afurasi si atimọle ju ọgbọn ọjọ lọ lodi si ofin to ti ẹtọ ọmọniyan lẹyin labẹ ofin Naijiria ti ọdun 1999".

Wọn pe fun ki kọmisọnna ọlọpaa tete wa nkan ṣe si ọrọ yii.

Lori lẹta naa la ri ti wọn fi ontẹ ọfiisi kọmisọnna ipinlẹ Eko jan an eyi to tumọ si wipe o ti ri i o si ti tẹwọ gba lẹta naa, amọ ibuwọlu kọmisana la ri, ko tii wa si gbangba sọ ohunkohun.