A ti ṣe iṣẹ́ ribiribi lórí ètò ààbò láti ìgbà tí a ti gorií àléfà- Ààrẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu
Aarẹ Muhamadu Buhari ti ṣalaye ọrọ lori ipenija nnkan ijagun to n koju awọn omo ogun bi wọn ṣe n koju awọn ikọ Boko haram.
Aarẹ ṣalaye pe kii ṣe igba diẹ ni lo n gba awọn ki wọn to ko ohun ija ogun wọle si Naijiria ati ki wọn to kọm awọn ologun bi wọn ṣe n lo awọn ohun ija atawọn irinṣẹ naa.
O ni adiyẹ n laagun ṣugbọn iyẹ ni ko jẹ kayẹ mọ ati pe ijọba oun n sa ipa rẹ sugbọn omi lo pọ ju ọka lọ.
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá rí ọmọ oṣù kan he lẹ́ba ọ̀nà lẹ́yìn tí wọ́n gbé e sọnù l'Eko
- ICPC ń wá ọkọ ọmọ Buhari àtàwọn méjì míì lórí ṣíṣe $65,000,000 kúmọ kùmọ
- Aàrẹ Joe Biden sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí ìja Isreal àti Palestine
- Sunday Igboho àtwọn ọmọ Yoruba láti ìpínlẹ̀ mẹ́jọ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de 'Yoruba Nation' nílùú Osogbo
"Bi a ba ni ki awọn to n ṣe nnkan ija o ṣe ọkọ ijagun, yoo gba akoko ki wọn to se tan, o le gba ọdun, igbesẹ to pẹ ni"
Àwọn ọmọ Naijiria mọ ipo ti a wa lasiko ti a de ni ọdun 2015 ati ipo ti a wa bayii paapaa julọ lori ọrọ eto abo ati eto ọrọ aje, a n sa ipa wa"
"Pẹlu gbogbo nnkan ti a ni ikawọ wa, a n ṣe iwọn ti a le ṣe lori ọrọ abo, awọn ọmọ ile igbimọ asofin naa n fọwọsowọpọ pẹlu wa"
Ààrẹ Buhari ni iṣẹ ribiribi ti awọn ọmọogun n ṣe lọwọ bayii ni lati ri adaju pe awọn eniyan pada si ori ilẹ wọn ki wọn le maa bá iṣẹ oojọ wọn lọ ki aara ilu le ri ounjẹ jẹ.
Buhari ọrọ rẹ pe "Ti ẹ ba mọ ajagun fẹyin ti ti é si bii, wọn yoo sọ iyatọ laarin asiko ti a de ati isinyi, bi a ṣe se ti ṣe iṣẹ to, iye eniyan ti a ti se idanilẹkọ fun."
Lẹyin naa lo ni "Ti ko ba da ẹ loju lọ bere lọwọ awọn ara Borno."












