Yoruba Nation: Kókó mẹ́ta tí Sunday Igboho sọ nípa ìbo 2023 níbi ìwọ́de l‘Osogbo

Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ti ṣalaye fun awọn to n kigbe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Yoruba Nation, pe oun atawọn ẹlẹgbẹ oun ko ni gba eto idibo laaye mọ ni ilẹ Yoruba, titi di igba ti ẹkun naa ba gba ominira rẹ.
Lọjọ Satide ni Igboho sọrọ yii lasiko to fi n ba awọn to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba sọrọ nibi iwọde itagbangba kan to waye nilu Osogbo.
Igboho tun rọ awọn ọmọlẹyin rẹ lati dẹkun nina ika aleebu si awọn gomina ipinlẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria nitoripe gbogbo wọn lo duro lẹyin ipe ti wọn n ja fun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- A ti ṣe iṣẹ́ ribiribi lórí ètò ààbò láti ìgbà tí a ti gorií àléfà- Ààrẹ Buhari
- Àwọn Aláṣẹ ilẹ̀ Palestine ní eèyàn 139 ló ti kú ní Palestine nínú ìja Isreal àti Palestine
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọmọ oṣù kan he lẹ́ba ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko
- Èèyàn márùn ún kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ẹ̀ni ọdún 42 kan l'Ẹ́dẹ
- Kò sẹ́ni tó lè ní kí n má yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi
- Ẹ̀yìn tí ẹ̀ ń pè fún Yoruba Nation, òpè ní yín, ẹ kò ní ìmọ̀- Ladoja
O ni nitori ibẹru pe ki ijọba apapọ o ma gbẹsẹ le owo ipin oṣooṣu to n kan ijọba ipinlẹ wọn, ni wọn ṣe ṣe ẹnu ni mẹnumọ.
Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi awọn oṣiṣẹ aṣọbode kan ṣe yinbọn pa awọn olugbe ilu Isẹyin kan lọjọ diẹ sẹyin.
O fikun pe asiko to fun ijọba lati fopin si ipẹjọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to mu Isikilu Wakili, afurasi ti wọn fi ẹsun ọpọlọpọ iṣẹlẹ ijinigbe kan ni ilu Igangan ati agbegbe rẹ.
O fi kun pe aifi panpẹ ofin gbe awọn ọdaran darandaran to n da wahala silẹ, ti mu ki aya tubọ ko wọn lati maa hu awọn iwa kotọ kaakiri orilẹede Naijiria.
Awọn oluwọde fun Yoruba nation mu afurasi osisẹ DSS
Ẹwẹ, fidio kan tun fara han lori ayelujara lẹyin iwọde naa, eyi to ṣafihan bi awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho ṣe mu eeyan kan ti wọn fura si pe oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni.
Arakunrin naa to pe ara rẹ ni Idowu Ọlayinka ṣalaye ninu fidio naa pe, ijọba apapọ loun n ba ṣiṣẹ ati pe ọfiisi awọn ni wọn ti ni ki oun lọ mu nọmba ọkan lara awọn ọkọ to n tẹle Sunday Igboho.
Ileeṣẹ DSS ko tii sọ ohunkohun boya lootọ tabi irọ ni arakunrin naa jẹ ara awọn oṣiṣẹ rẹ.

Sunday Igboho àtàwọn ọmọ Yoruba láti ìpínlẹ̀ mẹ́jọ ṣe ìwọ́de 'Yoruba Nation' nílùú Osogbo

