#PantamiMustGo: Ajàfẹ́tọ́, Aisha Yesufu sọ ìdí tí kò fi lè so nọ́mbà fóònù rẹ̀ mọ́ nọ́mbà ìdánimọ̀ àpapọ̀ Nàìjíríà, NIN

aisha yesufu

Oríṣun àwòrán, Twitter/ aisha shehu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajafẹtọ ọmọniyan ni, Arabinrin Aisha Yesufu ti sọ pe ko sohun to jọọ o.

O ni oun ko le e so nọmba idanimọ apapọ ilẹẹ Naijiria, NIN mọ nọmba ibanisọrọ oun layelaye gẹgẹ bi ijọba apapọ Naijiria ṣe n fọnrere rẹ bayii.

Aisha Yesufu ni, siso oju opo numba ibanisọrọ oun mọ nọmba idanimọ apapọ NIN "yoo mu ki awọn iroyin to ṣe koko nipa oun wa ni ikawọ awọn elegbe ati alabaṣiṣẹpọ awọn agbesunmọmi" lorilẹ-ede Naijiria.

Aisha fi eleyi han loju opo Twitter rẹ nigba ti oun naa n da si ọrọ kan to n ja loju opo Twitter labẹ koko ọrọ #PantiMustGo.

Nibẹ ni awọn ero ori Twitter kan ti n pe fun iyọkuro nipo minisita fun ibanisọrọ lorilẹ-ede Naijiria, Isa Pantami.

"Ẹ jẹ ki n sọ ọ laifọtape pe, emi ko lee so nọmba idanimọ apapọ ilẹẹ Naijiria, NIN mọ nọmba ibanisọrọ mi o!

O san ki n kuku maa ni ẹrọ ibanisọrọ rara ju ki n finufindọ ko awọn iroyin to ṣe koko nipa oun wa ni ikawọ awọn elegbe ati alabaṣiṣẹpọ awọn agbesunmọmi #PantamiMustGo"

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ipe fun iyọkuro nipo minisita fun ibanisọrọ lorilẹ-ede Naijiria, Isa Pantami n jo bi ina ẹrun lori ayelujara.

Eyi ko ṣehin nitori ọrọ iwasu kan to gbe kalẹ lawọn ọdun diẹ sẹyin ninu eyi to ti n ṣe atilẹyin fun awọn ẹgbẹ agbesunmọmi bii Al-Qaeda ati Taliban.

Amọṣa ileeṣẹ arẹ ti sọ pe ko sọrọ lori rẹ nitori nigba ti minisita Pantami sọ ọrọ yii ọmọde lo n ṣe e, o si ti yipada lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale