Akure Akomolede: Àwọn Olùkọ́ Akure pegedé lórí ètò Akomolede àti Aṣa lórí BBC Yorùbá

Akure Akomolede

Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba ni eto akanṣe to maa n wa fun un yin ki ede ati aṣa Yoruba ma baa parun

Eto naa wa lori ikanni BBC pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ Onimọ ede Yoruba YSAN ati apapọ ẹgbẹ Akomolede kaakiri ipinlẹ Naijiria.

Ilu Akurẹ ni ipinlẹ Ondo ni awọn olukọ to n dabira yii ti wa la.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Mọ̀ si nípa àṣà ìsọmọlórúkọ́ nílẹ̀ Yorùbá àti ìtumọ̀ orúkọ̀ fún ìkókó

1) Arabinrin Modupe Ajileye lati ile ẹkọ St Thomas's Anglican Comprehensive, Oke Aro, akurẹ ni olukọ to yaranti to kọ nipa aṣa Isọmọlorukọ ni ilẹ Yoruba.

Olukọ yii ṣalaye igbesẹ itọju oyun ati oriṣi orukọ ti Yoruba n sọ ọmọ wọn.

Bakan naa lo tun mẹnuba awọn ohun eelo isọmọlorukọ bii obi, orogbo, adun, iyọ ireke, oyin, suga ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Ọdalẹ ni Babangida ati Abacha - Ọmọ Abiola

2) Arabinrin Victoria Sefunmi Atẹẹrẹ lati ileẹkọ St Micheal's Catholic High School.

Olukọ agba yii lo kọ wa ni Akanlo Ede.

Nibẹ lo ti ṣalaye ni ọrinkiniwin lori awọn ọrọ abẹ ahọn ti ko le tete ye ẹni ti ko ba gbọ ogidi ede Yoruba.

Àkọlé fídíò, Àwọn èdè abẹ́ ahọ́n tóo lè fi sọ̀rọ̀ rèé láì tú àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ áyé

3) Ijala ere Ọdẹ ni ewi alohun Yoruba to jẹ mọ aṣeyẹ to jẹ re awọn ọdẹ ni a gbe yẹwo.

Arabinrin Modupe aya Azeez lati ile ẹkọ Akure Commercial Secondary School ni olukọ to fi ewi alohun yii dabira.

Gbogbo igbesẹ inu Ijala ati akoonu Ijala ere ọdẹ naa ni olukọ yanana fun wa.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Kí ni Ìjálá láàrin àwọn ewì alohùn àti bí wọ́n ṣe ń sun-ún?

4) Ipolowo Ọja ni agunmu owo ni igbagbọ Yoruba.

Koko yii ni Arabinrin Olayinka Olorunyolemi kọ wa lori eto Akomolede lonii.

Ileẹkọ St Louis Girls Grammar School ni Akure ni olukọ wa ti wa.

Oriṣi ọna ipolowo ọja laye atijọ ati laye ode oni ni olukọ ṣalaye fun wa.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

5) Arabinrin Kemi Abiodun lati ile ẹkọ Celestial Church Grammar School ni Awulẹ Akurẹ ni olukọ wa to yaranti.

Olukọ yii lo kọ wa nipa Ọrọ Arọpo Afarajorukọ ninu girama ede Yoruba.

Olukọ fi ọpọlọpọ apẹẹrẹ ṣlaye gidi nipa ẹkọ yii fun wa.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé

Ẹ ma gbagbe pe BBC Yoruba n ṣe kookari eto yii lati rri pe ede ati aṣa Yoruba ko parun ki itẹsiwaju si ba ede naa.

Njẹ iwọ n sa ipa rẹ fun idagbasoke Yoruba bi?

Yoruba dun lete pupọ.

Àkọlé fídíò, Òǹtàjà aṣọ ni mí tẹ́lẹ̀, ọ̀dá owó ló sọ mi di alábárù