Kaduna State NLC strike: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ dorí ìṣèjọba kodò mọ́ Rl-Rufai lọ́wọ́

Awifunni ko to da ni, agba ijakadi ni pẹlu awọn osisẹ nipnilẹ Kaduna to n taporogan pẹlu ijọba gomina Mallam Nasir El-Rufai.
Lọwọ lọwọ bayii, ko si ina ọba tabi epo katakara pẹntirolu nipinlẹ Kaduna nibayi ti awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ osisẹ bẹrẹ iyansẹlodi loru mọjumọ oni.
Ọjọ Satide ijẹta si ni awọn olugbe ilu Kaduna ti foju kan ina ọba ati eto pẹtirolu gbẹyin nitori awọn osisẹ to n fi ẹhonu han lori bi ijọba ipinlẹ naa se gba isẹ lọwọ ẹgbẹlẹgbẹ osisẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ẹ̀yin Gómìnà, ọwọ́ yín ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Nàíjíríà wà - Atiku
- Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ PDP wọ̀lú Ibadan fún ìpàdé
- Ẹ fi Baba Ijesha sílẹ̀ fún mi, màá ṣe onídùróó rẹ̀ - Yomi Fabiyi
- Àgbà ọ̀jẹ̀ akọrin Fuji, Amoo Igisekele, jáde láyé
- Òkùnkùn birimùbirimù ni Kaduna bi àwọn òṣisẹ ṣe gùn le ìyànṣẹ́lódì-wo bi yóò ṣe kan ìwọ naa
- Wo ìdí méje tí olólùfẹ́ rẹ fi le kọ ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ
- Digbí ni ojú irin Kaduna- Abuja wà - Ọlọ́pàá Kaduna
- Ojú mi rí màbo nígbà tí mo bímọ àkọ́bí, ẹ̀ṣẹ̀ ni ká bímọ láì rí owó tọ́jú rẹ̀ - Lizzy Anjorin
Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ osisẹ NLC, Comrade Ayuba Magaji ti wi, iyansẹlodi ọlọjọ marun naa lo n kilọ fun ijọba lati yi ipinnu rẹ pada , ko si pe awọn osisẹ to da duro pada sẹnu isẹ.
Lasiko itọpinpin BBC yika igboro ilu Kaduna, se ni ohun gbogbo n lọ lẹwọlẹ, yatọ si bo se maa n waye tẹlẹ ni aarọ ọjọ Aje, tii se ọjọ isẹ.

Oríṣun àwòrán, Kaduna State Government
Koda, awọn ileewe ijọba ni wọn ti pa nitori bi ẹgbẹ olukọ se darapọ mọ iyansẹlodi naa, ti awọn osisẹ banki ati ile iwosan naa si n wosẹ niran.
Ijọba ipinlẹ Kaduna lo ji lọjọ kan, to si gba isẹ lọwọ ẹgbẹrun lọna meje osisẹ ijọba lai sin wọn ni gbẹrẹ ipakọ tẹlẹ tabi sanwo gba ma binu fun wọn.
Ọpọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ osisẹ to si pinnu lati kopa ninu iyansẹlodi onikilọ fun ọjọ marun naa ree:
- Ẹgbẹ awọn ileesẹ to n se ounjẹ ati siga (National Union of Food Beverages and Tobacco employees)
- Ẹgbẹ awọn osisẹ ijọba ibilẹ (Nigeria Union of Local government employees)
- Ẹgbẹ awọn osisẹ Nọọsi ati agbẹbi (Nigeria Association of Nurses and Midwives)
- Ẹgbẹ awọn osisẹ ileesẹ mọnamọna (Nigeria Union of Electricity employees)
- Ẹgbẹ awọn osisẹ elepo rọbi ati afẹfẹ gaasi (Nigeria Union of Petroleum and Natural Gas workers)
- Ẹgbẹ awọn osisẹ nileesẹ redio ati tẹlifisan (Radio Television and Theatre arts workers
- Amalgamated Union of public corporations)
- Ẹgbẹ awọn osisẹ ti kii se olukọ lawọn ibudo ikẹkọ giga (Non academic staff unions of educational and associated institutions)

Òkùnkùn birimùbirimù ni Kaduna bi àwọn òṣisẹ ṣe gùn le ìyànṣẹ́lódì-wo bi yóò ṣe kan ìwọ naa

