Student commits suicide: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ fásítì Akungba gbẹ̀mí ara rẹ̀?

Igbẹmi ara ẹni

Oríṣun àwòrán, others

Iroyin to lu ori ayelujara ni pe akẹkọọ nipa eto oṣelu ni fasiti ipinlẹ, ni ipinlẹ Ondo to wa niluu Akungba Akoko, Feranmi Fasunle Omowunmi.

Feranmi ti nọmba igbaniwọle rẹ si ile ẹkọ naa jẹ 180503006 ni iroyin sọ pe o mu oogun peku peku lati pa ara rẹ l'Ọjọru.

Ko si ẹni to le sọ pato ohun to ṣe okunfa iku ọdọmọbinrin naa ṣugbọn awọn kan sọ pe o ṣeeṣe ki o gbẹmi ara rẹ lẹyin ti ibaṣepọ rẹ pẹlu ọrẹkunrin rẹ fori ṣanpọn.

Ṣugbọn awọn ọrẹ to sun mọ ṣalaye fawọn akọroyin pe irọ nla lọrọ naa nitori awọn ko mọ ọ mọ ọkunrin kankan lati igba to ti wọle si ile ẹkọ naa.

Iroyin sọ pe awọn ọrẹ Feranmi lo ri pe o ti mu oogun ti o si n pọkaka iku ninu ile rẹ.

Lati ibẹ ni wọn ti gbe e lọ si ile iwosan fun itọju awọn eleru ti sun igi.

Àkọlé fídíò, International Nurses Day 2021: Wo ìpèníjà àti àǹfàní inú iṣk nọ́ọ̀sì- Adetokunbo Shaba

A gbọ wi pe awọn obi rẹ wa nile iwosan nibi ti o ti pada gbẹmi mi.

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ṣalaye pe otitọ ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, amọ ko si ẹni to le sọ pe ohun to faa to fi pa ara rẹ gan na niyii.

Nigba ti BBC Yoruba ba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọrọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Teo Ikoro sọ pe awọn naa ti ka nipa iṣẹlẹ ọhun lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Ṣugbọn Ọgbẹni IKoro ṣalaye ko si ẹni ti o tii mu ọrọ naa wa sọdọ awọn ọlọpaa.

Ọgbẹni Ikoro ni ileeṣẹ ko le mu ẹnikẹni ti eeyan ba gba ẹmi ara rẹ.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa le bẹrẹ iwadii ti awọn ẹbi ẹni to ba p ara ba fu ra si ẹnikan pe oun lo wa ni idi rẹ loku.