Baba Ijesha: Amòfin Ogunlana ní kò tọ́ bí wọn ṣe fi béèlì Omiyinka kọ́ ọrùn ìyanṣẹ́lódì òṣìṣẹ́ iléẹjọ́

Baba Ijesha ati amofin Adesina Ogunlana

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha Instagram/Adesina Ogunlana Facebook

Gbajugbaja agbẹjọro to n ja fun ominira Baba Ijesha, Adesina Ademola Ogunlana ti sọrọ lori iha ti awọn ọlapaa kọ si ọrọ to sọ nipa Baba Ijesha.

Ogunlana, tii se alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awọn agbẹjọro nipinlẹ Eko salaye pe, se ni ẹrin n pa oun nipa bi awọn eeyan naa se n dọgbọn lati tako ofin.

Ogunlana wa fikun pe awọn ọlọpaa ti ni ki oun kọ lẹta si Kọmisana ọlọpaa pe ki wọn fun Baba Ijesha ni beeli kuro ni ahamọ.

"Amọ igbesẹ ti wọn n beere naa ya mi lẹnu nitori ilana ti ko nitumọ lasan ni wsn ni ki n tẹle, ko wulo rara.

Mo si ti sọ fun igbakeji Kọmisana ọlọpaa Adegoke to beere lẹta naa pe se lo n tẹti abala kan ninu ero awọn araalu lori isẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Face Transplant: DiMeo ṣùn lásìkò tó n wa ọkọ̀ lálẹ́, ló bá jóná nígbà tí ọkọ̀ gbiná

Mo si sọ fun pe ẹnikẹni to ba jẹ asaaju gbọdọ ni ọkan akin ati igboya lati sọ ati se ohun to tọ nigba gbogbo, ko maa si dabi Pọntu Pilatu to mọ ohun to yẹ ko se lasiko igbẹjọ Jesu, amọ ti ko se e."

Agbẹjọro naa ni Pọntu Pilatu mọ ohun to yẹ ko se amọ se lo n fọ ọwọ rẹ kuro ninu igbẹjọ Jesu, to si jẹ ki wọn kan mọ agbelebu,eyi to fi n tan ara rẹ jẹ.

O ni oun tun sọ fun pe ko lọ ba ọga rẹ pe ki wọn se ohun to yẹ lati se lori ọrọ Baba Ijesha, ki wọn ma si se tẹti si ero araalu lasan.

Awọn ọlọpaa n tẹle abala kan ero araalu lori ọrọ Baba Ijesha

"Lootọ ni ero araalu se pataki lootọ amọ ko se pataki to ohun to yẹ labẹ ofin ati ohun ti ofin sọ.

O n salaye fun mi pe awọn ri pe afurasi naa se asemase pẹlu ọmọde ni awọn ko fi lee gba beeli rẹ gẹgẹ bi ofin se sọ.

Mo si ni se ofin tipinlẹ Eko lo n sọ, se ofin tipinlẹ Eko ga ju ofin apapọ ilẹ wa lọ ni? rara o, lootọ ni ko ga ju ofin Naijiria lọ."

Amofin Ogunlana ni ọrọ Baba Ijesha kọja boya o ba ọmọde se asemase tabi bẹẹkọ, ohun to wa nilẹ ni pe ka tẹle ohun ti ofin Naijiria sọ lori ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ọrọ ofin kọja pe boya a fẹran oju Baba Ijesha tabi iwa to hu amọ ohun to yẹ ka wo ni ẹtọ atawọn anfaani ti afurasi naa ni labẹ ofin, ka si tẹle.

"O ti foju han gbangba pe se ni wọn n fi ọwọ ọla gba Baba Ijesha loju, ti wọn si n sọ fun pe a tẹ ori rẹ ba, ta si fi ẹtọ rẹ du ọ dipo ka sẹ awọn alagbara to tako ọ."

