Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

A fé ki ijọba ba wa kọ isọ to dara sabẹ afara naa ni ki ebi ma baa pa awọn Ontaja ni Iganmu.

Mr Focus ọkan lara awọn ontaja to wa ni abẹ afara Iganmu ni ipinlẹ Eko ṣalaye ohun to ṣokunfa bi ijọba ṣe wa wo ile naa.

O menuba bi wọn ṣe maa n ja bagi gba lọwọ awọn eeyan to ba ti di alẹ ati awọn iṣẹ ibi lorisiirisii to maa n waye nibẹ.

Bakan naa ni o tun parọwa fun ijọba lati ṣaanu awọn agbalagba to n taja bii omi tutu nibẹ.

O tun ni ki wọn ro ti awọn ọdọ to n ṣiṣẹ aje nibẹ pe ki ijoba kọ awọn isọ keekeekee to ni eto fun wọn dipo ki wọn lọ di alainiṣẹ.