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria (NLC) ẹka ti ìpińlẹ̀ Kaduna ti bẹ̀rẹ̀ ìyànṣẹ̀lódì lónìí ọjọ́ Aiku gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe fi síta pé àwọn yóò gùnlé ìyànṣẹ́ lódí ìukìlọ̀, sùgbọ́n inú òkùnkùn birimùbirimù ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ìhà ariwa iwọ-oorun.
Àwọn òṣìsẹ́ ilé iṣẹ́ mọ̀nàmọ́nà ní ìpińlẹ̀ Kaduna náà ti darapọ̀ fún ìyànṣẹ́lódì ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ márùn kí ìjọba le dá ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjè tó yọ níṣẹ́ padà sí ẹnu iṣẹ́ wọ́n.
Alágba ẹgbẹ NLC Comrade Ayuba Magaji Suleiman sọ pe ìp;inu àwọn ni láti dojú gbogbo ǹkan bolẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kaduna fún ọjọ́ márùn.
Ìròyìn sọ pé gómìnà El-Rufai gbé ìgbésẹ̀ náà láti mú àdínkù báàwọn ènìyàn tí ó n gba owó oṣù lábẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ náà.
Ìjọba ni mowó tí àwọn fí gbọ́ owó oṣù nínú owó tó n wọlé sí àpò ìjọba tí pọ̀ jú , ó sì tí n jẹ́ ìnìrà fún ìjọba .
Sùgbọ́n àwọn olórí òṣìṣẹ́ ní àwọn kò le faramọ̀ ìgbésẹ̀ gómìnà.
"Ìjọba kan ji láàrọ̀ ọjọ́ kan wọ́n si gbé ìwé lọ rọ́kún nílé fún odikdi ènìyàn ẹgbẹ̀rún méje, láìsí àjọsọ kankan tàbi kí wọ́n san owó ìfẹ́yìnti fún wọ́n" adari ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ló sọ bẹ́ẹ̀.
" Ènìyàn ni àwọn ewọ̀nyìí náà, wọ́n sì ni ẹbí pẹ̀lú, bákan náà ni wọ́n ni àwọn tó n wòi wọ́n lóke fún òunjẹ òòjọ́ wọn, nítorí náà, ìgbésẹ̀ tí kò dára ni.
"Ìdí níyi tí a fi pè fún ìyànṣẹ́ lódì, ọ̀pọ́ àwọn ẹgbẹ́ tó kù náà ló si ti darapọ̀ mọ́ wá à fi ti gómìnà bá yíi ìpinu rẹ̀ padà."
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí kọ lẹ́tà sí oníruurú ẹgbẹ́ tó kù láti darapọ̀ mọ́ wọ́n fún ìyànṣẹ́lódì náà
Báwo ìyànṣẹ́lódì náà ṣe kàn ọ?
Ilé iṣẹ́ mọ̀nàmọ́nà ní Kaduna ti fi àtẹ̀jáde síta pé àwọn oníbàrà wọ́n kò ni le lo iná nítori pé àwọn n'lọ fun ìyanṣẹ́lódì.
"Ní ìlànà ìdarí ti NLC fi lélẹ̀ ilé iṣẹ́ to n pín iná Mọ̀nàmọ́ná (TCN) ti pa gbogbo 33kv ti ọ n pin iná fún Kaduna."

Oríṣun àwòrán, KAEDC
NLC ti sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́kada àti àwọn onímótò láti darapọ̀ fún ìyanṣklódì náà.
!["Kaduna State NLC strike update": [Labour union strike to shut down Kaduna]](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/640/cpsprodpb/16424/production/_118527119_kadunastatenlcstrikeupdate-labourunionstriketoshutdownkaduna.jpg.webp)
Oríṣun àwòrán, NAN
Nínú ìwé tí wọ́n pín gbogbo àwọn ilé iṣẹ́ yìí ni wọ́n ni ki wọ́n máa ṣisẹ́:
- National Union of Food Beverages and Tobacco employees,
- Nigeria Union of Local government employees
- Nigeria Association of Nurses and Midwives
- Nigeria Union of Electricity employees
- Nigeria Union of Petroleum and Natural Gas workers
- Radio Television and Theatre arts workers
- Amalgamated Union of public corporations
- Non academic staff unions of educational and associated institutions

Kíni ìjọba Kaduna sọ níp;a ìyànsẹ́lódì?
Nínú àtẹjáde, ìjọba ìpińlẹ̀ Kaduna sọ pé gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ kan lọ sọ ara dáada.
Ìjọba ní ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC tàpá sí òfin sí òfin to ni ìyànṣẹ́lódì kò gbọdọ kan àwọn oṣiṣẹ́ tó n pèsè àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì fún ará ìlú.
Bákan náà ni òfin lòdì sí níní ọmọlakejì lára láti jáde lọ ibi ti ó wù wọ́n nítolri pé wọ́n gùnlé ìyanṣẹ́lódì."
Bákan náà ni ìjọba Kaduna sọ pé òun yóò da ààbò tó péye bo àwọn ilé iṣẹ́ òun ti ààyè sì wà fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ṣiṣẹ́ ni ọfíísì wọn.
Ó fi kun pé òfin ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà kìí ṣe fún híhù ìwà àìbìkítà"
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló tí bọ́ sójú òpó twitter láti sọ èrò ọkàn wọ́n lórí ọ̀rọ̀ náà.

Oríṣun àwòrán, Kaduna state govt
Kíni Gómìnà El-Rufai sọ?
Gómìnà ìpińlẹ̀ Kaduna ṣe n dá àwọn kan lóhùn nítolrí wan sọ pé ìyáṣe lódì yìí ní yóò burújù nínú ìtàn ìyanṣẹ́lódì"
Bákan náà ni wọ́n fi kú pé gómínà ń pinu láti fi ọlọ́pàá mú àwọn adarí òṣìṣẹ́.
Gómìnà ìpińlẹ̀ Kaduna wá dáwọn lóhùn pé àwọn ni bábanla baba awọn alábòsí, àti pé òun ń dúró de wọn

Oríṣun àwòrán, Twitter
Bákan náà lo fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ láti ipele kẹrinla ti n ṣiṣẹ́ láti ilé láti ẹyin wá ó ṣ pàtàkì kí an tẹ̀síwájú láti má ṣiṣk láti ilé wọn

Oríṣun àwòrán, El-rufai
Wo nǹkan ti àwọn ènìyàn ń sọ

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter
