Agbẹjọro naa ni awọn ti kọ lẹta ọhun, ti awọn si ti fun ọlọpaa Adegoke, ẹni to salaye pe awọn yoo wo boya ileẹjọ yoo sisẹ lọjọ Aje lati gbe Baba Ijesha rele ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Iganmu shanty demolition: Oníṣẹ́ ibi pọ̀ tó ń ṣọṣẹ́ lábẹ́ afárá Iganmu yìí ti pẹ́ ṣùgbọ́n.

"Maa pe Kọmisana ọlọpaa Eko, Odumosu lẹjọ"

"Eyi naa ko tọna rara nitori ko dara bi wọn gbe ẹjọ Baba Ijesha kọ ọrun awọn osisẹ ẹka eto idajọ to n wosẹ niran.

Mo sọ fun pe maa pe oun ati Kọmisana Odumosu lẹjọ, kii se pe mo n dunkooko mọ wọn ni nitori a ti kọja akoko to yẹ ka maa dirẹbẹ fun awọn osisẹ ọba to yẹ ko maa tẹle ofin.

Otitọ ọrọ ree, bi wọn ba si se tete se ohun to tọ, lo se dara si nitori gbogbo eeyan lo yẹ ko maa sọrọ soke lori ifiyajẹni, ko si yẹ ka duro de akoko ti yoo kan wa abi ẹbi wa."

Ogunlana ni ohun tawọn n beere ni pe ki wọn fi Baba Ijesha silẹ nitori awọn osisẹ ẹka eto idajọ ni awọn si n tẹsiwaju pẹlu iyansẹlodi wọn, ti ipade wọn pẹlu ijọba si tun fori sanpọn.

Amofin naa wa n beere pe ti Baba Ijesha ba jẹ ibatan awọn ọlọpaa yii, se wọn yoo se bi wsn ti se yii?

O wa rọ awọn araalu lati maa dagunla si iwa ifiyajẹni, ti wọn yoo si ni bawọn ba ti jiire, abusebuse nitori ori yeye nimogun, ti aisẹ lo pọ.

"Beeli ni ẹtọ ẹnikọọkan to ba jẹ afurasi, koda ko si ẹsẹ ti ko yẹ ki wọn mase gba beeli rẹ. Baba Ijesha kọ lo kọ ofin naa."

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

"Ẹrin n pa mi lori bawọn eeyan kan se n sọko ọrọ si mi tori Baba Ijesha"

Wayi o, amofin Ogunlana tun ti sọrọ lori bi awọn eeyan kan se n sọko ọrọ lu oun lori ayelujara nipa bi oun se n beere ẹtọ ofin fun Baba Ijesha.

O ni igbesẹ wọn naa ko sẹyin igbesẹ ti oun gbe lati lọ wo Baba Ijesha ni ahamọ, ti oun si kọwe pe ki wọn gba beeli rẹ ni ahamọ ọlọpaa.

Bẹẹ ba gbagbe, agbẹjọro naa ati Yomi Fabiyi pẹlu awọn lọya miran ni wsn bẹ Baba Ijesha wo ni ahamọ, ti wọn si n sọ fun awọn ọlọpaa pe o tọ ki wọn gba beeli rẹ.

Amọ lẹyin igbesẹ naa ni agbẹjọro Ogunlana kede loju opo ayelujara Facebook rẹ pe se lawọn eeyan kan n sọko ọrọ si oun fun atilẹyin gbangba ti oun n se fun afurasi naa.

Àkọlé fídíò, India, Coronavirus: Ìtọ́jú aláìsàn ló jẹ́ mi lógún nítorí ètò ìlera wa mẹ́hẹ- Nọ́ọ̀sì Kama

"Awọn eeyan ni anfaani lati sọ ero ọkan wọn lori awọn iroyin ti oun ba gbe soju opo ibanidọrẹ oun ati fidio pẹlu.

Amọ mo n kilọ fun awọn to ba n sọrọ lori iroyin naa pe wọn yoo gbara gba bọnbu ni ilọpo mẹwa.

Ẹ ba fi ọbẹ ge mi, ma fun yin lesi nitori emi kii se agbẹjọro to n mu tii lasan, ẹ ro lẹẹmeji, kẹ to maa se ẹnu belebele si mi."