Baba Ijesha: Àkójọpọ̀ ìwádìí wa rèé nípa gbígbá béèlì Olanrewaju Omiyinka

Aworan Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha/Twitter

Oju opo ayelujara ati tawọn ileeṣẹ iroyin Naijiria kan n gbona janin-janin lọsan ọjọ Aje, lori iroyin kan pe Baba Ijesa to wa ni ahamọ ọlọpaa ti gba itusilẹ.

Lati nkan irọlẹ ọjọ Aiku ni iroyin yii ti kọkọ lu jade sigboro, ti awọn eeyan si n gba bi ẹni gba igba ọti kaakiri.

Idi si niyi ti BBC Yoruba fi n se iwadi pe se lootọ ni wọn ti gba oniduro Olanrewaju James, ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijesa, tabi o si wa ni ahamọ ọlọpaa?

Ọna lati ri okodoro ọrọ nipa ahesọ ọrọ yii lo mu wa pe awọn to sunmọ Baba Ijesa ati awọn agbofinro to fi si ahamọ lori ẹsun aṣemase pẹlu ọmọdebinrin kan.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

Yomi Fabiyi - N ko gbọ pe wọn ti gba beeli Baba Ijesha

Ninu awọn to lewaju pe ki wọn tu Baba Ijesa silẹ ni gbajugbaja osere Yomi Fabiyi wa.

Ninu ijagudu rẹ fun idande Baba Ijesha ni ahamọ, Fabiyi ni ofin lo yẹ ka tẹle lori ọrọ Baba Ijesa nitori naa, ko yẹ ki o wa ni ahamọ gbere titi ti wọn yoo fi gbẹjọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba ti BBC Yoruba kan si lori aago rẹ, Fabiyi ni oun ko ti gbọ pe wọn ti gba beeli Baba Ijesa.

O ni ''Bi o ba jẹ pe wọn gba beeli rẹ, ohun to yẹ labẹ ofin naa lo ṣẹlẹ yẹn''

O ni bi awọn eeyan ṣe n gbọ pe wọn tu silẹ loun naa ṣe n gbọ ṣugbọn bi oun ba ri aridaju ọrọ yii, oun yoo fi to wa leti.

Àkọlé fídíò, Asẹ́yìn, àwọn ẹbí olóògbé ṣì ń fomijé dárò àwọn tóṣìṣẹ́ 'Custom' yìnbọn pa nílùú Iseyin

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa - N ko gbọ rara pe wọn ti gba beeli Baba Ijesha

Esi Yomi Fabiyi yii si lo mu wa kan si alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lati fidi ootọ ọrọ naa mulẹ.

Nigba to n fesi pada lori atẹjisẹ ta fi ransẹ si, Muyiwa Adejobi tii se Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko ni oun ko mọ rara boya wọn ti tu afurasi naa silẹ ni ahamọ ọlọpaa.

Amọ sibẹ isẹju- isẹju ni awọn iroyin n kan wa lori ayelujara pe wọn ti gba beeli Baba Ijesha, ti a ko si ri aworan, fidio tabi ẹnikẹni to fidi ọrọ naa mulẹ.

Koda, awọn ololufẹ wa loju opo Facebook BBC Yoruba gan n sọ pe awọn hu gbọ nipa pe wọn ti gba beeli Baba Ijesha sugbọn a ko ri aridaju kankan nipa rẹ.

Niwọn igba ti ileesẹ ti wa kii he ira ti ko mi ọmọ ninu, to ba se jẹ, iwadi si n tẹ siwaju, a maa kan si yin.