Manchester United vs Leicester: Leicester City ṣẹ́ṣó ìyà fún Man United, Man City gba ife ẹ̀yẹ Premier League ti sáà yìí

Kevin De Bruyne

Oríṣun àwòrán, Twitter/Kevin de Bruyne

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti gba ife ẹyẹ Premier League fun saa bọọlu yii.

Man City gba ife naa lẹyin ti Leicestrer City lu Man U mọle pẹlu ami ayo meji sẹyọkan lọjọ Iṣẹgun.

Ami ayo mẹwaa ni Man City fi n ṣiwaju United ninu eyi ti wọn si ni ifẹsẹwọnsẹ mẹta pere to ku ti wọn yoo gba ti saa yii yoo fi pari.

Igba kẹta ti Man City yoo gba ife ẹyẹ Premier League ree laarin ọdun mẹrin ti Pep Guardiola ti di akọnimọọgba wọn.