Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dóòlà ọmọ oṣù kan tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko

Abandoned baby

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti doola ẹmi ọmọ oṣu kan ti wọn gbe ju si ẹba ọna nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọhun, Muyiwa Adejobi fi ṣọwọ si BBC Yoruba, o ni wọn ri ọmọ jojolo naa ni orita ti ile epo Odun-Ade wa, iyẹn ni ibudokọ Orile.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn eeyan kan to n kọja lẹba ọna ọhun lo ke si awọn agbofinro ni ẹka Orile lati wa wo ọmọ naa, lẹyin naa ni wọn gbe ọmọ ọhun lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ọrọ awọn obinrin, eyii to wa ni Ikeja.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti foju ganni ọmọ naa, o si ti paṣẹ pe ki wọn fun ni itọju to peye.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan ilu yoo gbe ọmọ sọnu nilu Eko ninu ọdun yii.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

Lọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta ọdun ti a wa yii, oninure kan pe akiyesi ileeṣẹ ọlọpaa si ọmọ kan ti wọn gbe sọnu lagbegbe Oko Oba, niluu Eko.

Ninu oṣu Kẹta kan naa ni wọn ri oku ọmọ jojolo miran lẹba ile iwosan Ayinke, to wa ni opopona papakọ ọkọ ofurufu, ni Ikeja niluu Eko yii kan naa.

Odumosu ti wa ṣeleri pe oun atawọn alabaṣiṣẹ oun yoo fọ ilu Eko mọ kuro lọwọ awọn iwa bii ki eeyan maa gbe ọmọ sọnu.

Àkọlé fídíò, 'Tééyàn bá kú a lè yọ yọ ojú yẹn tẹ́ẹ bá gbà wá láyé, a lè dá a sí fún ẹlòmíràn'