Oloye Sunday Igboho ati ogunlọgọ awọn eeyan to n ja fun ominira ilẹ Yoruba, Yoruba Nation, ti ṣe iwọde niluu Osogbo, to jẹ olu ilu ipinlẹ Osun.
Awọn oluwọde naa to bẹrẹ iwọde ọhun laarọ ọjọ Abamẹta gbe oniruru kaadi lọwọ ti wọn kọ awọn akọle kan si bii "A fẹ ominira" ati "Ọmọ Yoruba ile ya" ati bẹẹbẹẹ lọ.
Wọn bẹrẹ iwọde naa lati agbegbe Ogo-Oluwa, titi de Olaiya, Freedom Park, Old Garage atawọn agbegbe mii to ṣe pataki niluu Osogbo.
Nigba to n sọrọ nibi iwọde naa, Sunday Igboho sọ pe asiko ti to ki ilẹ Yoruba bọ lọwọ awọn amunisin to n pa awọn eeyan ilẹ rẹ lai bikita.
- lai biÈèyàn márùn ún kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ẹ̀ni ọdún 42 kan l'Ẹ́dẹ
- Kò sẹ́ni tó lè ní kí n má yan àwọn Baálẹ̀ nílùú Akure- Ọba Aladetoyinbo Aladelusi
- ICPC ń wá ọkọ ọmọ Buhari àtàwọn méjì míì lórí ṣíṣe $65,000,000 kúmọ kùmọ
- Àwọn ọlọ́pàá fojú afurasí to ṣekúpa Iniubong Umoren hàn bí ó ti wọ káà ilẹ̀ lọ
Ọgọọrọ awọn agbofinro lo peju sibi iwọde naa lati pese eto abo to peye.
Lara awọn agbofinro to peju sibi iwọde ọhun ni awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ileeṣẹ ọlọpaa, awọn oṣiṣẹ abo araẹni labo ilu, awọn ọlọde ilu, ati bẹẹ beẹ lọ.
Irufẹ iwọde bẹẹ ti kọkọ waye ni ilu Ibadan, ni ipinlẹ Oyo ati ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun.
Awọn onigbọwọ iwọde ọhun ti ṣeleri pe awọn yoo geb iwọde naa de ipinlẹ Ondo ati Ekiti laipẹ.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?
Àwọn ọmọ Yoruba láti ìpínlẹ̀ mẹ́jọ wọ́de fún ìdásílẹ̀ 'Yoruba Nation' ní ìlú Osogbo

Awọn igun ọmọ Yoruba to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Yoruba nation pade ni ilu Oṣogbo tii ṣe olu ilu Ipinlẹ Ọṣun loni.
Iwọde wọn ọhun to waye fun ọpọlọpọ wakati da lilọ bibọ ọkọ duro ni ilu Osogbo.
Gbogbo bi wọn ti n wọde ni wọn n kọrin ijagbara ati ẹhonu lori ipenija ti wọn woye pe o nkoju iran ọmọ Yoruba ni orilẹede Naijiria.
lati ipinlẹ Kogi, Kwara, Eko, Ọyọ, Ogun, Ondo, Ekiti ati Ọṣun lawọn oluwọde naa ti wa

Ọpọlọpọ awọn to sọrọ nibi iwọde naa ni wọn ni bi nnkan ṣe ri lorilẹede Naijiria bayii, nnkan ko rọgbọ, bẹẹni ohun ẹya gbogbo to so Naijiria pọ ko ṣọkan.

Wọn fi kun un pe ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba kii ṣe eyi ti o la wahala, jagidijagan lilo ibọn tabi ohun ija oloro dani rara.


- Irọ́ ni pé àwọn ajínigbé ń bèèrè fún N30m láti tú pásítọ̀ Deeper Life sílẹ̀- ọmọ pásítọ̀
- Ẹ̀yìn tí ẹ̀ ń pè fún Yoruba Nation, òpè ní yín, ẹ kò ní ìmọ̀- Ladoja
- Aàrẹ Joe Biden sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí ìja Isreal àti Palestine
- Àwọn eèyàn kan fara gbọta níbi ìjà àwọn Aṣọ́bodè àti Ònífàyàwọ́ nígboro Iseyin lọ́jọ́ ọdún
- 'Nígbá tí a rí Baba Ijesha lónìí ní Panti, ohun tójú wa rí, ẹnu kò lè sọ o!'
- ''Àwa àgbààgbà òṣèré kò dákẹ́ lórí wàhálà láàrin Iyabọ Ojo ati Yomi Fabiyi nitori Baba Ijẹsha''






























