Israel-Palestinian conflict: Irọ́ táwọn kan ń gbé kiri lórí ìjà tó wáyé

Israel-Palestinian conflict: Irọ́ táwọn kan ń gbé kiri lórí ìjà tó wáyé

Oriṣiiriṣii iroyin lo gba ori ayelujara kan lẹnu ọjọ mẹta yii.BBC ṣe iwadi awọn iroyin ofege to n jade lati ọdọ awọn to gbe lẹyin Israel ati Palestine lati igba ti ija naa ti bẹrẹ.Agbẹnusọ fun olootu ijọba orilẹ-ede Israel, Benjamin Netanyahu pin fidio kan lori Twitter eyi to ni o n ṣafihan bi Hamas ṣe ju rọkẹẹti sí ibi tawọn eeyan Israel pọ sí.

Àkọlé fídíò, Face Transplant: DiMeo ṣùn lásìkò tó n wa ọkọ̀ lálẹ́, ló bá jóná nígbà tí ọkọ̀ gbiná

Ṣugbọn fidio yii ti pẹ, orilẹ-ede Syria ni wọn si ti lo o.

Nigba ti ijọba Syria kọju ija si awọn ọlọtẹ niluu Deraa lọdun 2018 ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

Lẹyin ti ọpọ tako Ofir Gendelman to fi fidio naa soju opo Twitter ni ọgbẹni fa fidio ọhun yọ

Bakan naa, irọ ni ọpọ ọrọ tawọn sọ pe ileeṣẹ ọm'ogun Israel lo fi soju opo Twitter

Awọn eeyan naa kọ soju opo Twitter wọn pe "a nífẹẹ si ka ṣa maa payan.

A ṣẹṣẹ fi ado oloro pa awọn ọmọde kan ni

Irọ nla gbogbo rẹ, arumọjẹ ori ayelujara lasan ni.

Awọn eeyan kan to n gbe lẹyin Palestine naa pin fidio kan ninu eyi ti wọn ti sọ pe awọn ọmọ Israel ti sọ ina si mọṣalaaṣi al-Aqsa to wa ni ila oorun Israel.

Otitọ ni fidio yii amọ igi to wa lẹgbẹ mọṣalaaṣi naa lo gbana kii ṣe mọṣalaaṣi gan an gan an.Mọṣalaasi to wa ni ilu Jerusalem jẹ ọkan lara mọṣalaaṣi t'awọn musulumi Palestine fẹran julọ.

Ileeṣẹ iroyin Reuters tiẹ sọ pe igi naa jina bi iwọn bàtà mẹwaa sí ibi tí mọṣalaaṣi ọhún wa.