Insecurity in Nigeria: Awọn janduku agbébọn tun ti ṣekupa ọlọpaa meji lẹnu iṣẹ ti wọn si tun dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá.

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn janduku agbebọn tun ti ṣekupa ọlọpaa meji lẹnu iṣẹ ti wọn si tun dana sun agọ ọlọ́pàá.

Ni idaji ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ní àgọ ọlọpaa Ubakala ni ijọba ibilẹ Gusu Umuahia nipinlẹ Abia.

Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Abia, SP Godfrey Ogbonna lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akoroyin.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

Ogbonna ni bíi ago mejila kọja isẹju mẹwaa loru ni lawọn janduku ọhun de pẹlu ado oloro.

O ni awọn ọlọpaa to lọ kọju ija si wọn gbiyanju agbara wọn, ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ.

Ogbonna ni oun ko le sọ ni pato iye t'awọn janduku agbebọn naa jẹ.

Awọn ọlọpaa to f'arapa nibi iṣẹlẹ naa sí wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọrọ naa ti di ọmọ to ni iya oun ko ni sun bayii, oun naa ko ni foju boorun.

Bi ọjọ marun un sẹyin lawọn ọlọpaa meji lẹyin tawọn agbebọn kọlu ọfiisi wọn ni ijọba ibilẹ Bende nipinlẹ Abia kan naa.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Ní ọ̀sẹ̀ kan, ẹ̀mí tó lé ní 100 bá ààbò tó mẹ́hẹ lọ ní Nàìjíríà

Èèyàn 100 kú, ajínigbé jí 44 lọ tórí àbò tó mẹ́hẹ ní Nàìjíríà

Ọrọ ipenija abo lorilẹede Naijiria ti di eyi to n ta ba ara ile ati ero ọna bayii.

Ko fẹrẹ si ojumọ kan ti iroyin iwa ipa tabi ijinigbe, ipaniyan ati bẹẹbẹẹ lọ kii waye lorilẹede Naijiria mọ bayii.

Ọrọ naa ti di ti ojumọ kan, ara kan.

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, other

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi gan lo mu ki awọn gomina ipinlẹ to wa lapa gusu orilẹede Naijiria o lọ ree forikori ni ilu Asaba nipinlẹ Delta.

Laarin ọsẹ to kọja nikan, ko din ni ọgọrun eeyan ti wọn pa lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi awọn iwe iroyin ti ṣe gbe e sita.

Ẹyin naa ṣe haa, ẹ jẹ ka jijọ woo.

Ọjọ Aiku:

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, other

Awọn agbebọn kọlu agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Akwa Ibom lọsan ọjọ Aiku ni ijọba ibilẹ Abak.

Wọn pa ọlọpaa meji ati maluu mejila.

Bakan naa ni awọn agbebọn tun pa eeyan mẹta nileto kan torukọ rẹ n jẹ Golkofa nipinlẹ Kaduna.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ naa tun fi idi rẹ mulẹ pe eeyan marun un miran tun ku, ti wọn ṣi n wa eeyan kan miran ninu iṣẹlẹ miran to tun ṣẹlẹ nibẹ.

Ni ipinlẹ Katsina, awọn agbebọn to lọ gbẹsan ni ileto Tsatskiya nijọba ibilẹ Safana ni ipinlẹ Katsina naa tun gbẹmi eeyan mọkanla.

Lọjọ Aje:

Awọn agbebọn pa eeyan mẹta ni ileto kan to wa nijọba ibilẹ Awka ni ipinlẹ Anambra.

Ọwọ kẹjọ ileeṣẹ ọmọogun orilẹ nipinlẹ Kaduna ni awọn ti pa awọn balogun awọn agbebọn kan pẹlu mejidinlaadọta ọmọ ẹgbẹ wọn lẹkun iwọ oorun ariwa, ninu ikọlu kan ti wọn pe ni "Operation Tsare Mutane".

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Lowurọ ọjọ Aje yii kan naa, awọn agbebọn ji ogoji awọn olujọsin ti wọn n gba adura oru (Tahajjud) ninu mọsalaṣi kan nijọba ibilẹ Jibia nipinlẹ Katsina.

Bakan naa lawọn agbebọn kan tun kọlu agọ ọlọpaa kan ni Mkpanak ni ijọba ibilẹ Essien Udim ni ipinlẹ Akwa Ibom. Wọn pa ọlọpaa kan.

Lọjọ Aje yii kan naa, awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Edo forigbari pẹlu awọn ajinigbe kan, ti wọn si pa mẹta ninu wọn nibi ti wọn ti tu eeyan meje ti wọn jigbe silẹ.

Ọjọ Iṣẹgun:

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, Twitter/nigeria army

Oluọagutan ijọ Deeper life kan nilu Akurẹ, Pasitọ Ogedengbe Ọtayọmi ko sọwọ awọn ajinigbe.

Iyawo pasitọ naa ni inu ijs ni wọn ti wa ji skọ oun gbe.

Ni ilu Ikaramu Akoko, ni ipinlẹ Ondo kan naa, awọn ajinigbe tun ji agbaẹ meji gbe lọna oko wọn.

Ọjọru

Awọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter/nigeria army

Awsn agbebọn kan yinbọn pa ọga ọlspaa DSP Abdulqadir Hardo ni ipinlẹ Kebbi

Ileeṣẹ ọmọogun pẹlu fi iwe sita pe awọn koju iks agbebọn Boko Haram ni agbegbe kan nilu Maiduguri.

Mẹsan ninu wọn ni wọn ba ikọlu naa lọ.

Ẹwẹ awọn agbebọn to to ọgọrun niye pẹlu kọ lu agọ ọlọpaa Bende ni ipinlẹ Abia ti wọn si dana sun agọ ọlọpaa naa.

Bakan naa awọn olugbe ilu Mọdakẹkẹ meji lawọn eeyan kan yinbọn pa nileto Alapata.

Ọjọbọ

Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, Twitter/nigeria army

Awọn oṣiṣẹ aṣọbode ṣina ibsn fun awsn onifayawọ laarin igboro, nigba ti ina naa yoo fi rọlẹ araalu mẹrin lo ti di ero ọrun ti ọpọ dukia si bajẹ lọjọ ọdun itunu awẹ.

Ọjọ Ẹti

Ileeṣẹ ologun Naijiria ni awọn pa ọpọlọpọ agbebọn ati ibuba wọn lawọn aginju kan ni ijọba ibilẹ Chikun ati Birnin Gwari ni ipinlẹ Kaduna.

Awọn ologun ni ko din ni eeyan mẹwaa lasiko ikọlu naa.

Bakan naa, awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Akwa Ibom ni eeyan mẹjọ lo ku lasiko tawọn ẹgbẹ okunkun kan forigbari nijọba ibilẹ Esit Eket.

Satide

Awọn janduku pa eeyan meji kan lasiko ti ikọlu kan waye lagbegbe Arulogun nilu Ede

Bakan naa lawọn ọlọpaa ya bo ibuba awọn agbebọn kan nijsba ibilẹ Oyigbo ni ipinlẹ Rivers, mẹrin ninu wọn ati nọọsi obinrin kan ni wọn pa

Àkọlé fídíò, Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin