Yoruba Nation: Àbọ̀ tí Sunday Igboho mú bọ̀ rèé lẹ́nu àbẹ̀wò rẹ̀ sọ́dọ̀ Guru Maharaji

Sat Guru Maharaji ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ajijagbara fun idasilẹ́ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti se abẹwo sọdọ asaaju ẹsin One Love Family, Sat Guru Maharaji nilu Ibadan.

Igboho, ẹni to ko ọpọ awọn ajijagbara sodi lọ sile asaaju ẹsin naa to wa loju ọna marosẹ Ibadan silu Eko, ni ko si ẹni to mọ idi to fi lọ.

Amọ fidio kan to n ja rain lori ayelujara lo safihan Igboho to n kan saara si Maharaji fun atilẹyin rẹ lori ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba.

Bakan naa lo n rọ asaaju ẹsin naa lati kede atilẹyin rẹ nita gbangba fun ominira orilẹede Yoruba nitori o ni awọn gbadun bo se dugba gbogbo nnkan tawọn n se.

Àkọlé fídíò, Yemi Farounbi: Yorùbá yóò dáàbò bo ara rẹ́, bí ìjọ́ba bá kùnà láti ràgà bò wọ́n

Nigba to n fesi, Sat Guru Maharaji ni atẹlẹwọ ẹni kii tan ni jẹ, ati pe gbogbo awọn orisa wa, omi , odo, Oluwo, Apena atawọn Ọba wa mọ pe oun duro ti Sunday Igboho.

"Gbogbo awọn igbesẹ to n gbe pe ki iran Yoruba ma subu tabi parẹ, o si da mi loju pe gbogbo orisa ilẹ Yoruba lo duro ti Igboho.

Bi o si se n lọ ni yoo se ohun to yẹ ko se ti ko fi ni si wahala mọ nitori awọn to wa niwaju gan, o ti rẹ wọn."

Àkọlé fídíò, Alara tí Ilara Epe: Òjò gbọ́dọ̀ rọ̀ lásìkò ọdún Ẹlẹ́gba ni ìlú Epe- Oba Olufolarin Ogunsan

O wa rọ awọn akẹkọọ ati gbogbo araalu lati duro ti Igboho, ki wọn si duro lori otitọ, ka le gba Naijiria la, amọ ti ko ba ri bẹẹ, a jẹ pe oduduwa ti duro niyẹn.

Guru Maharaji ni "a ko binu tabi ba ẹnikẹni ja amọ a ko le duro sile ki ebi maa pa wa, ka wa ro pe o digba ta ba de ọrun, ki ara to tu wa, rara, a gbọdọ gba ara wa la.."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asaaju ẹsin naa wa kesi awọn gomina nilẹ Yoruba lati maa tọju awọn eeyan to n jija gbara fun ilẹ Yoruba, o ni ko yẹ ki wọn sa gbogbo nnkan si oorun.

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'

"Ẹ fun wọn ni mọto, bi wọn se n se ni Amẹrika, Japan nuu. Ti wọn ba ri olotitọ, wọn maa n duro ti wọn ni, ẹru ko gbọdọ ba yin. Oduduwa ti de o."